< Psalms 93 >
1 Olúwa ń jẹ ọba, ọláńlá ni ó wọ̀ ní aṣọ; ọláńlá ni Olúwa wọ̀ ní aṣọ àti ìhámọ́ra rẹ̀ pẹ̀lú agbára. Ó fi ìdí ayé múlẹ̀; kò sì le è yí.
耶和华作王! 他以威严为衣穿上; 耶和华以能力为衣,以能力束腰, 世界就坚定,不得动摇。
2 Ìjọba rẹ̀ wà láti ọjọ́ pípẹ́; ìwọ wà títí ayérayé.
你的宝座从太初立定; 你从亘古就有。
3 A ti gbé òkun sókè, Olúwa, òkun ti gbé ohùn wọn sókè; òkun ti gbé rírú omi wọn sókè.
耶和华啊,大水扬起, 大水发声,波浪澎湃。
4 Ó ni ògo ju àrá omi ńlá lọ, ó ni ògo ju òkun rírú lọ Olúwa ga ní ògo.
耶和华在高处大有能力, 胜过诸水的响声,洋海的大浪。
5 Ẹ̀rí rẹ̀ dúró ṣinṣin; ìwà mímọ́ ni ó fi ṣe ilé rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ fún ọjọ́ àìlópin, Olúwa.
耶和华啊,你的法度最的确; 你的殿永称为圣,是合宜的。