< Psalms 107 >
1 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó ṣeun; nítorí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé.
Louvai ao Senhor, porque ele é bom, porque a sua benignidade dura para sempre.
2 Jẹ́ kí àwọn ẹni ìràpadà Olúwa kí ó wí báyìí, àwọn ẹni tí ó rà padà kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá,
Digam-no os remidos do Senhor, os que remiu da mão do inimigo,
3 àwọn tí ó kójọ láti ilẹ̀ wọ̀n-ọn-nì, láti ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn, láti àríwá àti Òkun wá.
E os que congregou das terras do oriente e do ocidente, do norte e do sul.
4 Wọ́n ń rìn káàkiri ní aginjù ní ibi tí ọ̀nà kò sí, wọn kò rí ọ̀nà lọ sí ìlú níbi tí wọn ó máa gbé.
Andaram desgarrados pelo deserto, por caminhos solitários; não acharam cidade para habitarem.
5 Ebi ń pa wọn, òǹgbẹ gbẹ wọ́n, ó sì rẹ ọkàn wọn nínú wọn.
Famintos e sedentos, a sua alma neles desfalecia.
6 Ní ìgbà náà, wọ́n kígbe sókè sí Olúwa nínú ìdààmú wọn, ó sì yọ wọ́n kúrò nínú ìrora wọn
E clamaram ao Senhor na sua angústia, e os livrou das suas necessidades.
7 Ó fi ọ̀nà títọ́ hàn wọ́n sí ìlú tí wọn lè máa gbé.
E os levou por caminho direito, para irem a uma cidade de habitação.
8 Ẹ jẹ́ kí wọn máa yin Olúwa nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti nítorí iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ sí àwọn ọmọ ènìyàn,
Louvem ao Senhor pela sua bondade, e pelas suas maravilhas para com os filhos dos homens.
9 nítorí tí ó tẹ́ ìfẹ́ ọkàn lọ́run ó sì fi ìre fún ọkàn tí ebi ń pa.
Pois fartou a alma sedenta, e encheu de bondade a alma faminta.
10 Ọ̀pọ̀ jókòó nínú òkùnkùn àti òjìji ikú, a dè wọ́n ní ìrora àti ní irin,
Tal como a que se assenta nas trevas e sombra da morte, presa em aflição e em ferro;
11 nítorí tí wọ́n ṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n kẹ́gàn ìbáwí Ọ̀gá-ògo,
Porquanto se rebelaram contra as palavras de Deus, e desprezaram o conselho do altíssimo,
12 Ó sì fi ìkorò rẹ àyà wọn sílẹ̀; wọn ṣubú, kò sì ṣí ẹni tí yóò ràn wọ́n lọ́wọ́.
Portanto lhes abateu o coração com trabalho; tropeçaram, e não houve quem os ajudasse.
13 Ní ìgbà náà wọ́n ké pe Olúwa nínú ìdààmú wọn, ó sì gbà wọ́n nínú ìṣòro wọn
Então clamaram ao Senhor na sua angústia, e os livrou das suas necessidades.
14 Ó mú wọn jáde kúrò nínú òkùnkùn àti òjìji ikú, ó sì fa irin tí wọ́n fi dè wọ́n já.
Tirou-os das trevas e sombra da morte; e quebrou as suas prisões.
15 Ẹ jẹ́ kí wọn fi ọpẹ́ fún Olúwa! Nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti nítorí iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ sí ọmọ ènìyàn.
Louvem ao Senhor pela sua bondade, e pelas suas maravilhas para com os filhos dos homens.
16 Nítorí tí ó já ìlẹ̀kùn idẹ wọ̀n-ọn-nì ó sì ké irin wọn ní agbede-méjì.
Pois quebrou as portas de bronze; e despedaçou os ferrolhos de ferro.
17 Ọ̀pọ̀ di aṣiwèrè nítorí ìrékọjá wọn wọ́n sì pọ́n wọn lójú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
Os loucos, por causa da sua transgressão, e por causa das suas iniquidades, são aflitos.
18 Wọ́n kọ gbogbo oúnjẹ wọ́n sì súnmọ́ ẹnu-ọ̀nà ikú.
A sua alma aborreceu toda a comida, e chegaram até às portas da morte.
19 Nígbà náà wọ́n kígbe sí Olúwa nínú ìṣòro wọn, ó sì yọ wọ́n nínú ìdààmú wọn.
Então clamaram ao Senhor na sua angústia: e ele os livrou das suas necessidades.
20 Ó rán ọ̀rọ̀ rẹ̀, ara wọn sì dá ó sì yọ wọ́n nínú isà òkú.
Enviou a sua palavra, e os sarou; e os livrou da sua destruição.
21 Ẹ jẹ́ kí wọ́n fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ fún ọmọ ènìyàn.
Louvem ao Senhor pela sua bondade, e pelas suas maravilhas para com os filhos dos homens.
22 Jẹ́ kí wọn rú ẹbọ ọpẹ́ kí wọn kí ó fi ayọ̀ sọ̀rọ̀ iṣẹ́ rẹ̀.
E ofereçam os sacrifícios de louvor, e relatem as suas obras com regozijo.
23 Àwọn tí ń sọ̀kalẹ̀ lọ sí Òkun nínú ọkọ̀ ojú omi, wọ́n jẹ́ oníṣòwò nínú omi ńlá.
Os que descem ao mar em navios, mercando nas grandes águas,
24 Wọ́n rí iṣẹ́ Olúwa, àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ nínú ibú.
Esses veem as obras do Senhor, e as suas maravilhas no profundo.
25 Nítorí tí ó pàṣẹ, ó sì mú ìjì fẹ́ tí ó gbé ríru rẹ̀ sókè.
Pois ele manda, e se levanta o vento tempestuoso, que eleva as suas ondas.
26 Wọ́n gòkè lọ sí ọ̀run wọ́n sì tún sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibú: nítorí ìpọ́njú, ọkàn wọn di omi.
Sobem aos céus; descem aos abismos, e a sua alma se derrete em angústias.
27 Wọ́n ń ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n bí ọ̀mùtí ènìyàn: ọgbọ́n wọn sì dé òpin.
Andam e cambaleam como ébrios, e perderam todo o tino.
28 Nígbà náà wọ́n ń kígbe sókè sí Olúwa nínú ìdààmú wọn, ó sì mú wọn jáde nínú ìṣòro wọn.
Então clamam ao Senhor na sua angústia; e ele os livra das suas necessidades.
29 Ó sọ ìjì di ìdákẹ́rọ́rọ́ bẹ́ẹ̀ ni ríru omi rẹ̀ dúró jẹ́ẹ́.
Faz cessar a tormenta, e calam-se as suas ondas.
30 Inú wọn dùn nígbà tí ara wọn balẹ̀, ó mú wọn lọ sí ibi tí ọkàn wọn lọ.
Então se alegram, porque se aquietaram; assim os leva ao seu porto desejado.
31 Jẹ́ kí wọn fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ fún ọmọ ènìyàn.
Louvem ao Senhor pela sua bondade, e pelas suas maravilhas para com os filhos dos homens.
32 Jẹ́ kí wọn gbé e ga ní àárín àwọn ènìyàn kí wọn kí ó sì yìn ín ní ìjọ àwọn àgbàgbà.
Exaltem-no na congregação do povo, e glorifiquem-no na assembléia dos anciãos.
33 Ó sọ odò di aginjù, àti orísun omi di ilẹ̀ gbígbẹ.
Ele converte os rios em um deserto, e as fontes em terra sedenta:
34 Ilẹ̀ eléso di aṣálẹ̀ nítorí ìwà búburú àwọn tí ó wà nínú rẹ̀.
A terra frutífera em estéril, pela maldade dos que nela habitam.
35 O sọ aginjù di adágún omi àti ilẹ̀ gbígbẹ di orísun omi,
Converte o deserto em lagoa, e a terra seca em fontes.
36 níbẹ̀ ó mú ẹni tí ebi ń pa wà, wọ́n sì pilẹ̀ ibi tí wọn ó máa gbé.
E faz habitar ali os famintos, para que edifiquem cidade para habitação;
37 Wọn fún irúgbìn, wọ́n sì gbin ọgbà àjàrà tí yóò máa so èso tí ó dára;
E semeiam os campos e plantam vinhas, que produzem fruto abundante.
38 Ó bùkún wọn, wọ́n sì pọ̀ sí i ní iye kò sí jẹ́ kí ẹran ọ̀sìn wọn kí ó dínkù.
Também os abençoa, de modo que se multiplicam muito; e o seu gado não diminui.
39 Nígbà náà, ọjọ́ wọn kúrú, ìnira, ìpọ́njú àti ìṣòro wọn sì dínkù,
Depois se diminuem e se abatem, pela opressão, aflição e tristeza.
40 ẹni tí ó da ẹ̀gàn lu ọmọ-aládé ó sì mú wọn rìn níbi tí ọ̀nà kò sí.
Derrama o desprezo sobre os príncipes, e os faz andar desgarrados pelo deserto, onde não há caminho.
41 Ṣùgbọ́n ó gbé aláìní sókè kúrò nínú ìnira ó mú ìdílé wọn pọ̀ bí agbo ẹran.
Porém livra ao necessitado da opressão em um lugar alto, e multiplica as famílias como rebanhos.
42 Àwọn tí ó dúró sì rí i, inú wọn sì dùn ṣùgbọ́n gbogbo olùṣe búburú yóò pa ẹnu rẹ̀ mọ́.
Os retos o verão, e se alegrarão, e toda a iniquidade tapará a boca.
43 Ẹni tí ó bá gbọ́n, jẹ́ kí ó kíyèsi nǹkan wọ̀nyí kí ó wo títóbi ìfẹ́ Olúwa.
Quem é sábio observará estas coisas, e eles compreenderão as benignidades do Senhor.