Preface
Read
+
Publisher
Nainoia, Inc.
PO Box 462, Bellefonte, PA 16823
(814) 470-8028
Nainoia Inc, Publisher
LinkedIn/NAINOIA-INC
Third Party Publisher Resources
Request Custom Formatted Verses
Please contact us below
Submit your proposed corrections
I understand that the Aionian Bible republishes public domain and Creative Commons Bible texts and that volunteers may be needed to present the original text accurately. I also understand that apocryphal text is removed and most variant verse numbering is mapped to the English standard. I have entered my corrections under the verse(s) below. Proposed corrections to the Yoruba Bible, Psalms Chapter 91 https://www.AionianBible.org/Bibles/Yoruba---Yoruba-Bible/Psalms/91 1) Ẹni tí ó gbé ibi ìkọ̀kọ̀ Ọ̀gá-ògo ni yóò sinmi ní ibi òjìji Olódùmarè. 2) Èmi yóò sọ nípa ti Olúwa pé, “Òun ni ààbò àti odi mi, Ọlọ́run mi, ẹni tí èmi gbẹ́kẹ̀lé”. 3) Nítòótọ́ òun yóò gbà mí nínú ìdẹ̀kùn àwọn pẹyẹpẹyẹ àti nínú àjàkálẹ̀-ààrùn búburú. 4) Òun yóò fi ìyẹ́ rẹ̀ bò mí, àti ni abẹ́ ìyẹ́ rẹ̀ ni èmi yóò ti rí ààbò; òtítọ́ rẹ̀ ni yóò ṣe ààbò àti odi mi. 5) Ìwọ kì yóò bẹ̀rù nítorí ẹ̀rù òru, tàbí fún ọfà tí ń fò ní ọ̀sán, 6) tàbí fún àjàkálẹ̀-ààrùn tí ń rìn kiri ní òkùnkùn, tàbí fún ìparun tí ń rìn kiri ní ọ̀sán gangan. 7) Ẹgbẹ̀rún yóò ṣubú ní ẹ̀gbẹ́ rẹ, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ, ṣùgbọ́n kì yóò súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ. 8) Ìwọ yóò máa wò ó pẹ̀lú ojú rẹ àti wo ìjìyà àwọn ẹni búburú. 9) Nítorí ìwọ fi Olúwa ṣe ààbò rẹ, ìwọ fi Ọ̀gá-ògo ṣe ibùgbé rẹ. 10) Búburú kan ki yóò ṣubú lù ọ́, Bẹ́ẹ̀ ni ààrùnkárùn kì yóò súnmọ́ ilé rẹ. 11) Nítorí yóò fi àṣẹ fún àwọn angẹli nípa tìrẹ láti pa ọ́ mọ́ ní gbogbo ọ̀nà rẹ; 12) wọn yóò gbé ọ sókè ní ọwọ́ wọn, nítorí kí ìwọ má ba à fi ẹsẹ̀ rẹ gún òkúta. 13) Ìwọ yóò rìn lórí kìnnìún àti paramọ́lẹ̀; ìwọ yóò tẹ kìnnìún ńlá àti ejò ńlá ni ìwọ yóò fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀. 14) “Nítorí ti ìfẹ́ rẹ sí mi, èmi yóò gbà ọ́; èmi yóò pa ọ́ mọ́, nítorí ìwọ jẹ́wọ́ orúkọ mi. 15) Òun yóò pè mí, èmi yóò sì dá a lóhùn; èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìpọ́njú, èmi yóò gbà á, èmi yóò sì bu ọlá fún un. 16) Pẹ̀lú ẹ̀mí gígùn ni èmi yóò fi tẹ́ ẹ lọ́rùn, èmi yóò sì fi ìgbàlà mi hàn án.” Additional comments?
Refresh Captcha
The world's first Holy Bible un-translation!