Preface
Read
+
Publisher
Nainoia, Inc.
PO Box 462, Bellefonte, PA 16823
(814) 470-8028
Nainoia Inc, Publisher
LinkedIn/NAINOIA-INC
Third Party Publisher Resources
Request Custom Formatted Verses
Please contact us below
Submit your proposed corrections
I understand that the Aionian Bible republishes public domain and Creative Commons Bible texts and that volunteers may be needed to present the original text accurately. I also understand that apocryphal text is removed and most variant verse numbering is mapped to the English standard. I have entered my corrections under the verse(s) below. Proposed corrections to the Yoruba Bible, Jeremiah Chapter 21 https://www.AionianBible.org/Bibles/Yoruba---Yoruba-Bible/Jeremiah/21 1) Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jeremiah wá nígbà tí ọba Sedekiah rán Paṣuri ọmọ Malkiah àti àlùfáà Sefaniah ọmọ Maaseiah sí i; wọ́n wí pé: 2) “Wádìí lọ́wọ́ Olúwa fún wa nítorí Nebukadnessari ọba Babeli ń kọlù wá. Bóyá Olúwa yóò ṣe ìyanu fún wa gẹ́gẹ́ bí ti àtẹ̀yìnwá, kí ó sì yípadà kúrò lọ́dọ̀ wa.” 3) Ṣùgbọ́n Jeremiah dáhùn wí pé, “Sọ fún Sedekiah, 4) ‘Èyí ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli wí, Èmi fẹ́ kọjú idà tí ó wà lọ́wọ́ yín sí yín, èyí tí ẹ̀ ń lò láti bá ọba àti àwọn ará Babeli tí wọ́n wà lẹ́yìn odi jà, Èmi yóò sì kó wọn jọ sínú ìlú yìí. 5) Èmi gan an yóò sì bá yín jà pẹ̀lú ohun ìjà olóró nínú ìbínú àti ìrunú líle. 6) Èmi yóò sì lu gbogbo ìlú yìí, ènìyàn àti ẹranko, gbogbo wọn ni àjàkálẹ̀-ààrùn yóò kọlù tí wọn yóò sì kú. 7) Olúwa sọ pé lẹ́yìn èyí, èmi yóò fi Sedekiah ọba Juda, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àti àwọn ènìyàn, àti àwọn tí ó kù ní ìlú yìí lọ́wọ́ àjàkálẹ̀-ààrùn àti lọ́wọ́ idà, àti lọ́wọ́ ìyàn; èmi yóò fi wọ́n lé Nebukadnessari ọba Babeli lọ́wọ́, àti lé ọwọ́ àwọn ọ̀tá wọn, àti lé ọwọ́ àwọn tí ń lépa ẹ̀mí wọn, òun yóò sì fi ojú idà pa wọ́n, kì yóò sì dá wọn sí, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ní ìyọ́nú tàbí ṣàánú wọn.’ 8) “Síwájú sí i, sọ fún àwọn ènìyàn, ‘Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó sọ: Wò ó, Èmi ń fi ọ̀nà ìyè àti ikú hàn yín. 9) Ẹnikẹ́ni tí ó bá dúró sí ìlú yìí yóò ti ipa idà, ìyàn tàbí àjàkálẹ̀-ààrùn kú. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jáde tí ó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún àwọn Babeli tí ó ń lépa yín yóò sì yè. Òun yóò sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ̀. 10) Mo ti pinnu láti jẹ ìlú yìí ní yà, ni Olúwa wí. A ó sì gbé e fún ọba Babeli, yóò sì run ún pẹ̀lú iná.’ 11) “Ẹ̀wẹ̀, wí fún ìdílé ọba Juda pé, ‘Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa. 12) Ilé Dafidi èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa sọ: “‘Ṣe ìdájọ́ tí ó tọ́ ní àràárọ̀; yọ ọ́ kúrò lọ́wọ́ ẹni tí ó ń ni í lára ẹni tí a ti jà lólè bí bẹ́ẹ̀ kọ́ ìbínú mi yóò jáde síta, yóò sì jó bí iná. Nítorí ibi tí a ti ṣe yóò sì jó láìsí ẹni tí yóò pa á. 13) Mo kẹ̀yìn sí ọ, Jerusalẹmu, ìwọ tí o gbé lórí àfonífojì lórí òkúta tí ó tẹ́jú, ni Olúwa wí. Ìwọ tí o ti wí pé, “Ta ni ó le dojúkọ wá? Ta ni yóò wọ inú ibùgbé wa?” 14) Èmi yóò jẹ ọ ní ìyà gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni Olúwa wí. Èmi yóò mú kí iná jó ilé rẹ̀; yóò si jó gbogbo ohun tí ó wà ní àyíká rẹ.’” Additional comments?
Refresh Captcha
The world's first Holy Bible un-translation!