< Zephaniah 3 >
1 Ègbé ni fún ìlú aninilára, ọlọ̀tẹ̀ àti aláìmọ́.
Горе городу нечистому и оскверненному, притеснителю!
2 Òun kò gbọ́rọ̀ sí ẹnikẹ́ni, òun kò gba ìtọ́ni, òun kò gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni òun kò súnmọ́ ọ̀dọ̀ Ọlọ́run rẹ̀.
Не слушает голоса, не принимает наставления, на Господа не уповает, к Богу своему не приближается.
3 Àwọn olórí rẹ̀ jẹ́ kìnnìún tí ń ké ramúramù, àwọn onídàájọ́ rẹ̀, ìkookò àṣálẹ́ ni wọn, wọn kò sì fi nǹkan kan kalẹ̀ fún òwúrọ̀.
Князья его посреди него - рыкающие львы, судьи его - вечерние волки, не оставляющие до утра ни одной кости.
4 Àwọn wòlíì rẹ̀ gbéraga, wọ́n sì jẹ́ alárékérekè ènìyàn. Àwọn àlùfáà rẹ̀ ti ba ibi mímọ́ jẹ́, wọ́n sì rú òfin.
Пророки его - люди легкомысленные, вероломные; священники его оскверняют святыню, попирают закон.
5 Olúwa ni àárín rẹ̀ jẹ́ olódodo; kì yóò ṣe ohun tí kò tọ̀nà. Àràárọ̀ ni ó máa ń mú ìdájọ́ rẹ̀ wá sí ìmọ́lẹ̀, kì í sì kùnà ní gbogbo ọjọ́ tuntun, síbẹ̀ àwọn aláìṣòótọ́ kò mọ ìtìjú.
Господь праведен посреди него, не делает неправды, каждое утро являет суд Свой неизменно; но беззаконник не знает стыда.
6 “Èmi ti ké àwọn orílẹ̀-èdè kúrò, ilé gíga wọn sì ti bàjẹ́. Mo ti fi ìgboro wọn sílẹ̀ ní òfo tó bẹ́ẹ̀ tí ẹnìkankan kò kọjá níbẹ̀. Ìlú wọn parun tó bẹ́ẹ̀ tí kò sí ẹnìkan tí yóò ṣẹ́kù, kò sì ní sí ẹnìkan rárá.
Я истребил народы, разрушены твердыни их; пустыми сделал улицы их, так что никто уже не ходит по ним; разорены города их: нет ни одного человека, нет жителей.
7 Èmi wí fún ìlú náà wí pé, ‘Nítòótọ́, ìwọ yóò bẹ̀rù mi, ìwọ yóò sì gba ìtọ́ni!’ Bẹ́ẹ̀ ni, a kì yóò ké ibùgbé rẹ̀ kúrò bí ó ti wù kí ń jẹ wọ́n ní yà tó. Ṣùgbọ́n síbẹ̀ wọ́n sì tún ní ìtara láti ṣe ìbàjẹ́.
Я говорил: “бойся только Меня, принимай наставление!”, и не будет истреблено жилище его, и не постигнет его зло, какое Я постановил о нем; а они прилежно старались портить все свои действия.
8 Nítorí náà ẹ dúró dè mí,” ni Olúwa wí, “títí di ọjọ́ náà tí èmi yóò fi jẹ́rìí sí yin. Nítorí ìpinnu mi ni láti kó orílẹ̀-èdè jọ kí èmi kí ó lè kó ilẹ̀ ọba jọ àti láti da ìbínú mi jáde sórí wọn, àní gbogbo ìbínú gbígbóná mi. Nítorí gbogbo ayé ni a ó fi iná owú mi jẹ run.
Итак, ждите Меня, говорит Господь, до того дня, когда Я восстану для опустошения, ибо Мною определено собрать народы, созвать царства, чтобы излить на них негодование Мое, всю ярость гнева Моего; ибо огнем ревности Моей пожрана будет вся земля.
9 “Nígbà náà ni èmi yóò yí èdè àwọn ènìyàn padà sí èdè mímọ́, nítorí kí gbogbo wọn bá a lè máa pe orúkọ Olúwa, láti fi ọkàn kan sìn ín.
Тогда опять Я дам народам уста чистые, чтобы все призывали имя Господа и служили Ему единодушно.
10 Láti òkè odò Etiopia, àwọn olùjọsìn mi, àwọn ènìyàn mi tí ó ti fọ́nká, yóò mú ọrẹ wá fún mi.
Из заречных стран Ефиопии поклонники Мои, дети рассеянных Моих, принесут Мне дары.
11 Ní ọjọ́ náà ni a kì yóò sì dójútì nítorí gbogbo iṣẹ́ ibi ni tí ó ti ṣẹ̀ sí mi, nígbà náà ni èmi yóò mu kúrò nínú ìlú yìí, àwọn tí ń yọ̀ nínú ìgbéraga wọn. Ìwọ kì yóò sì gbéraga mọ́ ní òkè mímọ́ mi.
В тот день ты не будешь срамить себя всякими поступками твоими, какими ты грешил против Меня, ибо тогда Я удалю из среды твоей тщеславящихся твоею знатностью, и не будешь более превозноситься на святой горе Моей.
12 Ṣùgbọ́n Èmi yóò fi àwọn ọlọ́kàn tútù àti onírẹ̀lẹ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú ni àárín rẹ̀, wọn yóò sì gbẹ́kẹ̀lé orúkọ Olúwa.
Но оставлю среди тебя народ смиренный и простой, и они будут уповать на имя Господне.
13 Àwọn ìyókù Israẹli kì yóò hùwà ibi, wọn kì yóò sọ̀rọ̀ èké. Bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò rí ahọ́n àrékérekè ní ẹnu wọn. Àwọn yóò jẹun, wọn yóò sì dùbúlẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kì yóò dẹ́rùbà wọ́n.”
Остатки Израиля не будут делать неправды, не станут говорить лжи, и не найдется в устах их языка коварного, ибо сами будут пастись и покоиться, и никто не потревожит их.
14 Kọrin, ìwọ ọmọbìnrin Sioni, kígbe sókè, ìwọ Israẹli! Fi gbogbo ọkàn yọ̀, kí inú rẹ kí ó sì dùn, ìwọ ọmọbìnrin Jerusalẹmu.
Ликуй, дщерь Сиона! торжествуй, Израиль! веселись и радуйся от всего сердца, дщерь Иерусалима!
15 Olúwa ti mú ìdájọ́ rẹ wọ̀n-ọn-nì kúrò, ó sì ti ti àwọn ọ̀tá rẹ padà sẹ́yìn. Olúwa, ọba Israẹli wà pẹ̀lú rẹ; ìwọ kì yóò sì bẹ̀rù ibi kan mọ́.
Отменил Господь приговор над тобою, прогнал врага твоего! Господь, царь Израилев, посреди тебя: уже более не увидишь зла.
16 Ní ọjọ́ náà, wọn yóò sọ fún Jerusalẹmu pé, “Má ṣe bẹ̀rù Sioni; má sì ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó dẹ̀.
В тот день скажут Иерусалиму: “не бойся” - и Сиону: “да не ослабевают руки твои!”
17 Olúwa Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ, Ó ní agbára láti gbà ọ là. Yóò yọ̀ ni orí rẹ fún ayọ̀; Yóò tún ọ ṣe nínú ìfẹ́ rẹ̀, Yóò sì fi orin yọ̀ ní orí rẹ.”
Господь Бог твой среди тебя, Он силен спасти тебя; возвеселится о тебе радостью, будет милостив по любви Своей, будет торжествовать о тебе с ликованием.
18 “Èmi ó kó àwọn tí ó ń banújẹ́ fún àjọ̀dún tí a yàn jọ, àwọn tí ó jẹ́ tirẹ̀; àwọn tí ẹ̀gàn rẹ̀ jásí ẹ̀rù.
Сетующих о торжественных празднествах Я соберу: твои они, на них тяготеет поношение.
19 Ní àkókò náà ni èmi yóò dojúkọ àwọn tí ń ni yín lára, èmi yóò gba àtiro là, èmi yóò sì ṣa àwọn tí ó ti fọ́nká jọ, èmi yóò fi ìyìn àti ọlá fún wọn ní gbogbo ilẹ̀ tí a bá ti dójútì wọ́n.
Вот, Я стесню всех притеснителей твоих в то время и спасу хромлющее, и соберу рассеянное, и приведу их в почет и именитость на всей этой земле поношения их.
20 Ní àkókò náà ni èmi yóò ṣà yín jọ; nígbà náà ni èmi yóò mú un yín padà wá sílé. Èmi yóò fi ọlá àti ìyìn fún un yín láàrín gbogbo ènìyàn àgbáyé, nígbà tí èmi yóò yí ìgbèkùn yín padà bọ sípò ní ojú ara yín,” ni Olúwa wí.
В то время приведу вас и тогда же соберу вас, ибо сделаю вас именитыми и почетными между всеми народами земли, когда возвращу плен ваш перед глазами вашими, говорит Господь.