< Zechariah 9 >

1 Ọ̀rọ̀-ìmọ̀. Ọ̀rọ̀ Olúwa kọjú ìjà sí Hadiraki, Damasku ni yóò sì jẹ́ ibi ìsinmi rẹ̀; nítorí ojú Olúwa ń bẹ lára ènìyàn, àti lára gbogbo ẹ̀yà Israẹli.
λῆμμα λόγου κυρίου ἐν γῇ Σεδραχ καὶ Δαμασκοῦ θυσία αὐτοῦ διότι κύριος ἐφορᾷ ἀνθρώπους καὶ πάσας φυλὰς τοῦ Ισραηλ
2 Àti Hamati pẹ̀lú yóò ṣe ààlà rẹ̀ Tire àti Sidoni bí o tilẹ̀ ṣe ọlọ́gbọ́n gidigidi.
καὶ Εμαθ ἐν τοῖς ὁρίοις αὐτῆς Τύρος καὶ Σιδών διότι ἐφρόνησαν σφόδρα
3 Tire sì mọ odi líle fún ara rẹ̀, ó sì kó fàdákà jọ bí eruku, àti wúrà dáradára bí ẹrẹ̀ ìgboro.
καὶ ᾠκοδόμησεν Τύρος ὀχυρώματα ἑαυτῇ καὶ ἐθησαύρισεν ἀργύριον ὡς χοῦν καὶ συνήγαγεν χρυσίον ὡς πηλὸν ὁδῶν
4 Ṣùgbọ́n, Olúwa yóò kó gbogbo ohun ìní rẹ̀ lọ, yóò sì pa agbára rẹ̀ run ní ojú Òkun, a ó sì fi iná jó o run.
διὰ τοῦτο κύριος κληρονομήσει αὐτὴν καὶ πατάξει εἰς θάλασσαν δύναμιν αὐτῆς καὶ αὕτη ἐν πυρὶ καταναλωθήσεται
5 Aṣkeloni yóò rí í, yóò sì bẹ̀rù; Gasa pẹ̀lú yóò rí í, yóò sì káàánú gidigidi, àti Ekroni: nítorí tí ìrètí rẹ̀ yóò ṣákì í. Gasa yóò pàdánù ọba rẹ̀, Aṣkeloni yóò sì di ahoro.
ὄψεται Ἀσκαλὼν καὶ φοβηθήσεται καὶ Γάζα καὶ ὀδυνηθήσεται σφόδρα καὶ Ακκαρων ὅτι ᾐσχύνθη ἐπὶ τῷ παραπτώματι αὐτῆς καὶ ἀπολεῖται βασιλεὺς ἐκ Γάζης καὶ Ἀσκαλὼν οὐ μὴ κατοικηθῇ
6 Ọmọ àlè yóò sì gbé inú Aṣdodu, Èmi yóò sì gé ìgbéraga àwọn Filistini kúrò.
καὶ κατοικήσουσιν ἀλλογενεῖς ἐν Ἀζώτῳ καὶ καθελῶ ὕβριν ἀλλοφύλων
7 Èmi yóò sì mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ kúrò ni ẹnu rẹ̀, àti àwọn ohun èèwọ̀ kúrò láàrín eyín rẹ̀: ṣùgbọ́n àwọn tó ṣẹ́kù yóò jẹ́ tí Ọlọ́run wa, wọn yóò sì jẹ baálẹ̀ ní Juda, àti Ekroni ni yóò rí bí Jebusi.
καὶ ἐξαρῶ τὸ αἷμα αὐτῶν ἐκ στόματος αὐτῶν καὶ τὰ βδελύγματα αὐτῶν ἐκ μέσου ὀδόντων αὐτῶν καὶ ὑπολειφθήσεται καὶ οὗτος τῷ θεῷ ἡμῶν καὶ ἔσονται ὡς χιλίαρχος ἐν Ιουδα καὶ Ακκαρων ὡς ὁ Ιεβουσαῖος
8 Èmi yóò sì dó yí ilẹ̀ mi ká nítorí ogun àwọn tí wọ́n ń wá ohun tí wọn yóò bàjẹ́ kiri, kò sí aninilára tí yóò bori wọn mọ́: nítorí ni ìsinsin yìí ni mo fi ojú ṣọ́ wọn.
καὶ ὑποστήσομαι τῷ οἴκῳ μου ἀνάστημα τοῦ μὴ διαπορεύεσθαι μηδὲ ἀνακάμπτειν καὶ οὐ μὴ ἐπέλθῃ ἐπ’ αὐτοὺς οὐκέτι ἐξελαύνων διότι νῦν ἑώρακα ἐν τοῖς ὀφθαλμοῖς μου
9 Kún fún ayọ̀, ìwọ ọmọbìnrin Sioni, hó ìhó ayọ̀, ìwọ ọmọbìnrin Jerusalẹmu. Wò ó, ọba rẹ ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ: òdodo ni òun, ó sì ní ìgbàlà; ó ní ìrẹ̀lẹ̀, ó sì ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àní ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.
χαῖρε σφόδρα θύγατερ Σιων κήρυσσε θύγατερ Ιερουσαλημ ἰδοὺ ὁ βασιλεύς σου ἔρχεταί σοι δίκαιος καὶ σῴζων αὐτός πραῢς καὶ ἐπιβεβηκὼς ἐπὶ ὑποζύγιον καὶ πῶλον νέον
10 Èmi ó sì gbé kẹ̀kẹ́ kúrò ni Efraimu, àti ẹṣin ogun kúrò ni Jerusalẹmu, a ó sì ṣẹ́ ọrun ogun. Òun yóò sì kéde àlàáfíà sí àwọn kèfèrí. Ìjọba rẹ̀ yóò sì gbilẹ̀ láti Òkun dé Òkun, àti láti odò títí de òpin ayé.
καὶ ἐξολεθρεύσει ἅρματα ἐξ Εφραιμ καὶ ἵππον ἐξ Ιερουσαλημ καὶ ἐξολεθρευθήσεται τόξον πολεμικόν καὶ πλῆθος καὶ εἰρήνη ἐξ ἐθνῶν καὶ κατάρξει ὑδάτων ἕως θαλάσσης καὶ ποταμῶν διεκβολὰς γῆς
11 Ní tìrẹ, nítorí ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ, Èmi ó dá àwọn ìgbèkùn rẹ̀ sílẹ̀ kúrò nínú ọ̀gbun.
καὶ σὺ ἐν αἵματι διαθήκης ἐξαπέστειλας δεσμίους σου ἐκ λάκκου οὐκ ἔχοντος ὕδωρ
12 Ẹ padà sínú odi agbára yín, ẹ̀yin òǹdè ti o ni ìrètí: àní lónìí yìí èmi sọ pé, èmi o san án fún ọ ni ìlọ́po méjì.
καθήσεσθε ἐν ὀχυρώματι δέσμιοι τῆς συναγωγῆς καὶ ἀντὶ μιᾶς ἡμέρας παροικεσίας σου διπλᾶ ἀνταποδώσω σοι
13 Èmi ó fa Juda le bí mo ṣe fa ọrun mi le, mo sì fi Efraimu kún un, Èmi yóò gbé àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin dìde, ìwọ Sioni, sí àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, ìwọ Giriki, mo ṣe ọ́ bí idà alágbára.
διότι ἐνέτεινά σε Ιουδα ἐμαυτῷ τόξον ἔπλησα τὸν Εφραιμ καὶ ἐπεγερῶ τὰ τέκνα σου Σιων ἐπὶ τὰ τέκνα τῶν Ἑλλήνων καὶ ψηλαφήσω σε ὡς ῥομφαίαν μαχητοῦ
14 Olúwa yóò sì fi ara hàn ní orí wọn; ọfà rẹ̀ yóò sì jáde lọ bí mọ̀nàmọ́ná. Olúwa Olódùmarè yóò sì fọn ìpè, Òun yóò sì lọ nínú atẹ́gùn ìjì gúúsù.
καὶ κύριος ἔσται ἐπ’ αὐτοὺς καὶ ἐξελεύσεται ὡς ἀστραπὴ βολίς καὶ κύριος παντοκράτωρ ἐν σάλπιγγι σαλπιεῖ καὶ πορεύσεται ἐν σάλῳ ἀπειλῆς αὐτοῦ
15 Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò dáàbò bò wọ́n; wọn ó sì jẹ ni run, wọn ó sì tẹ òkúta kànnàkànnà mọ́lẹ̀; wọn ó sì mu ẹ̀jẹ̀ wọn bí wáìnì, wọn ó sì kún bí ọpọ́n, wọn ó sì rin ṣinṣin bí àwọn igun pẹpẹ.
κύριος παντοκράτωρ ὑπερασπιεῖ αὐτῶν καὶ καταναλώσουσιν αὐτοὺς καὶ καταχώσουσιν αὐτοὺς ἐν λίθοις σφενδόνης καὶ ἐκπίονται αὐτοὺς ὡς οἶνον καὶ πλήσουσιν ὡς φιάλας θυσιαστήριον
16 Olúwa Ọlọ́run wọn yóò sì gbà wọ́n là ni ọjọ́ náà bí agbo ènìyàn rẹ̀: nítorí wọn ó dàbí àwọn òkúta adé, tí a gbé sókè bí àmì lórí ilẹ̀ rẹ̀.
καὶ σώσει αὐτοὺς κύριος ἐν τῇ ἡμέρᾳ ἐκείνῃ ὡς πρόβατα λαὸν αὐτοῦ διότι λίθοι ἅγιοι κυλίονται ἐπὶ τῆς γῆς αὐτοῦ
17 Nítorí oore rẹ̀ tí tóbi tó, ẹwà rẹ̀ sì tí pọ̀! Ọkà yóò mú ọ̀dọ́mọkùnrin dárayá, àti ọtí wáìnì tuntun yóò mú àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.
ὅτι εἴ τι ἀγαθὸν αὐτοῦ καὶ εἴ τι καλὸν παρ’ αὐτοῦ σῖτος νεανίσκοις καὶ οἶνος εὐωδιάζων εἰς παρθένους

< Zechariah 9 >