< Zechariah 14 >

1 Kíyèsi i, ọjọ́ Olúwa ń bọ̀, a ó sì pín ìkógun rẹ̀ láàrín rẹ̀.
Behold, a day of the LORD is coming when your plunder will be divided in your presence.
2 Nítorí èmi ó kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ sí Jerusalẹmu fún ogun; a ó sì ko ìlú náà, a ó sì kó àwọn ilé, a ó sì ba àwọn obìnrin jẹ́, ààbọ̀ ìlú náà yóò lọ sí ìgbèkùn, a kì yóò sì gé ìyókù àwọn ènìyàn náà kúrò ni ìlú náà.
For I will gather all the nations for battle against Jerusalem, and the city will be captured, the houses looted, and the women ravished. Half of the city will go into exile, but the rest of the people will not be removed from the city.
3 Nígbà náà ni Olúwa yóò jáde lọ, yóò sì bá àwọn orílẹ̀-èdè náà jà, gẹ́gẹ́ bí í ti ìjà ní ọjọ́ ogun.
Then the LORD will go out to fight against those nations, as He fights in the day of battle.
4 Ẹsẹ̀ rẹ̀ yóò sì dúró ni ọjọ́ náà lórí òkè Olifi, tí ó wà níwájú Jerusalẹmu ni ìlà-oòrùn, òkè Olifi yóò sì là á sí méjì, sí ìhà ìlà-oòrùn àti ìhà ìwọ̀-oòrùn, àfonífojì ńlá ńlá yóò wà: ìdajì òkè náà yóò sì ṣí síhà àríwá, àti ìdajì rẹ̀ síhà gúúsù.
On that day His feet will stand on the Mount of Olives, east of Jerusalem, and the Mount of Olives will be split in two from east to west, forming a great valley, with half the mountain moving to the north and half to the south.
5 Ẹ̀yin ó sì sá sí àfonífojì àwọn òkè mi, nítorí pé àfonífojì òkè náà yóò dé Aseli: nítòótọ́, ẹ̀yin ó sá bí ẹ tí sá fún ìmìmì-ilẹ̀ ni ọjọ́ Ussiah ọba Juda: Olúwa Ọlọ́run mi yóò sì wá, àti gbogbo àwọn Ẹni mímọ́ pẹ̀lú rẹ̀.
You will flee by My mountain valley, for it will extend to Azal. You will flee as you fled from the earthquake in the days of Uzziah king of Judah. Then the LORD my God will come, and all the holy ones with Him.
6 Yóò sì ṣe ni ọjọ́ náà, ìmọ́lẹ̀ kì yóò mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ṣókùnkùn.
On that day there will be no light, no cold or frost.
7 Ṣùgbọ́n yóò jẹ́ ọjọ́ kan mímọ́ fún Olúwa, kì í ṣe ọ̀sán, kì í ṣe òru; ṣùgbọ́n yóò ṣe pé, ni àṣálẹ́ ìmọ́lẹ̀ yóò wà.
It will be a day known only to the LORD, without day or night; but when evening comes, there will be light.
8 Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà, omi ìyè yóò tí Jerusalẹmu sàn lọ; ìdajì wọn síhà Òkun ìlà-oòrùn, àti ìdajì wọn síhà okùn ẹ̀yìn: nígbà ẹ̀rùn àti nígbà òtútù ni yóò rí bẹ́ẹ̀.
And on that day living water will flow out from Jerusalem, half of it toward the Eastern Sea and the other half toward the Western Sea, in summer and winter alike.
9 Olúwa yóò sì jẹ ọba lórí gbogbo ayé; ni ọjọ́ náà ni Olúwa kan yóò wa orúkọ rẹ̀ nìkan náà ni orúkọ.
On that day the LORD will become King over all the earth—the LORD alone, and His name alone.
10 A ó yí gbogbo ilẹ̀ padà bi pẹ̀tẹ́lẹ̀ kan láti Geba dé Rimoni lápá gúúsù Jerusalẹmu: yóò di bí aginjù, ṣùgbọ́n a ó sì gbé Jerusalẹmu sókè, yóò sì gbe ipò rẹ̀, láti ibodè Benjamini títí dé ibi ibodè èkínní, dé ibodè igun nì, àti láti ilé ìṣọ́ Hananeli dé ibi ìfúntí wáìnì ọba.
All the land from Geba to Rimmon south of Jerusalem will be turned into a plain, but Jerusalem will be raised up and will remain in her place, from the Benjamin Gate to the site of the First Gate to the Corner Gate, and from the Tower of Hananel to the royal winepresses.
11 Ènìyàn yóò sì máa gbé ibẹ̀, kì yóò sì sí ìparun mọ́; ṣùgbọ́n a ó máa gbé Jerusalẹmu láìléwu.
People will live there, and never again will there be an utter destruction. So Jerusalem will dwell securely.
12 Èyí ni yóò sì jẹ́ ààrùn tí Olúwa yóò fi kọlu gbogbo àwọn ènìyàn ti ó tí ba Jerusalẹmu jà; ẹran-ara wọn yóò rù nígbà tí wọn dúró ni ẹsẹ̀ wọn, ojú wọn yóò sì rà ni ihò wọn, ahọ́n wọn yóò sì bàjẹ́ ni ẹnu wọn.
And this will be the plague with which the LORD strikes all the peoples who have warred against Jerusalem: Their flesh will rot while they stand on their feet, their eyes will rot in their sockets, and their tongues will rot in their mouths.
13 Yóò sì ṣe ni ọjọ́ náà, ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ńlá láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá yóò wà láàrín wọn; wọn ó sì di ọwọ́ ara wọn mú, ọwọ́ èkínní yóò sì dìde sì ọwọ́ èkejì rẹ̀.
On that day a great panic from the LORD will come upon them, so that each will seize the hand of another, and the hand of one will rise against the other.
14 Juda pẹ̀lú yóò sì jà ni Jerusalẹmu: ọrọ̀ gbogbo àwọn kèfèrí tí ó wà káàkiri ni a ó sì kójọ, wúrà àti fàdákà, àti aṣọ, ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.
Judah will also fight at Jerusalem, and the wealth of all the surrounding nations will be collected—gold, silver, and apparel in great abundance.
15 Bẹ́ẹ̀ ni ààrùn ẹṣin, ìbáaka, ìbákasẹ, àti tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, yóò sì wà, àti gbogbo ẹranko tí ń bẹ nínú àgọ́.
And a similar plague will strike the horses and mules, camels and donkeys, and all the animals in those camps.
16 Yóò sì ṣe, olúkúlùkù ẹni tí o kù nínú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó dìde sí Jerusalẹmu yóò máa gòkè lọ lọ́dọọdún láti sìn ọba, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, àti láti ṣe àjọyọ̀ àsè àgọ́ náà.
Then all the survivors from the nations that came against Jerusalem will go up year after year to worship the King, the LORD of Hosts, and to celebrate the Feast of Tabernacles.
17 Yóò sì ṣe, ẹnikẹ́ni tí kì yóò gòkè wá nínú gbogbo ìdílé ayé sí Jerusalẹmu láti sín ọba, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, òjò kì yóò rọ̀ fún wọn.
And should any of the families of the earth not go up to Jerusalem to worship the King, the LORD of Hosts, then the rain will not fall on them.
18 Bí ìdílé Ejibiti kò bá sì gòkè lọ, tí wọn kò sì wá, fi ara wọn hàn tí wọn kò ní òjò; ààrùn náà yóò wà, tí Olúwa yóò fi kọlù àwọn kèfèrí tí kò gòkè wá láti ṣe àjọyọ̀ àsè àgọ́ náà.
And if the people of Egypt will not go up and enter in, then the rain will not fall on them; this will be the plague with which the LORD strikes the nations who do not go up to celebrate the Feast of Tabernacles.
19 Èyí ni yóò sì jẹ́ ìyà Ejibiti, àti ìyà gbogbo orílẹ̀-èdè tí kò gòkè wá láti pa àsè àgọ́ mọ́.
This will be the punishment of Egypt and of all the nations that do not go up to celebrate the Feast of Tabernacles.
20 Ní ọjọ́ náà ni “mímọ́ sí Olúwa” yóò wà lára ṣaworo ẹṣin: àti àwọn ìkòkò ni ilé Olúwa yóò sì dàbí àwọn ọpọ́n tí ń bẹ níwájú pẹpẹ.
On that day, HOLY TO THE LORD will be inscribed on the bells of the horses, and the cooking pots in the house of the LORD will be like the sprinkling bowls before the altar.
21 Nítòótọ́, gbogbo ìkòkò ni Jerusalẹmu àti ni Juda yóò jẹ́ mímọ́ sí Olúwa àwọn ọmọ-ogun: àti gbogbo àwọn tí ń rú ẹbọ yóò wá, wọn ó sì mú ìkòkò díẹ̀, wọn ó sì bọ ẹran wọn nínú rẹ̀, ni ọjọ́ náà ni àwọn Kenaani kò ní sí mọ́ ni ilé Olúwa àwọn ọmọ-ogun.
Indeed, every pot in Jerusalem and Judah will be holy to the LORD of Hosts, and all who sacrifice will come and take some pots and cook in them. And on that day there will no longer be a Canaanite in the house of the LORD of Hosts.

< Zechariah 14 >