< Song of Solomon 1 >
1 Orin, àwọn orin tí í ṣe orin Solomoni.
Solomon's song of songs.
2 Fi ìfẹnukonu ìfẹ́ kò mí ní ẹnu, nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ọtí wáìnì lọ.
Kiss me, kiss me with your mouth again and again, for your love is sweeter than wine.
3 Òórùn ìkunra rẹ fanimọ́ra. Orúkọ rẹ rí bí ìkunra tí a tú jáde abájọ tí àwọn wúńdíá fi fẹ́ ọ.
I love the way you smell from the perfumed oils you use. You have quite a reputation—it spreads like spilled perfumed oil. It's not surprising that all the young women adore you!
4 Fà mí lọ pẹ̀lú rẹ, kí a lọ kíákíá ọba ti mú mi wá sínú yàrá rẹ̀. Ọ̀rẹ́ Àwa yọ̀ inú wa sì dùn sí ọ; a gbé ìfẹ́ rẹ ga ju ọtí wáìnì lọ. Olólùfẹ́ Wọ́n fẹ́ ọ nítòótọ́!
Take me by the hand—let's run! (The king has brought me to his bedroom.) Let's be happy together and find pleasure in your love. Your love is far better than wine! Women are right to adore you so!
5 Èmi dúdú mo sì ní ẹwà. Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu dúdú bí àgọ́ ìlú Kedari, bí aṣọ títa ti Solomoni.
I'm black, but I'm beautiful, women of Jerusalem, like the tents of Kedar, like the curtains of Solomon.
6 Má ṣe wò mí nítorí wí pé mo dúdú, nítorí oòrùn mú mi dúdú, ọmọkùnrin ìyá mi bínú sí mi ó sì fi mí ṣe olùtọ́jú ọgbà àjàrà; ọgbà àjàrà tèmi ni èmi kò tọ́jú.
Don't look down on me because I'm black, because the sun has burned me. My brothers were angry with me and made me look after the vineyards, so I couldn't look after my own vineyard.
7 Wí fún mi, ìwọ ẹni tí ọkàn mí fẹ́, níbo ni ìwọ ń da agbo ẹran lọ. Níbi tí ìwọ mú agbo ẹran rẹ sinmi ní ọ̀sán, kí ni ìdí tí èmi yóò fi jẹ́ obìnrin asán ní ẹ̀bá agbo ẹran àwọn ọ̀rẹ́ rẹ.
My love, please tell me where you're taking your flock. Where will you rest them at noon? For why should I have to wear a veil while looking for you among the flocks of your companions?
8 Bí ìwọ kò bá mọ̀, ìwọ arẹwà jùlọ nínú àwọn obìnrin. Bá ọ̀nà tí agbo ẹran rìn lọ, kí o sì bọ́ àwọn ọmọ ewúrẹ́ rẹ. Ní ẹ̀bá àgọ́ àwọn olùṣọ́-àgùntàn.
If you really don't know, you who are more beautiful than any other woman, then follow the tracks of my flock, and let your goats graze near the shepherd's tents.
9 Olùfẹ́ mi, mo fi ọ́ wé ẹṣin mi nínú kẹ̀kẹ́ Farao.
My darling, to me you're like a mare among Pharaoh's horses that pull his chariots,
10 Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ dára ní ohun ọ̀ṣọ́, ọrùn rẹ sì yẹ ọ̀ṣọ́ ìlẹ̀kẹ̀.
Your beautiful cheeks adorned with ornaments, your neck with strings of jewels.
11 A ó fi wúrà ṣe òrùka etí fún ọ, a ó fi fàdákà ṣe ìlẹ̀kẹ̀.
Let's make you some gold ornaments inlaid with silver.
12 Nígbà tí ọba wà ní orí ìjókòó rẹ̀, òróró ìkunra mi tú òórùn jáde.
As the king lay on his couch, my nard perfume gave off its fragrance.
13 Ìdì òjìá ni olùfẹ́ mi jẹ sí mi, òun ó sinmi lé àárín ọmú mi.
My love is like a pouch of myrrh, lying all night between my breasts.
14 Bí ìdì ìtànná Henina ni olùfẹ́ mi rí sí mi láti inú ọgbà àjàrà ti En-Gedi.
My love is like a bunch of fragrant henna flowers in the vineyards of Engedi.
15 Báwo ni o ti lẹ́wà tó, olólùfẹ́ mi! Háà, báwo ni o ṣe lẹ́wà tó! Ìwọ ní ojú ẹyẹlé.
Look at how very beautiful you are, my darling, how beautiful! Your eyes are as gentle as doves.
16 Báwo ni o ṣe dára tó, olùfẹ́ mi! Háà, báwo ni o ṣe wu ni! Ibùsùn wa ní ìtura.
And you, my love, are so handsome—how charming you are! The green grass is our bed,
17 Ìtànṣán ilé wa jẹ́ ti igi kedari ẹkẹ́ ilé wa jẹ́ ti igi firi.
with cedar trees as beams for our “house,” and pine trees for the rafters.