< Song of Solomon 8 >
1 Ìwọ ìbá rí bí arákùnrin mi si mi, èyí tí ó mú ọmú ìyá mi dàgbà! Èmi ìbá rí ọ ní òde, èmi ìbá fi ẹnu kò ọ́ ní ẹnu, wọn kì bá fi mí ṣe ẹlẹ́yà.
O that you were to me like a brother who nursed at my mother’s breasts! If I found you outdoors, I would kiss you, and no one would despise me.
2 Èmi ìbá fi ọ̀nà hàn ọ́ èmi ìbá mú ọ wá sínú ilé ìyá mi, ìwọ ìbá kọ́ mi. Èmi ìbá fi ọtí wáìnì olóòórùn dídùn fún ọ mu, àti oje èso pomegiranate mi.
I would lead you and bring you to the house of my mother who taught me. I would give you spiced wine to drink, the nectar of my pomegranates.
3 Ọwọ́ òsì rẹ ìbá wà ní abẹ́ orí mi, ọwọ́ ọ̀tún rẹ ìbá sì gbà mí mọ́ra.
His left hand is under my head, and his right arm embraces me.
4 Ọmọbìnrin Jerusalẹmu, èmi pè yín ní ìjà. Ẹ má ṣe rú olùfẹ́ mi sókè. Ẹ má ṣe jí i títí tí yóò fi wù ú.
O daughters of Jerusalem, I adjure you: Do not arouse or awaken love until the time is right.
5 Ta ni ẹni tí ń gòkè bọ̀ wá láti aginjù, tí ó fi ara ti olùfẹ́ rẹ̀. Olólùfẹ́ Ní abẹ́ igi ápù ni mo ti jí ọ dìde; níbẹ̀ ni ìyá rẹ ti lóyún rẹ níbẹ̀ ni ẹni tí ń rọbí bí ọ sí.
Who is this coming up from the wilderness, leaning on her beloved? I roused you under the apple tree; there your mother conceived you; there she travailed and brought you forth.
6 Gbé mi sí àyà rẹ bí èdìdì bí èdìdì lé apá rẹ; nítorí ìfẹ́ lágbára bí ikú, ìjowú sì le bí isà òkú jíjò rẹ̀ rí bí jíjò iná, gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́-iná Olúwa. (Sheol )
Set me as a seal over your heart, as a seal upon your arm. For love is as strong as death, its jealousy as unrelenting as Sheol. Its sparks are fiery flames, the fiercest blaze of all. (Sheol )
7 Omi púpọ̀ kò le paná ìfẹ́; bẹ́ẹ̀ ni gbígbá omi kò le gbá a lọ. Bí ènìyàn bá fún ìfẹ́, ní gbogbo ọrọ̀ ilé rẹ̀, a ó kẹ́gàn rẹ̀ pátápátá.
Mighty waters cannot quench love; rivers cannot sweep it away. If a man were to give all the wealth of his house for love, his offer would be utterly scorned.
8 Àwa ní arábìnrin kékeré kan, òun kò sì ní ọmú, kí ni àwa yóò fún arábìnrin wa, ní ọjọ́ tí a ó bá fẹ́ ẹ?
We have a little sister, and her breasts are not yet grown. What shall we do for our sister on the day she is spoken for?
9 Bí òun bá jẹ́ ògiri, àwa yóò kọ́ ilé odi fàdákà lé e lórí. Bí òun bá jẹ́ ìlẹ̀kùn, àwa yóò fi pákó kedari dí i.
If she is a wall, we will build a tower of silver upon her. If she is a door, we will enclose her with panels of cedar.
10 Èmi jẹ́ ògiri, ọmú mi sì rí bí ilé ìṣọ́ bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe rí ní ojú rẹ̀ bí ẹni tí ń mú àlàáfíà wá.
I am a wall, and my breasts are like towers. So I have become in his eyes like one who brings peace.
11 Solomoni ní ọgbà àjàrà kan ní Baali-Hamoni ó gbé ọgbà àjàrà rẹ̀ fún àwọn alágbàtọ́jú olúkúlùkù ni ó ń mú èso rẹ̀ wá ẹgbẹ̀rún fàdákà.
Solomon had a vineyard in Baal-hamon. He leased it to the tenants. For its fruit, each was to bring a thousand shekels of silver.
12 Ṣùgbọ́n ọgbà àjàrà mi jẹ́ tèmi, ó wà fún mi; ẹgbẹ̀rún ṣékélì jẹ́ tìrẹ, ìwọ Solomoni, igba sì jẹ́ ti àwọn alágbàtọ́jú èso.
But my own vineyard is mine to give; the thousand shekels are for you, O Solomon, and two hundred are for those who tend its fruit.
13 Ìwọ tí ń gbé inú ọgbà, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ dẹtí sí ohùn rẹ, jẹ́ kí èmi náà gbọ́ ohùn rẹ!
You who dwell in the gardens, my companions are listening for your voice. Let me hear it!
14 Yára wá, Olùfẹ́ mi, kí ìwọ kí ó sì rí bí abo egbin, tàbí gẹ́gẹ́ bí ọmọ àgbọ̀nrín, lórí òkè òórùn dídùn.
Come away, my beloved, and be like a gazelle or a young stag on the mountains of spices.