< Song of Solomon 7 >
1 Báwo ni ẹsẹ̀ rẹ ti ní ẹwà tó nínú bàtà. Ìwọ ọmọbìnrin ọba! Oríkèé itan rẹ rí bí ohun ọ̀ṣọ́ iṣẹ́ ọlọ́gbọ́n oníṣọ̀nà
How beautiful are your feet in sandals, prince's daughter. Your rounded thighs are like jewels, the work of the hands of a skillful workman.
2 Ìdodo rẹ rí bí àwo tí kì í ṣe aláìní ọtí, ìbàdí rẹ bí òkìtì alikama tí a fi lílì yíká.
Your body is like a round goblet, no mixed wine is wanting. Your waist is like a heap of wheat, set about with lilies.
3 Ọmú rẹ rí bí abo egbin méjì tí wọ́n jẹ́ ìbejì àgbọ̀nrín.
Your two breasts are like two fawns, that are twins of a gazelle.
4 Ọrùn rẹ rí bí ilé ìṣọ́ eyín erin. Ojú rẹ rí bí adágún ní Heṣboni ní ẹ̀bá ẹnu ibodè Bati-Rabbimu. Imú rẹ rí bí ilé ìṣọ́ Lebanoni tí ó kọ ojú sí Damasku.
Your neck is like an ivory tower. Your eyes are like the pools in Heshbon by the gate of Bathrabbim. Your nose is like the tower of Lebanon which looks toward Damascus.
5 Bí òkè Karmeli ṣe ṣe adé yí àwọn òkè ká, bẹ́ẹ̀ ni irun orí rẹ ṣe adé yí orí rẹ ká a fi àìdi irun rẹ mú ọba ní ìgbèkùn.
Your head on you is like Carmel. The hair of your head like purple. The king is held captive in its tresses.
6 Báwo ni ẹwà rẹ ti pọ̀ tó báwo ni o sì ti dára tó ìwọ olùfẹ́ mi nínú ìfẹ́?
How beautiful and how pleasant you are, love, for delights.
7 Ìdúró rẹ rí bí igi ọ̀pẹ, àti ọmú rẹ bí ìdì èso àjàrà.
This, your stature, is like a palm tree, your breasts like its fruit.
8 Mo ní, “Èmi yóò gun igi ọ̀pẹ lọ, èmi yóò di ẹ̀ka rẹ̀ mú.” Kí ọmú rẹ rí bí ìdì èso àjàrà, àti èémí imú rẹ bí i ápù.
I said, "I will climb up into the palm tree. I will take hold of its fruit." Let your breasts be like clusters of the vine, the smell of your breath like apples,
9 Àti ìfẹnukonu rẹ rí bí ọtí wáìnì tí ó dára jùlọ. Olólùfẹ́ Tí ó kúnná tí ó sì dùn, tí ń mú kí ètè àwọn tí ó sùn kí ó sọ̀rọ̀.
Your mouth like the best wine, that goes down smoothly for my beloved, gliding over my lips and my teeth.
10 Ti olùfẹ́ mi ni èmi í ṣe, èmi sì ni ẹni tí ó wù ú.
I am my beloved's. His desire is toward me.
11 Wá, olùfẹ́ mi, jẹ́ kí a lọ sí ibi pápá, jẹ́ kí a lo àṣálẹ́ ní àwọn ìletò.
Come, my beloved, let us go forth into the field. Let us lodge in the villages.
12 Jẹ́ kí a lọ sínú ọgbà àjàrà ní kùtùkùtù láti wo bí àjàrà rúwé bí ìtànná àjàrà bá là. Àti bí pomegiranate bá ti rudi, níbẹ̀ ni èmi yóò ti fi ìfẹ́ mi fún ọ.
Let's go early up to the vineyards. Let's see whether the vine has budded, its blossom is open, and the pomegranates are in flower. There I will give you my love.
13 Àwọn èso mándrákì mú òórùn wọn jáde ní ẹnu-ọ̀nà wa ni onírúurú àṣàyàn èso, èso tuntun àti ọjọ́ pípẹ́ tí mo ti kó pamọ́ fún ọ, olùfẹ́ mi.
The mandrakes give forth fragrance. At our doors are all kinds of precious fruits, new and old, which I have stored up for you, my beloved.