< Song of Solomon 6 >

1 Níbo ni olùfẹ́ rẹ lọ, ìwọ arẹwà jùlọ láàrín àwọn obìnrin? Níbo ni olùfẹ́ rẹ yà sí, kí a lè bá ọ wá a?
אָ֚נָה הָלַ֣ךְ דּוֹדֵ֔ךְ הַיָּפָ֖ה בַּנָּשִׁ֑ים אָ֚נָה פָּנָ֣ה דוֹדֵ֔ךְ וּנְבַקְשֶׁ֖נּוּ עִמָּֽךְ׃
2 Olùfẹ́ mi ti sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ọgbà rẹ̀, sí ibi ibùsùn tùràrí, láti máa jẹ nínú ọgbà láti kó ìtànná lílì jọ.
דּוֹדִי֙ יָרַ֣ד לְגַנּ֔וֹ לַעֲרוּג֖וֹת הַבֹּ֑שֶׂם לִרְעוֹת֙ בַּגַּנִּ֔ים וְלִלְקֹ֖ט שֽׁוֹשַׁנִּֽים׃
3 Èmi ni ti olùfẹ́ mi, olùfẹ́ mi sì ni tèmi, Ó ń jẹ láàrín ìtànná lílì.
אֲנִ֤י לְדוֹדִי֙ וְדוֹדִ֣י לִ֔י הָרֹעֶ֖ה בַּשׁוֹשַׁנִּֽים׃ ס
4 Ìwọ lẹ́wà olùfẹ́ mi, bí i Tirsa, ìwọ lẹ́wà bí i Jerusalẹmu, ìwọ ògo bí ogun pẹ̀lú ọ̀págun.
יָפָ֨ה אַ֤תְּ רַעְיָתִי֙ כְּתִרְצָ֔ה נָאוָ֖ה כִּירוּשָׁלִָ֑ם אֲיֻמָּ֖ה כַּנִּדְגָּלֽוֹת׃
5 Yí ojú rẹ kúrò lára mi; nítorí ojú rẹ borí mi. Irun rẹ rí bí i ọ̀wọ́ ewúrẹ́ tí ó sọ̀kalẹ̀ wá láti Gileadi.
הָסֵ֤בִּי עֵינַ֙יִךְ֙ מִנֶּגְדִּ֔י שֶׁ֥הֵ֖ם הִרְהִיבֻ֑נִי שַׂעְרֵךְ֙ כְּעֵ֣דֶר הָֽעִזִּ֔ים שֶׁגָּלְשׁ֖וּ מִן־הַגִּלְעָֽד ׃
6 Eyín rẹ rí bí ọ̀wọ́ àgùntàn, tí ó gòkè láti ibi ìwẹ̀ rẹ̀ wá, gbogbo wọn bí ìbejì, kò sì ṣí ọ̀kankan tí ó yàgàn nínú wọn.
שִׁנַּ֙יִךְ֙ כְּעֵ֣דֶר הָֽרְחֵלִ֔ים שֶׁעָל֖וּ מִן־הָרַחְצָ֑ה שֶׁכֻּלָּם֙ מַתְאִימ֔וֹת וְשַׁכֻּלָ֖ה אֵ֥ין בָּהֶֽם׃
7 Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ lẹ́bàá ìbòjú rẹ, rí bí ẹ̀là èso pomegiranate.
כְּפֶ֤לַח הָרִמּוֹן֙ רַקָּתֵ֔ךְ מִבַּ֖עַד לְצַמָּתֵֽךְ׃
8 Ọgọ́ta ayaba ní ń bẹ níbẹ̀, àti ọgọ́rin àlè, àti àwọn wúńdíá láìníye.
שִׁשִּׁ֥ים הֵ֙מָּה֙ מְּלָכ֔וֹת וּשְׁמֹנִ֖ים פִּֽילַגְשִׁ֑ים וַעֲלָמ֖וֹת אֵ֥ין מִסְפָּֽר׃
9 Àdàbà mi, aláìlábàwọ́n mi, ọ̀kan ni, ọ̀kan ṣoṣo ọmọbìnrin ìyá rẹ̀, ààyò ẹyọ kan ṣoṣo ẹni tí ó bí i. Àwọn obìnrin rí i wọ́n pè é ní alábùkún fún àwọn ayaba àti àwọn àlè gbé oríyìn fún un.
אַחַ֥ת הִיא֙ יוֹנָתִ֣י תַמָּתִ֔י אַחַ֥ת הִיא֙ לְאִמָּ֔הּ בָּרָ֥ה הִ֖יא לְיֽוֹלַדְתָּ֑הּ רָא֤וּהָ בָנוֹת֙ וַֽיְאַשְּׁר֔וּהָ מְלָכ֥וֹת וּפִֽילַגְשִׁ֖ים וַֽיְהַלְלֽוּהָ׃ ס
10 Ta ni èyí tí ó tàn jáde bí i ìràwọ̀ òwúrọ̀, tí ó dára bí òṣùpá, tí ó mọ́lẹ̀ bí oòrùn, tí ó ní ẹ̀rù bí i jagunjagun pẹ̀lú ọ̀págun?
מִי־זֹ֥את הַנִּשְׁקָפָ֖ה כְּמוֹ־שָׁ֑חַר יָפָ֣ה כַלְּבָנָ֗ה בָּרָה֙ כַּֽחַמָּ֔ה אֲיֻמָּ֖ה כַּנִּדְגָּלֽוֹת׃ ס
11 Èmi sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibi ọgbà èso igi láti wo àwọn ẹ̀ka igi tuntun ní àfonífojì, láti rí i bí àjàrà rúwé, tàbí bí pomegiranate ti rudi.
אֶל־גִּנַּ֤ת אֱגוֹז֙ יָרַ֔דְתִּי לִרְא֖וֹת בְּאִבֵּ֣י הַנָּ֑חַל לִרְאוֹת֙ הֲפָֽרְחָ֣ה הַגֶּ֔פֶן הֵנֵ֖צוּ הָרִמֹּנִֽים׃
12 Kí èmi tó mọ̀, àárẹ̀ ọkàn mú mi, mo sì fẹ́ kí ń wà láàrín àwọn ènìyàn mi.
לֹ֣א יָדַ֔עְתִּי נַפְשִׁ֣י שָׂמַ֔תְנִי מַרְכְּב֖וֹת עַמִּי־נָדִֽיב׃
13 Padà wá, padà wá, ìwọ ọmọ Ṣulamati; padà wá, padà wá, kí àwa kí ó lè yọ́ ọ wò. Olùfẹ́ Èéṣe tí ẹ̀yin fẹ́ yọ́ Ṣulamati wò, bí ẹni pé orin ijó Mahanaimu?
שׁ֤וּבִי שׁ֙וּבִי֙ הַשּׁ֣וּלַמִּ֔ית שׁ֥וּבִי שׁ֖וּבִי וְנֶחֱזֶה־בָּ֑ךְ מַֽה־תֶּחֱזוּ֙ בַּשּׁ֣וּלַמִּ֔ית כִּמְחֹלַ֖ת הַֽמַּחֲנָֽיִם׃

< Song of Solomon 6 >