< Romans 9 >
1 Òtítọ́ ni èmi ń sọ nínú Kristi, èmi kò ṣèké, ọkàn mi sì ń jẹ́ mi ní ẹ̀rí nínú Ẹ̀mí Mímọ́.
I SAY the truth in Christ, I lie not, my conscience also bearing me witness in the Holy Ghost,
2 Pé mo ní ìbìnújẹ́ púpọ̀, àti ìkáàánú ìgbà gbogbo ni ọkàn mi.
That I have great heaviness and continual sorrow in my heart.
3 Nítorí mo fẹ́rẹ lè gbàdúrà pé kí èmi tìkára mi kúrò lọ́dọ̀ Kristi nítorí àwọn ará mi, àwọn ìbátan mi nípa ti ara.
For I could wish that myself were accursed from Christ for my brethren, my kinsmen according to the flesh:
4 Àwọn ẹni tí i ṣe Israẹli; tí àwọn ẹni tí ìsọdọmọ í ṣe, àti ògo, àti májẹ̀mú, àti ìfúnilófin, àti ìsìn Ọlọ́run, àti àwọn ìlérí.
Who are Israelites; to whom pertaineth the adoption, and the glory, and the covenants, and the giving of the law, and the service of God, and the promises;
5 Tí ẹni tí àwọn Baba í ṣe, àti láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹni tí Kristi ti wá nípa ti ara, ẹni tí ó borí ohun gbogbo, Ọlọ́run olùbùkún láéláé. Àmín. (aiōn )
Whose are the fathers, and of whom as concerning the flesh Christ came, who is over all, God blessed for ever. Amen. (aiōn )
6 Ṣùgbọ́n kì í ṣe pé nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di asán. Kì í sá í ṣe gbogbo àwọn tí ó ti inú Israẹli wá, àwọn ni Israẹli.
Not as though the word of God hath taken none effect. For they are not all Israel, which are of Israel:
7 Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pé, nítorí wọ́n jẹ́ irú-ọmọ Abrahamu, gbogbo wọn ni ọmọ. Ní ọ̀nà mìíràn, “Nínú Isaaki ni a ó ti pe irú-ọmọ rẹ̀.”
Neither, because they are the seed of Abraham, are they all children: but, In Isaac shall thy seed be called.
8 Èyí nì ni pé, kì í ṣe àwọn ọmọ nípa ti ara ni ọmọ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ìlérí ni a kà ní irú-ọmọ.
That is, They which are the children of the flesh, these are not the children of God: but the children of the promise are counted for the seed.
9 Nítorí ọ̀rọ̀ ìlérí ni èyí: “Ní ìwòyí àmọ́dún ni èmi yóò wá, Sara yóò sì ní ọmọ ọkùnrin.”
For this is the word of promise, At this time will I come, and Sara shall have a son.
10 Kì í sì í ṣe kìkì èyí, ṣùgbọ́n nígbà tí Rebeka pẹ̀lú lóyún fún ẹnìkan, fún Isaaki baba wa.
And not only this; but when Rebecca also had conceived by one, even by our father Isaac;
11 Nítorí nígbà tí kò tí ì bí àwọn ọmọ náà, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tí ì ṣe rere tàbí búburú—kí ìpinnu Ọlọ́run nípa ti ìyànfẹ́ kí ó lè dúró,
(For the children being not yet born, neither having done any good or evil, that the purpose of God according to election might stand, not of works, but of him that calleth; )
12 kì í ṣe nípa ti iṣẹ́, bí kò ṣe ti ẹni tí ń peni—a ti sọ fún un pé, “Ẹ̀gbọ́n ni yóò máa sin àbúrò.”
It was said unto her, The elder shall serve the younger.
13 Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Jakọbu ni mo fẹ́ràn, ṣùgbọ́n Esau ni mo kórìíra.”
As it is written, Jacob have I loved, but Esau have I hated.
14 Ǹjẹ́ àwa yóò ha ti wí? Àìṣòdodo ha wà lọ́dọ̀ Ọlọ́run bí? Kí a má ri!
What shall we say then? Is there unrighteousness with God? God forbid.
15 Nítorí ó wí fún Mose pé, “Èmi ó ṣàánú fún ẹni tí èmi yóò ṣàánú fún, èmi yóò sì ṣe ìyọ́nú fún ẹni tí èmi yóò ṣe ìyọ́nú fún.”
For he saith to Moses, I will have mercy on whom I will have mercy, and I will have compassion on whom I will have compassion.
16 Ǹjẹ́ bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ti ẹni tí ó fẹ́, kì í sì í ṣe ti ẹni tí ń sáré, bí kò ṣe ti Ọlọ́run tí ń ṣàánú.
So then it is not of him that willeth, nor of him that runneth, but of God that sheweth mercy.
17 Nítorí ìwé mímọ́ wí fún Farao pé, “Nítorí èyí náà ni mo ṣe gbé ọ dìde, kí èmi kí ó le fi agbára mi hàn lára rẹ, àti kí a bá à le máa ròyìn orúkọ mi ká gbogbo ayé.”
For the scripture saith unto Pharaoh, Even for this same purpose have I raised thee up, that I might shew my power in thee, and that my name might be declared throughout all the earth.
18 Nítorí náà ni ó ṣe ń ṣàánú fún ẹni tí ó wù ú, ẹni tí ó wù ú a sì mú ní ọkàn le.
Therefore hath he mercy on whom he will have mercy, and whom he will he hardeneth.
19 Ìwọ ó sì wí fún mi pé, “Kín ni ó ha tún bá ni wí sí? Nítorí ta ni ó ń de ìfẹ́ rẹ lọ́nà?”
Thou wilt say then unto me, Why doth he yet find fault? For who hath resisted his will?
20 Bẹ́ẹ̀ kọ́, ìwọ ènìyàn, tà ni ìwọ tí ń dá Ọlọ́run lóhùn? “Ohun tí a mọ, a ha máa wí fún ẹni tí ó mọ ọ́n pé, ‘Èéṣe tí ìwọ fi mọ mi báyìí?’”
Nay but, O man, who art thou that repliest against God? Shall the thing formed say to him that formed it, Why hast thou made me thus?
21 Amọ̀kòkò kò ha ni agbára lórí amọ̀, nínú ìṣù kan náà láti ṣe apá kan nínú ohun èlò sí ọlá, àti apá kan nínú ohun èlò sí àìlọ́lá?
Hath not the potter power over the clay, of the same lump to make one vessel unto honour, and another unto dishonour?
22 Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run bá fẹ́ fi ìbínú rẹ̀ hàn ń kọ́? Tí ó sì fẹ́ sọ agbára rẹ̀ di mí mọ̀, tí ó sì mú sùúrù púpọ̀ fún àwọn ohun èlò ìbínú tí a ṣe fún ìparun.
What if God, willing to shew his wrath, and to make his power known, endured with much longsuffering the vessels of wrath fitted to destruction:
23 Àti kí ó lè sọ ọ̀rọ̀ ògo rẹ̀ di mí mọ̀ lára àwọn ohun èlò àánú tí ó ti pèsè ṣáájú fún ògo.
And that he might make known the riches of his glory on the vessels of mercy, which he had afore prepared unto glory,
24 Àní àwa, tí ó ti pè, kì í ṣe nínú àwọn Júù nìkan, ṣùgbọ́n nínú àwọn Kèfèrí pẹ̀lú?
Even us, whom he hath called, not of the Jews only, but also of the Gentiles?
25 Bí ó ti wí pẹ̀lú ní Hosea pé, “Èmi ó pe àwọn tí kì í ṣe ènìyàn mi, ní ‘ènìyàn mi’, àti ẹni tí kí í ṣe àyànfẹ́ ní ‘àyànfẹ́.’”
As he saith also in Osee, I will call them my people, which were not my people; and her beloved, which was not beloved.
26 Yóò sì ṣe, “Ní ibi ti a gbé ti sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin kì í ṣe ènìyàn mi,’ níbẹ̀ ni a ó gbé pè wọ́n ní ‘ọmọ Ọlọ́run alààyè.’”
And it shall come to pass, that in the place where it was said unto them, Ye are not my people; there shall they be called the children of the living God.
27 Isaiah sì kígbe nítorí Israẹli pé: “Bí iye àwọn ọmọ Israẹli bá rí bí iyanrìn Òkun, apá kan ni ó gbàlà.
Esaias also crieth concerning Israel, Though the number of the children of Israel be as the sand of the sea, a remnant shall be saved:
28 Nítorí Olúwa yóò mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé, yóò parí rẹ̀, yóò sì ké e kúrò ní òdodo.”
For he will finish the work, and cut it short in righteousness: because a short work will the Lord make upon the earth.
29 Àti bí Isaiah ti wí tẹ́lẹ̀: “Bí kò ṣe bí Olúwa àwọn Ọmọ-ogun ti fi irú-ọmọ sílẹ̀ fún wa, àwa ìbá ti dàbí Sodomu, a bá sì ti sọ wá dàbí Gomorra.”
And as Esaias said before, Except the Lord of Sabaoth had left us a seed, we had been as Sodoma, and been made like unto Gomorrha.
30 Ǹjẹ́ kí ni àwa ó ha wí? Pé àwọn Kèfèrí, tí kò lépa òdodo, ọwọ́ wọn tẹ òdodo, ṣùgbọ́n òdodo tí ó ti inú ìgbàlà wá ni.
What shall we say then? That the Gentiles, which followed not after righteousness, have attained to righteousness, even the righteousness which is of faith.
31 Ṣùgbọ́n Israẹli ti ń lépa òfin òdodo, ọwọ́ wọn kò tẹ òfin òdodo.
But Israel, which followed after the law of righteousness, hath not attained to the law of righteousness.
32 Nítorí kí ni? Nítorí wọn kò wá a nípa ìgbàgbọ́, ṣùgbọ́n bí ẹni pé nípa iṣẹ́ òfin. Nítorí wọn kọsẹ̀ lára òkúta ìkọ̀sẹ̀ ni.
Wherefore? Because they sought it not by faith, but as it were by the works of the law. For they stumbled at that stumblingstone;
33 Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Kíyèsi, mo gbé òkúta ìkọ̀sẹ̀ kalẹ̀ ní Sioni àti àpáta tí ó mú wọn ṣubú, ẹnikẹ́ni ti ó bá sì gbà a gbọ́, ojú kì yóò tì í.”
As it is written, Behold, I lay in Sion a stumblingstone and rock of offence: and whosoever believeth on him shall not be ashamed.