< Romans 11 >

1 Ǹjẹ́ mo ní, Ọlọ́run ha ta àwọn ènìyàn rẹ̀ nù bí? Kí a má ri. Nítorí Israẹli ni èmi pẹ̀lú, láti inú irú-ọmọ Abrahamu, ni ẹ̀yà Benjamini.
λεγω ουν μη απωσατο ο θεος τον λαον αυτου μη γενοιτο και γαρ εγω ισραηλιτης ειμι εκ σπερματος αβρααμ φυλης βενιαμιν
2 Ọlọ́run kò ta àwọn ènìyàn rẹ̀ nù ti ó ti mọ̀ tẹ́lẹ̀. Tàbí ẹ̀yin kò mọ bí ìwé mímọ́ ti wí ní ti Elijah? Bí ó ti ń bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run fún Israẹli, wí pé:
ουκ απωσατο ο θεος τον λαον αυτου ον προεγνω η ουκ οιδατε εν ηλια τι λεγει η γραφη ως εντυγχανει τω θεω κατα του ισραηλ λεγων
3 “Olúwa, wọ́n ti pa àwọn wòlíì rẹ, wọn sì ti wó àwọn pẹpẹ rẹ lulẹ̀; èmi nìkan ṣoṣo ni ó sì kù, wọ́n sì ń wá ẹ̀mí mi.”
κυριε τους προφητας σου απεκτειναν και τα θυσιαστηρια σου κατεσκαψαν καγω υπελειφθην μονος και ζητουσιν την ψυχην μου
4 Ṣùgbọ́n ìdáhùn wo ni Ọlọ́run fi fún un? “Mo ti ṣẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin ènìyàn kù sílẹ̀ fún ara mi, àwọn tí kò tẹ eékún ba fún Baali.”
αλλα τι λεγει αυτω ο χρηματισμος κατελιπον εμαυτω επτακισχιλιους ανδρας οιτινες ουκ εκαμψαν γονυ τη βααλ
5 Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ sì ni, ní àkókò yìí àṣẹ́kù àwọn ènìyàn kan wà nípa ìyànfẹ́ ti oore-ọ̀fẹ́.
ουτως ουν και εν τω νυν καιρω λειμμα κατ εκλογην χαριτος γεγονεν
6 Bí ó bá sì ṣe pé nípa ti oore-ọ̀fẹ́ ni, ǹjẹ́ kì í ṣe ti iṣẹ́ mọ́; bí bẹ́ẹ̀ kọ́ oore-ọ̀fẹ́ kì yóò jẹ́ oore-ọ̀fẹ́ mọ́. Ṣùgbọ́n bí ó ṣe pé nípa ti iṣẹ́ ni, ǹjẹ́ kì í ṣe ti oore-ọ̀fẹ́ mọ́; bí bẹ́ẹ̀ kọ́, iṣẹ́ kì í ṣe iṣẹ́ mọ́.
ει δε χαριτι ουκετι εξ εργων επει η χαρις ουκετι γινεται χαρις ει δε εξ εργων ουκετι εστιν χαρις επει το εργον ουκετι εστιν εργον
7 Kí ha ni? Ohun tí Israẹli ń wá kiri, òun náà ni kò rí; ṣùgbọ́n àwọn ẹni àyànfẹ́ ti rí i, a sì sé àyà àwọn ìyókù le.
τι ουν ο επιζητει ισραηλ τουτου ουκ επετυχεν η δε εκλογη επετυχεν οι δε λοιποι επωρωθησαν
8 Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé: “Ọlọ́run ti fún wọn ní ẹ̀mí oorun, àwọn ojú tí kò le ríran àti àwọn etí tí kò le gbọ́rọ̀, títí ó fi di òní olónìí yìí.”
καθως γεγραπται εδωκεν αυτοις ο θεος πνευμα κατανυξεως οφθαλμους του μη βλεπειν και ωτα του μη ακουειν εως της σημερον ημερας
9 Dafidi sì wí pé: “Jẹ́ kí tábìlì wọn kí ó di ìdẹ̀kùn àti tàkúté, ohun ìkọ̀sẹ̀ àti ẹ̀san fún wọn.
και δαβιδ λεγει γενηθητω η τραπεζα αυτων εις παγιδα και εις θηραν και εις σκανδαλον και εις ανταποδομα αυτοις
10 Jẹ́ kí ojú wọn ṣókùnkùn, kí wọn kí ó má le ríran, Kí wọn kí ó sì tẹ ẹ̀yìn wọn ba nígbà gbogbo.”
σκοτισθητωσαν οι οφθαλμοι αυτων του μη βλεπειν και τον νωτον αυτων διαπαντος συγκαμψον
11 Ǹjẹ́ mo ní, wọ́n ha kọsẹ̀ kí wọn kí ó lè ṣubú? Kí a má ri i, ṣùgbọ́n nípa ìṣubú wọn, ìgbàlà dé ọ̀dọ̀ àwọn Kèfèrí, láti mú Israẹli jowú.
λεγω ουν μη επταισαν ινα πεσωσιν μη γενοιτο αλλα τω αυτων παραπτωματι η σωτηρια τοις εθνεσιν εις το παραζηλωσαι αυτους
12 Ṣùgbọ́n bí ìṣubú wọn bá di ọrọ̀ ayé, àti bí ìfàsẹ́yìn wọn bá di ọrọ̀ àwọn Kèfèrí; mélòó mélòó ni kíkún ọrọ̀ wọn?
ει δε το παραπτωμα αυτων πλουτος κοσμου και το ηττημα αυτων πλουτος εθνων ποσω μαλλον το πληρωμα αυτων
13 Ẹ̀yin tí i ṣe Kèfèrí ni èmi sá à ń bá sọ̀rọ̀, níwọ̀n bí èmi ti jẹ́ aposteli àwọn Kèfèrí, mo gbé oyè mi ga
υμιν γαρ λεγω τοις εθνεσιν εφ οσον μεν ειμι εγω εθνων αποστολος την διακονιαν μου δοξαζω
14 bí ó le ṣe kí èmi kí ó lè mú àwọn ará mi jowú, àti kí èmi kí ó lè gba díẹ̀ là nínú wọn.
ει πως παραζηλωσω μου την σαρκα και σωσω τινας εξ αυτων
15 Nítorí bí títanù wọn bá jẹ́ ìlàjà ayé, gbígbà wọn yóò ha ti rí, bí kò sí ìyè kúrò nínú òkú?
ει γαρ η αποβολη αυτων καταλλαγη κοσμου τις η προσληψις ει μη ζωη εκ νεκρων
16 Ǹjẹ́ bí àkọ́so bá jẹ́ mímọ́, bẹ́ẹ̀ ni àkópọ̀ yóò jẹ́ mímọ́; bí gbòǹgbò bá sì jẹ́ mímọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ẹ̀ka rẹ̀ náà.
ει δε η απαρχη αγια και το φυραμα και ει η ριζα αγια και οι κλαδοι
17 Ṣùgbọ́n bí a bá ya nínú àwọn ẹ̀ka kúrò, tí a sì lọ́ ìwọ, tí í ṣe igi òróró igbó sára wọn, tí ìwọ sì ń bá wọn pín nínú gbòǹgbò àti ọ̀rá igi olifi náà,
ει δε τινες των κλαδων εξεκλασθησαν συ δε αγριελαιος ων ενεκεντρισθης εν αυτοις και συγκοινωνος της ριζης και της πιοτητος της ελαιας εγενου
18 má ṣe ṣe féfé sí àwọn ẹ̀ka igi náà. Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá ṣe féfé, ìwọ kọ́ ni ó rù gbòǹgbò, ṣùgbọ́n gbòǹgbò ni ó rù ìwọ.
μη κατακαυχω των κλαδων ει δε κατακαυχασαι ου συ την ριζαν βασταζεις αλλ η ριζα σε
19 Ǹjẹ́ ìwọ ó wí pé, “A ti fa àwọn ẹ̀ka náà ya, nítorí kí a lè lọ́ mi sínú rẹ̀.”
ερεις ουν εξεκλασθησαν οι κλαδοι ινα εγω εγκεντρισθω
20 Ó dára; nítorí àìgbàgbọ́ ni a ṣe fà wọn ya kúrò, ìwọ sì dúró nípa ìgbàgbọ́ rẹ. Má ṣe gbé ara rẹ ga, ṣùgbọ́n bẹ̀rù.
καλως τη απιστια εξεκλασθησαν συ δε τη πιστει εστηκας μη υψηλοφρονει αλλα φοβου
21 Nítorí bí Ọlọ́run kò bá dá ẹ̀ka-ìyẹ́ka sí, kíyèsára kí ó má ṣe ṣe àìdá ìwọ náà sí.
ει γαρ ο θεος των κατα φυσιν κλαδων ουκ εφεισατο μηπως ουδε σου φεισηται
22 Nítorí náà wo oore àti ìkáàánú Ọlọ́run; lórí àwọn tí ó ṣubú, ìkáàánú; ṣùgbọ́n lórí ìwọ, oore, bi ìwọ bá dúró nínú oore rẹ̀; kí a má bá ké ìwọ náà kúrò.
ιδε ουν χρηστοτητα και αποτομιαν θεου επι μεν τους πεσοντας αποτομιαν επι δε σε χρηστοτητα εαν επιμεινης τη χρηστοτητι επει και συ εκκοπηση
23 Àti àwọn pẹ̀lú, bí wọn kò bá jókòó sínú àìgbàgbọ́, a ó lọ́ wọn sínú rẹ̀, nítorí Ọlọ́run le tún wọn lọ́ sínú rẹ̀.
και εκεινοι δε εαν μη επιμεινωσιν τη απιστια εγκεντρισθησονται δυνατος γαρ εστιν ο θεος παλιν εγκεντρισαι αυτους
24 Nítorí bí a bá ti ké ìwọ kúrò lára igi òróró igbó nípa ẹ̀dá rẹ̀, tí a sì lọ́ ìwọ sínú igi òróró rere lòdì sí ti ẹ̀dá; mélòó mélòó ni a ó lọ́ àwọn wọ̀nyí, tí í ṣe ẹ̀ka-ìyẹ́ka sára igi òróró wọn?
ει γαρ συ εκ της κατα φυσιν εξεκοπης αγριελαιου και παρα φυσιν ενεκεντρισθης εις καλλιελαιον ποσω μαλλον ουτοι οι κατα φυσιν εγκεντρισθησονται τη ιδια ελαια
25 Ará, èmi kò ṣá fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó wà ní òpè ní ti ohun ìjìnlẹ̀ yìí, kí ẹ̀yin má ba á ṣe ọlọ́gbọ́n ní ojú ara yín, pé ìfọ́jú bá Israẹli ní apá kan, títí kíkún àwọn Kèfèrí yóò fi dé.
ου γαρ θελω υμας αγνοειν αδελφοι το μυστηριον τουτο ινα μη ητε παρ εαυτοις φρονιμοι οτι πωρωσις απο μερους τω ισραηλ γεγονεν αχρις ου το πληρωμα των εθνων εισελθη
26 Bẹ́ẹ̀ ni a ó sì gba gbogbo Israẹli là, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé: “Ní Sioni ni Olùgbàlà yóò ti jáde wá, yóò sì yìí àìwà-bí-Ọlọ́run kúrò lọ́dọ̀ Jakọbu.
και ουτως πας ισραηλ σωθησεται καθως γεγραπται ηξει εκ σιων ο ρυομενος και αποστρεψει ασεβειας απο ιακωβ
27 Èyí sì ni májẹ̀mú mi pẹ̀lú wọn. Nígbà tí èmi yóò mú ẹ̀ṣẹ̀ wọn kúrò.”
και αυτη αυτοις η παρ εμου διαθηκη οταν αφελωμαι τας αμαρτιας αυτων
28 Nípa ti ìyìnrere, ọ̀tá ni wọ́n nítorí yín; bí ó sì ṣe ti ìyànfẹ́ ni, olùfẹ́ ni wọ́n nítorí ti àwọn baba.
κατα μεν το ευαγγελιον εχθροι δι υμας κατα δε την εκλογην αγαπητοι δια τους πατερας
29 Nítorí àìlábámọ̀ ni ẹ̀bùn àti ìpè Ọlọ́run.
αμεταμελητα γαρ τα χαρισματα και η κλησις του θεου
30 Nítorí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin kò ti gba Ọlọ́run gbọ́ rí, ṣùgbọ́n nísinsin yìí tí ẹ̀yin rí àánú gbà nípa àìgbàgbọ́ wọn.
ωσπερ γαρ και υμεις ποτε ηπειθησατε τω θεω νυν δε ηλεηθητε τη τουτων απειθεια
31 Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àwọn wọ̀nyí tí ó ṣe àìgbọ́ràn nísinsin yìí, kí àwọn pẹ̀lú bá le rí àánú gbà nípa àánú tí a fihàn yín.
ουτως και ουτοι νυν ηπειθησαν τω υμετερω ελεει ινα και αυτοι ελεηθωσιν
32 Nítorí Ọlọ́run sé gbogbo wọn mọ́ pọ̀ sínú àìgbàgbọ́, kí ó le ṣàánú fún gbogbo wọn. (eleēsē g1653)
συνεκλεισεν γαρ ο θεος τους παντας εις απειθειαν ινα τους παντας ελεηση (eleēsē g1653)
33 A! Ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run! Àwámárídìí ìdájọ́ rẹ̀ ti rí, ọ̀nà rẹ̀ sì jù àwárí lọ!
ω βαθος πλουτου και σοφιας και γνωσεως θεου ως ανεξερευνητα τα κριματα αυτου και ανεξιχνιαστοι αι οδοι αυτου
34 “Nítorí ta ni ó mọ ọkàn Olúwa? Tàbí ta ni í ṣe ìgbìmọ̀ rẹ̀?”
τις γαρ εγνω νουν κυριου η τις συμβουλος αυτου εγενετο
35 “Tàbí ta ni ó kọ́ fi fún un, tí a kò sì san padà fún un?”
η τις προεδωκεν αυτω και ανταποδοθησεται αυτω
36 Nítorí láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti nípa rẹ̀, àti fún un ni ohun gbogbo; ẹni tí ògo wà fún láéláé! Àmín. (aiōn g165)
οτι εξ αυτου και δι αυτου και εις αυτον τα παντα αυτω η δοξα εις τους αιωνας αμην (aiōn g165)

< Romans 11 >