< Romans 10 >

1 Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, ìfẹ́ ọkàn àti àdúrà mi sí Ọlọ́run fún àwọn ènìyàn Israẹli ni kí wọ́n le ní ìgbàlà.
αδελφοι η μεν ευδοκια της εμης καρδιας και η δεησις η προς τον θεον υπερ του ισραηλ εστιν εις σωτηριαν
2 Nítorí mo gba ẹ̀rí wọn jẹ́ wí pé, wọ́n ní ìtara fún Ọlọ́run, ṣùgbọ́n kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀.
μαρτυρω γαρ αυτοις οτι ζηλον θεου εχουσιν αλλ ου κατ επιγνωσιν
3 Nítorí bí wọn kò tí mọ òdodo Ọlọ́run, tí wọ́n si ń wá ọ̀nà láti gbé òdodo ara wọn kalẹ̀, wọn kò tẹríba fún òdodo Ọlọ́run.
αγνοουντες γαρ την του θεου δικαιοσυνην και την ιδιαν δικαιοσυνην ζητουντες στησαι τη δικαιοσυνη του θεου ουχ υπεταγησαν
4 Nítorí Kristi ni òpin òfin sí òdodo fún olúkúlùkù ẹni tí ó gbà á gbọ́.
τελος γαρ νομου χριστος εις δικαιοσυνην παντι τω πιστευοντι
5 Mose ṣá kọ èyí nípa òdodo tí í ṣe ti òfin pé, “Ẹni tí ó ba ṣe, yóò yè nípa wọn.”
μωσης γαρ γραφει την δικαιοσυνην την εκ του νομου οτι ο ποιησας αυτα ανθρωπος ζησεται εν αυτοις
6 Ṣùgbọ́n òdodo tí í ṣe ìgbàgbọ́ wí pé, “Má ṣe wí ni ọkàn rẹ̀ pé, ‘Ta ni yóò gòkè lọ si ọ̀run?’” (èyí ni, láti mú Kristi sọ̀kalẹ̀),
η δε εκ πιστεως δικαιοσυνη ουτως λεγει μη ειπης εν τη καρδια σου τις αναβησεται εις τον ουρανον τουτ εστιν χριστον καταγαγειν
7 “tàbí, ‘Ta ni yóò sọ̀kalẹ̀ lọ si ọ̀gbun?’” (èyí ni, láti mú Kristi gòkè ti inú òkú wá). (Abyssos g12)
η τις καταβησεται εις την αβυσσον τουτ εστιν χριστον εκ νεκρων αναγαγειν (Abyssos g12)
8 Ṣùgbọ́n kí ni ó wí? “Ọ̀rọ̀ náà wà létí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ní ẹnu rẹ̀, àti ní ọkàn rẹ̀,” èyí nì ni ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́, tí àwa ń wàásù pé:
αλλα τι λεγει εγγυς σου το ρημα εστιν εν τω στοματι σου και εν τη καρδια σου τουτ εστιν το ρημα της πιστεως ο κηρυσσομεν
9 Bí ìwọ bá fi ẹnu rẹ̀ jẹ́wọ́ “Jesu ní Olúwa,” tí ìwọ si gbàgbọ́ ní ọkàn rẹ pé, Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òku, a ó gbà ọ́ là.
οτι εαν ομολογησης εν τω στοματι σου κυριον ιησουν και πιστευσης εν τη καρδια σου οτι ο θεος αυτον ηγειρεν εκ νεκρων σωθηση
10 Nítorí ọkàn ni a fi ìgbàgbọ́ sí òdodo; ẹnu ni a sì ń fi ìjẹ́wọ́ sí ìgbàlà.
καρδια γαρ πιστευεται εις δικαιοσυνην στοματι δε ομολογειται εις σωτηριαν
11 Nítorí Ìwé Mímọ́ wí pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà a gbọ́ ojú kò yóò tì í.”
λεγει γαρ η γραφη πας ο πιστευων επ αυτω ου καταισχυνθησεται
12 Nítorí kò si ìyàtọ̀ nínú Júù àti Helleni: nítorí Olúwa kan náà ni Olúwa gbogbo wọn, o si pọ̀ ni ọrọ̀ fún gbogbo àwọn ti ń ké pe e.
ου γαρ εστιν διαστολη ιουδαιου τε και ελληνος ο γαρ αυτος κυριος παντων πλουτων εις παντας τους επικαλουμενους αυτον
13 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá à ti pe orúkọ Olúwa ni a ó gbàlà.”
πας γαρ ος αν επικαλεσηται το ονομα κυριου σωθησεται
14 Ǹjẹ́ wọn ó ha ti ṣe ké pe ẹni tí wọn kò gbàgbọ́? Wọn ó ha sì ti ṣe gba ẹni tí wọn kò gbúròó rẹ̀ rí gbọ́? Wọn o ha sì ti ṣe gbọ́ láìsí oníwàásù?
πως ουν επικαλεσονται εις ον ουκ επιστευσαν πως δε πιστευσουσιν ου ουκ ηκουσαν πως δε ακουσουσιν χωρις κηρυσσοντος
15 Wọ́n ó ha sì ti ṣe wàásù, bí kò ṣe pé a rán wọn? Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Ẹsẹ̀ àwọn tí ń wàásù ìyìnrere àlàáfíà ti dára tó, àwọn tí ń wàásù ìròyìn ayọ̀ ohun rere!”
πως δε κηρυξουσιν εαν μη αποσταλωσιν καθως γεγραπται ως ωραιοι οι ποδες των ευαγγελιζομενων ειρηνην των ευαγγελιζομενων τα αγαθα
16 Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo wọn ni ó gbọ́ ti ìyìnrere. Nítorí Isaiah wí pé, “Olúwa, ta ni ó gba ìyìn wa gbọ́?”
αλλ ου παντες υπηκουσαν τω ευαγγελιω ησαιας γαρ λεγει κυριε τις επιστευσεν τη ακοη ημων
17 Ǹjẹ́ nípa gbígbọ́ ni ìgbàgbọ́ ti í wá, àti gbígbọ́ nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
αρα η πιστις εξ ακοης η δε ακοη δια ρηματος θεου
18 Ṣùgbọ́n mo ní, wọn kò ha gbọ́ bí? Bẹ́ẹ̀ ni nítòótọ́: “Ohùn wọn jáde lọ sí gbogbo ilẹ̀, àti ọ̀rọ̀ wọn sí òpin ilẹ̀ ayé.”
αλλα λεγω μη ουκ ηκουσαν μενουνγε εις πασαν την γην εξηλθεν ο φθογγος αυτων και εις τα περατα της οικουμενης τα ρηματα αυτων
19 Ṣùgbọ́n mo wí pé, Israẹli kò ha mọ̀ bí? Mose ni ó kọ́ wí pé, “Èmi ó fi àwọn tí kì í ṣe ènìyàn mú yín jowú. Àti àwọn aláìmòye ènìyàn ni èmi ó fi bí yín nínú.”
αλλα λεγω μη ουκ εγνω ισραηλ πρωτος μωσης λεγει εγω παραζηλωσω υμας επ ουκ εθνει επι εθνει ασυνετω παροργιω υμας
20 Ṣùgbọ́n Isaiah tilẹ̀ láyà, ó wí pé, “Àwọn tí kò wá mi rí mi; Àwọn tí kò béèrè mi ni a fi mí hàn fún.”
ησαιας δε αποτολμα και λεγει ευρεθην τοις εμε μη ζητουσιν εμφανης εγενομην τοις εμε μη επερωτωσιν
21 Ṣùgbọ́n nípa ti Israẹli ni ó wí pé, “Ní gbogbo ọjọ́ ni mo na ọwọ́ mi sí àwọn aláìgbọ́ràn àti aláríwísí ènìyàn.”
προς δε τον ισραηλ λεγει ολην την ημεραν εξεπετασα τας χειρας μου προς λαον απειθουντα και αντιλεγοντα

< Romans 10 >