< Revelation 5 >

1 Mo sì rí i ni ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà, ìwé kan ti a kọ nínú àti lẹ́yìn, ti a sì fi èdìdì méje dí.
I vidjeh: na desnici Onoga koji sjedi na prijestolju - knjiga, iznutra i izvana ispisana, zapečaćena sa sedam pečata!
2 Mó sì rí angẹli alágbára kan, ó ń fi ohùn rara kéde pé, “Ta ni ó yẹ láti ṣí ìwé náà, àti láti tu èdìdì rẹ̀?”
I vidjeh snažna anđela gdje iza glasa proglašuje: “Tko je dostojan otvoriti knjigu i otpečatiti pečate njezine?”
3 Kò sì ṣí ẹni kan ní ọ̀run, tàbí lórí ilẹ̀ ayé, tàbí nísàlẹ̀ ilẹ̀, tí ó le ṣí ìwé náà, tàbí ti o lè wo inú rẹ̀.
I nitko - ni na nebu, ni na zemlji, ni pod zemljom - nije mogao otvoriti knjige i pogledati u nju.
4 Èmi sì sọkún gidigidi, nítorí tí a kò ri ẹnìkan tí o yẹ láti sí i àti láti ka ìwé náà, tàbí láti wo inú rẹ̀.
Briznem u plač jer se nitko ne nađe dostojan otvoriti knjigu i pogledati u nju.
5 Ọ̀kan nínú àwọn àgbà náà sì wí fún mi pé, “Má ṣe sọkún: kíyèsi i, kìnnìún ẹ̀yà Juda, Gbòǹgbò Dafidi, tí borí láti ṣí ìwé náà, àti láti tú èdìdì rẹ̀ méjèèje.”
A jedan od starješina reče: “Ne plači! Evo, pobijedi Lav iz plemena Judina, Korijen Davidov, on će otvoriti knjigu i sedam pečata njezinih.
6 Mo sì rí Ọ̀dọ́-Àgùntàn ni àárín ìtẹ́ náà, àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, àti ni àárín àwọn àgbà náà, Ọ̀dọ́-àgùntàn kan dúró bí èyí tí a ti pa, ó ní ìwo méje àti ojú méje, tí o jẹ́ Ẹ̀mí méje tí Ọlọ́run, tí a rán jáde lọ sì orí ilẹ̀ ayé gbogbo.
I vidjeh: posred prijestolja i četiriju bića i posred starješina stoji, kao zaklan, Jaganjac sa sedam rogova i sedam očiju, to jest sedam duhova Božjih, po svoj zemlji poslanih.
7 Ó sì wá, o sì gbà á ìwé náà ni ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà.
On pristupi te iz desnice Onoga koji sjedi na prijestolju uzme knjigu.
8 Nígbà tí ó sì gba ìwé náà, àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, àti àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún náà wólẹ̀ níwájú Ọ̀dọ́-àgùntàn náà, olúkúlùkù wọn mú ohun èlò orin olókùn kan lọ́wọ́, àti ago wúrà tí ó kún fún tùràrí tí i ṣe àdúrà àwọn ènìyàn mímọ́.
A kad on uze knjigu, četiri bića i dvadeset i četiri starješine padoše ničice pred Jaganjca. U svakoga bijahu citre i zlatne posudice pune kada, to jest molitava svetačkih.
9 Wọn sì ń kọ orin tuntun kan, wí pé: “Ìwọ ní o yẹ láti gba ìwé náà, àti láti ṣí èdìdì rẹ̀: nítorí tí a tí pa ọ, ìwọ sì tí fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ṣe ìràpadà ènìyàn sí Ọlọ́run láti inú ẹ̀yà gbogbo, àti èdè gbogbo, àti inú ènìyàn gbogbo, àti orílẹ̀-èdè gbogbo wá.
Pjevaju oni pjesmu novu: “Dostojan si uzeti knjigu i otvoriti pečate njezine jer si bio zaklan i otkupio, krvlju svojom, za Boga ljude iz svakoga plemena i jezika, puka i naroda;
10 Ìwọ sì tí ṣe wọ́n ni ọba àti àlùfáà sì Ọlọ́run wá: wọ́n sì ń jẹ ọba lórí ilẹ̀ ayé.”
učinio si ih Bogu našemu kraljevstvom i svećenicima i kraljevat će na zemlji.”
11 Èmi sì wò, mo sì gbọ́ ohùn àwọn angẹli púpọ̀ yí ìtẹ́ náà ká, àti yí àwọn ẹ̀dá alààyè náà àti àwọn àgbà náà ká. Iye wọn sì jẹ́ ẹgbàárùn-ún ọ̀nà ẹgbàárùn-ún àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún.
I vidjeh, i začuh glas anđela mnogih uokolo prijestolja, i bića i starješina. Bijaše ih na mirijade mirijada i tisuće tisuća.
12 Wọn ń wí lóhùn rara pé: “Yíyẹ ni Ọ̀dọ́-àgùntàn náà tí a tí pa, láti gba agbára, àti ọ̀rọ̀ àti ọgbọ́n, àti ipá, àti ọlá, àti ògo, àti ìbùkún.”
Klicahu iza glasa: “Dostojan je zaklani Jaganjac primiti moć, i bogatstvo, i mudrost, i snagu, i čast, i slavu, i blagoslov!”
13 Gbogbo ẹ̀dá tí o sì ń bẹ ni ọ̀run, àti lórí ilẹ̀ ayé, àti nísàlẹ̀ ilẹ̀ àti irú àwọn tí ń bẹ nínú Òkun, àti gbogbo àwọn tí ń bẹ nínú wọn, ni mo gbọ́ tí ń wí pé, “Kí a fi ìbùkún àti ọlá, àti ògo, àti agbára, fún Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ àti fún Ọ̀dọ́-àgùntàn
I začujem: sve stvorenje, i na nebu, i na zemlji, i pod zemljom, i u moru - sve na njima i u njima govori: “Onomu koji sjedi na prijestolju i Jaganjcu blagoslov i čast, i slava i vlast u vijeke vjekova!” (aiōn g165)
14 Àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà wí pé, “Àmín!” Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún náà wólẹ̀, wọn sì foríbalẹ̀ fún ẹni tí ń bẹ láààyè láé àti láéláé. (aiōn g165)
I četiri bića ponavljahu: “Amen!” A starješine padnu ničice i poklone se.

< Revelation 5 >