< Revelation 4 >

1 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí èmi wò, sì kíyèsi i, ìlẹ̀kùn kan ṣí sílẹ̀ ní ọ̀run, ohùn kìn-ín-ní tí mo gbọ́ bí ohùn ìpè tí ń bá mi sọ̀rọ̀, tí ó wí pé, “Gòkè wá níhìn-ín, èmi ó sì fi ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn èyí hàn ọ́.”
Post haec vidi: et ecce ostium apertum in caelo, et vox prima, quam audivi tamquam tubae loquentis mecum, dicens: Ascende huc, et ostendam tibi quae oportet fieri cito post haec.
2 Lójúkan náà, mo sì wà nínú Ẹ̀mí, sì kíyèsi i, a tẹ́ ìtẹ́ kan ní ọ̀run, ẹnìkan sì jókòó lórí ìtẹ́ náà.
Statim fui in spiritu: et ecce sedes posita erat in caelo, et supra sedem sedens.
3 Ẹni tí ó sì jókòó náà dàbí òkúta jasperi àti kaneliani lójú. Ni àyíká ìtẹ́ náà ni òṣùmàrè kan wà tí ó dàbí òkúta emeradi lójú.
Et qui sedebat similis erat aspectui lapidis iaspidis, et sardinis: et iris erat in circuitu sedis similis visioni smaragdinae.
4 Yí ìtẹ́ náà ká sì ni ìtẹ́ mẹ́rìnlélógún mìíràn; àti lórí àwọn ìtẹ́ náà mo rí àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún jókòó, tí a wọ̀ ni aṣọ àlà; adé wúrà sì wà ni orí wọn.
Et in circuitu sedis sedilia vigintiquattuor: et super thronos vigintiquattuor seniores sedentes, circumamicti vestimentis albis, et in capitibus eorum coronae aureae:
5 Àti láti ibi ìtẹ́ náà ni ìró mọ̀nàmọ́ná àti ohùn àti àrá ti jáde wá: níwájú ìtẹ́ náà ni fìtílà iná méje sì ń tàn, èyí tí ń ṣe Ẹ̀mí méje ti Ọlọ́run.
Et de throno procedebant fulgura, et voces, et tonitrua: et septem lampades ardentes ante thronum, qui sunt septem spiritus Dei.
6 Àti láti ibi ìtẹ́ náà ni òkun bi dígí wà tí o dàbí kristali. Àti yí ìtẹ́ náà ká ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan ni ẹ̀dá alààyè mẹ́rin tí ó kún fún ojú níwájú àti lẹ́yìn wọn.
Et in conspectu sedis tamquam mare vitreum simile crystallo: et in medio sedis, et in circuitu sedis quattuor animalia plena oculis ante et retro.
7 Ẹ̀dá kìn-ín-ní sì dàbí kìnnìún, ẹ̀dá kejì si dàbí ọmọ màlúù, ẹ̀dá kẹta sì ni ojú bi ti ènìyàn, ẹ̀dá kẹrin sì dàbí idì tí ń fò.
Et animal primum simile leoni, et secundum animal simile vitulo, et tertium animal habens faciem quasi hominis, et quartum animal simile aquilae volanti.
8 Àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, tí olúkúlùkù wọn ni ìyẹ́ mẹ́fà, kún fún ojú yíká ara àti nínú; wọn kò sì sinmi lọ́sàn àti lóru, láti wí pé:
Et quattuor animalia, singula eorum habebant alas senas in circuitu: et intus plena sunt oculis: et requiem non habebant die ac nocte, dicentia: Sanctus, Sanctus, Sanctus Dominus Deus omnipotens, qui erat, et qui est, et qui venturus est.
9 Nígbà tí àwọn ẹ̀dá alààyè náà bá sì fi ògo àti ọlá, àti ọpẹ́ fún ẹni tí o jókòó lórí ìtẹ́, tí o ń bẹ láààyè láé àti láéláé. (aiōn g165)
Et cum darent illa animalia gloriam, et honorem, et benedictionem sedenti super thronum, viventi in saecula saeculorum, (aiōn g165)
10 Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún náà yóò sì wólẹ̀ níwájú ẹni tí o jókòó lórí ìtẹ́, wọn yóò sì tẹríba fún ẹni tí ń bẹ láààyè láé àti láéláé, wọn yóò sì fi adé wọn lélẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà, wí pé: (aiōn g165)
procidebant vigintiquattuor seniores ante sedentem in throno, et adorabant viventem in saecula saeculorum, et mittebant coronas suas ante thronum dicentes: (aiōn g165)
11 “Olúwa àti Ọlọ́run, ìwọ ni o yẹ, láti gba ògo àti ọlá àti agbára, nítorí pé ìwọ ni o dá ohun gbogbo, àti nítorí ìfẹ́ inú rẹ̀ ni wọn fi wà tí a sì dá wọn.”
Dignus es Domine Deus noster accipere gloriam, et honorem, et virtutem: quia tu creasti omnia, et propter voluntatem tuam erant, et creata sunt.

< Revelation 4 >