< Revelation 3 >

1 “Àti sí angẹli ìjọ ni Sardi kọ̀wé: Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni ẹni tí ó ni Ẹ̀mí méje Ọlọ́run, àti ìràwọ̀ méje wí pé. Èmi mọ iṣẹ́ rẹ̀, àti pé ìwọ ní orúkọ pé ìwọ ń bẹ láààyè, ṣùgbọ́n ìwọ ti kú.
And wryte vnto the messenger of the congregacion of Sardis: this sayth he that hath the sprete of god and the vii. starres. I knowe thy workes thou haste a name that thou lvyest and thou art deed
2 Jí, kí o sì fi ẹsẹ̀ ohun tí ó kù múlẹ̀, tàbí tí ó ṣetán láti kú, nítorí èmi kò rí iṣẹ́ rẹ ni pípé níwájú Ọlọ́run.
Be awake and strength the thynges which remayne that are redy to dye. For I have not founde thy workes perfaycte before god.
3 Nítorí náà rántí bí ìwọ ti gbà, àti bí ìwọ ti gbọ́, kí o sì pa á mọ́, kí o sì ronúpìwàdà. Ǹjẹ́, bí ìwọ kò ba ṣọ́ra, èmi yóò dé sí ọ bí olè, ìwọ kì yóò sì mọ́ wákàtí tí èmi yóò dé sí ọ.
Remember therfore how thou hast receaved and hearde and hold faste and repet. Yf thou shalt not watche I will come on ye as a thefe and thou shalt not knowe what houre I wyll come apon the
4 Ìwọ ní orúkọ díẹ̀ ní Sardi, tí kò fi aṣọ wọn yí èérí; wọn yóò sì máa ba mi rìn ní aṣọ funfun: nítorí wọ́n yẹ.
Thou haste a feawe names in Sardis which have not defyled their garmentes: and they shall walke with me in whyte for they are worthy
5 Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun, òun náà ni a ó fi aṣọ funfun wọ̀; èmi kì yóò pa orúkọ rẹ̀ kúrò nínú ìwé ìyè, ṣùgbọ́n èmi yóò jẹ́wọ́ orúkọ rẹ̀ níwájú Baba mi, àti níwájú àwọn angẹli rẹ̀.
He that overcometh shalbe clothed in whyte araye and I will not put out his name out of the boke of lyfe and I will confesse his name before my father and before his angelles.
6 Ẹni tí ó ba létí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.
Let him that hath eares heare what the sprete sayth vnto the congregacions.
7 “Àti sí angẹli Ìjọ ni Filadelfia kọ̀wé. Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni ẹni tí ó jẹ́ mímọ́ náà wí, ẹni tí ó ṣe olóòtítọ́, ẹni tí ó ní kọ́kọ́rọ́ Dafidi, ẹni tí ó ṣí, tí kò sí ẹni tí yóò tì; ẹni tí o sì tì, tí kò sì ẹni tí yóò ṣí i.
And wryte vnto ye tydinges bringer of ye cogregacio of Philadelphia: this sayth he yt is holy and true which hath ye keye of Dauid: which openyth and noma shutteth and shutteth and no ma openeth.
8 Èmi mọ iṣẹ́ rẹ̀, kíyèsi i, mo gbe ìlẹ̀kùn tí ó ṣí kálẹ̀ níwájú rẹ̀, tí kò sí ẹni tí o lè tì í; pé ìwọ ni agbára díẹ̀, ìwọ sì pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, ìwọ kò sì sẹ́ orúkọ mi.
I knowe thy workes. Beholde I have set before the an open doore and no man can shut it for thou haste a lyttell strengthe and haste kept my sayinges: and haste not denyed my name.
9 Kíyèsi i, èmi ó mú àwọn ti Sinagọgu Satani, àwọn tí wọ́n ń wí pé Júù ni àwọn, tí wọn kì í sì ṣe bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n tí wọn ń ṣèké; kíyèsi i, èmi ó mú kí wọn wá wólẹ̀ níwájú ẹsẹ̀ rẹ̀, kí wọn sì mọ̀ pé èmi tí fẹ́ ọ.
Beholde I make them of the congregacion of Sathan which call them selves Iewes and are not but do lye: Beholde: I will make them that they shall come and worshippe before thy fete: and shall knowe that I love the.
10 Nítorí tí ìwọ tí pa ọ̀rọ̀ sùúrù mi mọ́, èmi pẹ̀lú yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú wákàtí ìdánwò, tí ń bọ̀ wá dé bá gbogbo ayé, láti dán àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé wò.
Because thou hast kept ye wordes of my paciece therfore I will kepe ye fro the houre of teptacion which will come upo all ye worlde to tempte them yt dwell vpo the erth.
11 Kíyèsi i, èmi ń bọ̀ kánkán, di èyí ti ìwọ ní mú ṣinṣin, kí ẹnikẹ́ni má ṣe gba adé rẹ.
Beholde I come shortly. Holde that which thou haste that no man take awaye thy croune
12 Ẹni tí ó ba ṣẹ́gun, òun ni èmi ó fi ṣe ọ̀wọ́n nínú tẹmpili Ọlọ́run mi, òun kì yóò sì jáde kúrò níbẹ̀ mọ́, èmi ó sì kọ orúkọ Ọlọ́run mi sí i lára, àti orúkọ ìlú Ọlọ́run mi, tí i ṣe Jerusalẹmu tuntun, tí ó ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run mi wá: àti orúkọ tuntun ti èmi tìkára mi.
Him that overcometh will I make a pyllar in the temple of my God and he shall goo no more oute. And I will wryt vpo him the name of my God and the name of ye cite of my god newe Ierusale which cometh doune oute of heve fro my God and I will wryte vpon him my newe name.
13 Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́ ohun ti Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.
Let him that hath eares heare what the sprete sayth vnto the congregacions.
14 “Àti sí angẹli ìjọ ní Laodikea kọ̀wé. Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni ẹni tí ń jẹ́ Àmín wí, ẹlẹ́rìí olódodo àti olóòtítọ́, olórí ìṣẹ̀dá Ọlọ́run.
And vnto the messenger of ye congregacio which is in Laodicia wryte: This sayth (ame) the faythfull and true witnes ye begynninge of the creatures of God.
15 Èmi mọ̀ iṣẹ́ rẹ, pé ìwọ kò gbóná bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò tútù: èmi ìbá fẹ́ pé kí ìwọ kúkú tutù, tàbí kí ìwọ kúkú gbóná.
I knowe thy workes yt thou arte nether colde nor hot: I wolde thou were colde or hotte.
16 Ǹjẹ́ nítorí tí ìwọ lọ wọ́ọ́rọ́, tí o kò si gbóná, bẹ́ẹ̀ ni tí o kò tutù, èmi yóò pọ̀ ọ́ jáde kúrò ni ẹnu mi.
So then because thou arte bitwene bothe and nether colde ner hot I will spew ye oute of my mouth:
17 Nítorí tí ìwọ wí pé, èmi ní ọrọ̀, èmi sì ń pọ̀ sí i ni ọrọ̀, èmi kò sì ṣe aláìní ohunkóhun; tí ìwọ kò sì mọ̀ pé, òsì ni ìwọ, ẹni-ìkáàánú, tálákà, afọ́jú, àti ẹni ìhòhò:
because thou sayst thou arte riche and incresyd wt goodes and haste nede of nothynge and knowest not howe thou arte wretched and miserable poore blinde and nakyd.
18 Èmi fún ọ ni ìmọ̀ràn pé kí o ra wúrà lọ́wọ́ mi tí a ti dà nínú iná, kí ìwọ lè di ọlọ́rọ̀; àti aṣọ funfun, kí ìwọ lè fi wọ ara rẹ̀, àti kí ìtìjú ìhòhò rẹ̀ má ba hàn kí ìwọ sì fi ohun ìkunra kun ojú rẹ̀, kí ìwọ lè ríran.
I counsell the to bye of me golde tryed in the fyre that thou mayste be riche and whyte raymet yt thou mayste be clothed yt thy fylthy nakednes do not apere: and anoynt thyne eyes with eye salve yt thou mayste se.
19 Gbogbo àwọn ti èmi bá fẹ́ ni èmi ń bá wí, tí mo sì ń nà: nítorí náà, ní ìtara, kì ìwọ sì ronúpìwàdà.
As many as I love I rebuke and chasten. Be fervent therfore and repet.
20 Kíyèsi i, èmi dúró ni ẹnu ìlẹ̀kùn, èmi sì ń kànkùn, bí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ ohun mi, tí ó sì ṣí ìlẹ̀kùn, èmi yóò sì wọlé tọ̀ ọ́ wá, èmi yóò sì máa bá a jẹun, àti òun pẹ̀lú mi.
Beholde I stode at the doore and knocke. Yf eny man heare my voyce and opon the dore I will come in vnto him and will suppe with him and he with me.
21 Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun ni èmi yóò fi fún láti jókòó pẹ̀lú mi lórí ìtẹ́ mi, bí èmi pẹ̀lú ti ṣẹ́gun, tí mo sì jókòó pẹ̀lú Baba mi lórí ìtẹ́ rẹ̀.
To him that overcommeth will I graunte to sytt with me in my seate evyn as I overcam and have sytten with my father in his seate.
22 Ẹni tí ó bá létí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.”
Lett him yt hath eares heare what the sprete sayth vnto the congregacions.

< Revelation 3 >