< Revelation 20 >
1 Mo sì rí angẹli kan ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, ti òun ti kọ́kọ́rọ́ ọ̀gbun, àti ẹ̀wọ̀n ńlá kan ní ọwọ́ rẹ̀. (Abyssos )
І я побачив ангела, що спускався з неба, маючи в руці ключ від безодні й великий ланцюг. (Abyssos )
2 O sì di dragoni náà mú, ejò àtijọ́ nì, tí í ṣe èṣù, àti Satani, ó sì dè é ní ẹgbẹ̀rún ọdún.
Він схопив дракона, стародавнього змія, який є дияволом та сатаною, і зв’язав його на тисячу років.
3 Ó sì gbé e sọ sínú ọ̀gbun náà, ó sì tì í, ó sì fi èdìdì dì í lórí rẹ̀, kí ó má ba à tan àwọn orílẹ̀-èdè jẹ mọ́ títí ẹgbẹ̀rún ọdún náà yóò fi pé. Lẹ́yìn èyí, a kò le ṣàì tú u sílẹ̀ fún ìgbà díẹ̀. (Abyssos )
Він кинув його в безодню, замкнув і запечатав над ним [вхід], щоб більше не обманював народи, поки не закінчиться тисяча років. Після цього він має бути звільнений на короткий час. (Abyssos )
4 Mo sì rí àwọn ìtẹ́, wọ́n sì jókòó lórí wọn, a sì fi ìdájọ́ fún wọ́n, mo sì rí ọkàn àwọn tí a ti bẹ́ lórí nítorí ẹ̀rí Jesu, àti nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti àwọn tí kò sì foríbalẹ̀ fún ẹranko náà, àti fún àwòrán rẹ̀, tàbí tí kò sì gbà àmì rẹ̀ ní iwájú wọn àti ní ọwọ́ wọn; wọ́n sì wà láààyè, wọ́n sì jẹ ọba pẹ̀lú Kristi ní ẹgbẹ̀rún ọdún.
І я побачив престоли й тих, хто сидів на них, їм була дана [влада] судити. Це душі тих, хто був обезголовлений за свідчення про Ісуса та за Слово Боже. Вони не поклонилися ні звіру, ні його образу й не отримали його знака на чоло чи руку. Вони ожили й царювали з Христом тисячу років.
5 (Àwọn òkú ìyókù kò wà láààyè mọ́ títí ẹgbẹ̀rún ọdún náà yóò fi pé). Èyí ni àjíǹde èkínní.
(Інші мертві не ожили, поки не закінчилася тисяча років.) Це перше воскресіння.
6 Ẹni ìbùkún àti mímọ́ ni ẹni tí ó ní ipa nínú àjíǹde èkínní náà. Lórí àwọn wọ̀nyí ikú ẹ̀ẹ̀kejì kò ní agbára, ṣùgbọ́n wọn ó jẹ́ àlùfáà Ọlọ́run àti ti Kristi, wọn ó sì máa jẹ ọba pẹ̀lú rẹ̀ ní ẹgbẹ̀rún ọdún.
Блаженні та святі [всі], хто має частку в першому воскресінні. Друга смерть не має над ними влади, але вони будуть священниками Бога та Христа й царюватимуть із Ним тисячу років.
7 Nígbà tí ẹgbẹ̀rún ọdún náà bá sì pé, a ó tú Satani sílẹ̀ kúrò nínú túbú rẹ̀.
Коли тисяча років закінчиться, сатана буде звільнений зі своєї в’язниці.
8 Yóò sì jáde lọ láti máa tan àwọn orílẹ̀-èdè tí ń bẹ ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé jẹ, Gogu àti Magogu, láti gbá wọn jọ sí ogun: àwọn tí iyè wọn dàbí iyanrìn Òkun.
Він піде обманювати народи з чотирьох сторін світу, Гога й Магога, щоб зібрати їх для війни. Число їх буде як пісок на березі моря.
9 Wọ́n sì gòkè lọ la ibú ayé já, wọ́n sì yí ibùdó àwọn ènìyàn mímọ́ ká àti ìlú àyànfẹ́ náà: iná sì ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, ó sì jó wọn run.
Вони піднялися по [всій] землі й оточили табір святих та улюблене місто. Але зійшов вогонь із неба й пожер їх.
10 A sì wọ́ Èṣù tí ó tàn wọ́n jẹ lọ sínú adágún iná àti sulfuru, níbi tí ẹranko àti wòlíì èké nì gbé wà, a ó sì máa dá wọn lóró tọ̀sán tòru láé àti láéláé. (aiōn , Limnē Pyr )
А диявола, який їх обманув, було кинуто у вогняне й сірчане озеро, де вже були звір і лжепророк. Вони будуть мучитися день і ніч навіки-віків. (aiōn , Limnē Pyr )
11 Mo sì rí ìtẹ́ funfun ńlá kan, àti ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀, níwájú ẹni tí ayé àti ọ̀run fò lọ; a kò sì rí ààyè fún wọn mọ́.
Потім я побачив великий білий престол і Того, Хто сидів на ньому. Земля та небо втекли від Його присутності, бо не знайшлося для них місця.
12 Mo sì rí àwọn òkú, àti èwe àti àgbà, wọn dúró níwájú ìtẹ́; a sì ṣí àwọn ìwé sílẹ̀; a sì ṣí àwọn ìwé mìíràn kan sílẹ̀ tí í ṣe ìwé ìyè: a sì ṣe ìdájọ́ fún àwọn òkú láti inú ohun tí a ti kọ sínú àwọn ìwé náà, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn.
І я побачив мертвих, великих і малих, що стояли перед престолом. Були розгорнуті книги; і була розгорнута іще одна книга, яка є [книгою] життя. Загиблих судили за їхніми вчинками згідно з тим, що записано в книгах.
13 Òkun sì jọ̀wọ́ àwọn òkú tí ń bẹ nínú rẹ̀ lọ́wọ́; àti òkú àti ipò òkú sì jọ̀wọ́ òkú tí ó wà nínú wọn pẹ̀lú: a sì ṣe ìdájọ́ wọn, olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn. (Hadēs )
Море віддало мертвих, що були в ньому, а смерть та царство мертвих – тих, що були в них, і кожного судили за його вчинками. (Hadēs )
14 Àti ikú àti ipò òkú ni a sì sọ sínú adágún iná. Èyí ni ikú kejì. (Hadēs , Limnē Pyr )
Потім смерть і царство мертвих були кинуті у вогняне озеро. Вогняне озеро – це друга смерть. (Hadēs , Limnē Pyr )
15 Bí a bá sì rí ẹnikẹ́ni tí a kò kọ orúkọ rẹ̀ sínú ìwé ìyè, a ó sọ ọ́ sínú adágún iná. (Limnē Pyr )
І той, кого не було знайдено записаним у книзі життя, був укинутий у вогняне озеро. (Limnē Pyr )