< Revelation 19 >
1 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí mo gbọ́ ohùn ńlá ní ọ̀run bí ẹni pé tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, ń wí pé: “Haleluya! Ti Olúwa Ọlọ́run wa ni ìgbàlà, àti ọlá àti agbára,
After these things I heard something like a loud voice of a great multitude in heaven, saying, "Hallelujah. Salvation, glory, and power belong to our God:
2 nítorí òtítọ́ àti òdodo ni ìdájọ́ rẹ̀. Nítorí o ti ṣe ìdájọ́ àgbèrè ńlá a nì, tí o fi àgbèrè rẹ̀ ba ilẹ̀ ayé jẹ́, ó sì ti gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ náà.”
for true and righteous are his judgments. For he has judged the great prostitute, who corrupted the earth with her sexual immorality, and he has avenged the blood of his servants at her hand."
3 Àti lẹ́ẹ̀kejì wọ́n wí pé: “Haleluya! Èéfín rẹ̀ sì gòkè lọ láé àti láéláé.” (aiōn )
A second said, "Hallelujah. Her smoke goes up forever and ever." (aiōn )
4 Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún nì, àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin nì sì wólẹ̀, wọ́n sì foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run tí ó jókòó lórí ìtẹ́, wí pé: “Àmín, Haleluya!”
The twenty-four elders and the four living creatures fell down and worshiped God who sits on the throne, saying, "Amen. Hallelujah."
5 Ohùn kan sì ti ibi ìtẹ́ náà jáde wá, wí pé: “Ẹ máa yin Ọlọ́run wa, ẹ̀yin ìránṣẹ́ rẹ̀ gbogbo, ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù rẹ̀, àti èwe àti àgbà!”
A voice came forth from the throne, saying, "Give praise to our God, all you his servants, you who fear him, the small and the great."
6 Mo sì gbọ́ bí ẹni pé ohùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àti bí ìró omi púpọ̀, àti bí ìró àrá ńlá ńlá, ń wí pé: “Haleluya! Nítorí Olúwa Ọlọ́run wa, Olódùmarè ń jẹ ọba.
I heard something like the voice of a great multitude, and like the voice of many waters, and like the voice of mighty thunders, saying, "Hallelujah. For the Lord our God the Almighty reigns.
7 Ẹ jẹ́ kí a yọ̀, kí inú wa kí ó sì dùn gidigidi, kí a sì fi ògo fún un. Nítorí pé ìgbéyàwó Ọ̀dọ́-Àgùntàn dé, aya rẹ̀ sì ti múra tán.
Let us rejoice and be exceedingly glad, and let us give the glory to him. For the marriage of the Lamb has come, and his wife has made herself ready."
8 Òun ni a sì fi fún pé kí ó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́ tí ó funfun gbòò.” (Nítorí pé aṣọ ọ̀gbọ̀ nì dúró fún iṣẹ́ òdodo àwọn ènìyàn mímọ́.)
It was given to her that she would array herself in bright, pure, fine linen: for the fine linen is the righteous acts of the saints.
9 Ó sì wí fún mi pé, “Kọ̀wé rẹ̀, ‘Ìbùkún ni fún àwọn tí a pè sí àsè alẹ́ ìgbéyàwó ọ̀dọ́-àgùntàn.’” Ó sì wí fún mi pé, “Ìwọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ òtítọ́ Ọlọ́run.”
He said to me, "Write, 'Blessed are those who are invited to the marriage supper of the Lamb.'" He said to me, "These are true words of God."
10 Mo sì wólẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀ láti foríbalẹ̀ fún un. Ó sì wí fún mi pé, “Wò ó, má ṣe bẹ́ẹ̀: ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ni èmi, àti ti àwọn arákùnrin rẹ̀ tí wọ́n di ẹ̀rí Jesu mú. Foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run: nítorí pé ẹ̀rí Jesu ni ìsọtẹ́lẹ̀.”
I fell down before his feet to worship him. He said to me, "Look. Do not do it. I am a fellow servant with you and with your brothers who hold the testimony of Jesus. Worship God, for the testimony of Jesus is the Spirit of Prophecy."
11 Mo sì rí ọ̀run ṣí sílẹ̀, sì wò ó, ẹṣin funfun kan; ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ ni à ń pè ní Olódodo àti Olóòtítọ́, nínú òdodo ni ó sì ń ṣe ìdájọ́, tí ó ń jagun.
I saw the heaven opened, and suddenly there was a white horse, and he who sat on it is called Faithful and True. In righteousness he judges and makes war.
12 Ojú rẹ̀ dàbí ọ̀wọ́-iná, àti ní orí rẹ̀ ni adé púpọ̀ wà; ó sì ní orúkọ kan tí a kọ, tí ẹnikẹ́ni kò mọ́, bí kò ṣe òun tìkára rẹ̀.
His eyes are a flame of fire, and on his head are many crowns. He had a name written which no one knows but he himself.
13 A sì wọ̀ ọ́ ní aṣọ tí a tẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀, a sì ń pe orúkọ rẹ̀ ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
He is clothed in a garment dipped in blood. His name is called "The Word of God."
14 Àwọn ogun tí ń bẹ ní ọ̀run tí a wọ̀ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́, funfun àti mímọ́, sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn lórí ẹṣin funfun.
The armies which are in heaven followed him on white horses, clothed in white, pure, fine linen.
15 Àti láti ẹnu rẹ̀ ni idà mímú ti ń jáde lọ, kí ó lè máa fi sá àwọn orílẹ̀-èdè: “Òun ó sì máa fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn.” Ó sì ń tẹ ìfúntí àti ìbínú Ọlọ́run Olódùmarè.
Out of his mouth proceeds a sharp sword, that with it he should strike the nations. He will rule them with an iron scepter. He treads the winepress of the fierceness of the wrath of God, the Almighty.
16 Ó sì ní lára aṣọ rẹ̀ àti ni ìtàn rẹ̀ orúkọ kan tí a kọ: Ọba àwọn ọba àti Olúwa àwọn olúwa.
He has on his garment and on his thigh a name written, "King of kings, and Lord of lords."
17 Mo sì rí angẹli kan dúró nínú oòrùn; ó sì fi ohùn rara kígbe, ó ń wí fún gbogbo àwọn ẹyẹ tí ń fò ní agbede-méjì ọ̀run pé, “Ẹ wá ẹ sì kó ara yín jọ pọ̀ sí àsè ńlá Ọlọ́run;
I saw an angel standing in the sun. He shouted with a loud voice, saying to all the birds that fly in the sky, "Come. Be gathered together to the great supper of God,
18 kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ ẹran-ara àwọn ọba, àti ẹran-ara àwọn olórí ogun àti ẹran-ara àwọn ènìyàn alágbára, àti ẹran àwọn ẹṣin, àti ti àwọn tí ó jókòó lórí wọn, àti ẹran-ara ènìyàn gbogbo, àti ti òmìnira, àti ti ẹrú, àti ti èwe àti ti àgbà.”
that you may eat the flesh of kings, the flesh of captains, the flesh of mighty people, and the flesh of horses and of those who sit on them, and the flesh of all people, both free and slave, and small and great."
19 Mo sì rí ẹranko náà àti àwọn ọba ayé, àti àwọn ogun wọn tí a gbá jọ láti bá ẹni tí ó jókòó lórí ẹṣin náà àti ogun rẹ̀ jagun.
I saw the beast, and the kings of the earth, and their armies, gathered together to make war against him who sat on the horse, and against his army.
20 A sì mú ẹranko náà, àti wòlíì èké nì pẹ̀lú rẹ̀, tí ó ti ń ṣe iṣẹ́ ìyanu níwájú rẹ̀, èyí tí ó fi ń tan àwọn tí ó gba àmì ẹranko náà àti àwọn tí ń foríbalẹ̀ fún àwòrán rẹ̀ jẹ. Àwọn méjèèjì yìí ni a sọ láààyè sínú adágún iná tí ń fi sulfuru jó. (Limnē Pyr )
The beast was taken, and with him the false prophet who worked the signs in his sight, with which he deceived those who had received the mark of the beast and those who worshiped his image. These two were thrown alive into the lake of fire that burns with sulfur. (Limnē Pyr )
21 Àwọn ìyókù ni a sì fi idà ẹni tí ó jókòó lórí ẹṣin náà pa, àní idà tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde, gbogbo àwọn ẹyẹ sì ti ipa ẹran-ara wọn yó.
The rest were killed with the sword of him who sat on the horse, the sword which came forth out of his mouth. All the birds were filled with their flesh.