< Revelation 17 >

1 Ọ̀kan nínú àwọn angẹli méje náà tí ó ní ìgò méje wọ̀n-ọn-nì sì wá, ó sì ba mi sọ̀rọ̀ wí pé, “Wá níhìn-ín; èmi ó sì fi ìdájọ́ àgbèrè ńlá ní tí ó jókòó lórí omi púpọ̀ han ọ,
Then one of the seven angels who had the seven bowls came and said to me, “Come, I will show yoʋ the judgment of the great prostitute who sits on many waters.
2 ẹni tí àwọn ọba ayé bá ṣe àgbèrè, tí a sì fi ọtí wáìnì àgbèrè rẹ̀ pa àwọn tí ń gbé inú ayé.”
With her the kings of the earth have committed fornication, and those who dwell on the earth have become drunk with the wine of her fornication.”
3 Ó sì gbé mi nínú ẹ̀mí lọ sí aginjù: mo sì rí obìnrin kan ó jókòó lórí ẹranko aláwọ̀ òdòdó kan tí ó kún fún orúkọ ọ̀rọ̀-òdì, ó ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá.
So he carried me away in the Spirit to a wilderness, and I saw a woman sitting on a scarlet beast that was full of blasphemous names and had seven heads and ten horns.
4 A sì fi aṣọ elése àlùkò àti aṣọ òdòdó wọ obìnrin náà, a sì fi wúrà àti òkúta iyebíye àti perli ṣe é ní ọ̀ṣọ́, ó ní ago wúrà kan ní ọwọ́ rẹ̀, tí ó kún fún ìríra àti fún ẹ̀gbin àgbèrè rẹ̀;
The woman was clothed in purple and scarlet, and adorned with gold, precious stones, and pearls. She held in her hand a golden cup full of abominations and the filth of her fornication.
5 àti níwájú rẹ̀ ni orúkọ kan tí a kọ: Ohun ìjìnlẹ̀ Babeli ńlá ìyá àwọn panṣágà àti àwọn ohun ìríra ayé.
A mysterious name was written on her forehead: “Babylon the great, the mother of prostitutes and of the abominations of the earth.”
6 Mo sì rí obìnrin náà mu ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́, àti ẹ̀jẹ̀ àwọn ajẹ́rìí ikú Jesu ní àmuyó. Nígbà tí mo sì rí i, ẹnu yà mi gidigidi.
And I saw the woman drunk with the blood of the saints, the blood of the martyrs of Jesus. When I saw her, I was greatly amazed.
7 Angẹli sì wí fún mi pé, “Nítorí kí ni ẹnu ṣe yà ọ́? Èmi ó sọ ti ìjìnlẹ̀ obìnrin náà fún ọ, àti ti ẹranko tí ó gùn, ti ó ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá.
But the angel said to me, “Why are yoʋ so amazed? I will tell yoʋ the mystery of the woman and of the beast with seven heads and ten horns that carries her.
8 Ẹranko tí ìwọ ri nì, o ti wà, kò sì ṣí mọ́, yóò sì ti inú ọ̀gbun gòkè wá, yóò sì lọ sínú ìparun rẹ. Àwọn olùgbé ayé ti a kọ orúkọ wọn sínú ìwé iye láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, nígbà tí wọn ń wò ẹranko tí o ti wà, tí kò sì ṣí mọ́, tí ó sì ń bọ̀ wá, ẹnu si ya wọn. (Abyssos g12)
The beast that yoʋ saw was, and is not, and is about to come up out of the abyss and go to destruction. Those who dwell on the earth, whose names have not been written in the book of life from the foundation of the world, will be amazed when they see that the beast was and is not and is to come. (Abyssos g12)
9 “Níhìn-ín ni ìtumọ̀ tí o ní ọgbọ́n wà. Orí méje ni òkè ńlá méje ni, lórí èyí tí obìnrin náà jókòó.
This calls for a mind that has wisdom: The seven heads are seven mountains on which the woman sits.
10 Ọba méje sì ní wọn: àwọn márùn-ún ṣubú, ọ̀kan ń bẹ, ọ̀kan ìyókù kò sì tí ì dé; nígbà tí ó bá sì dé, yóò dúró fún ìgbà kúkúrú.
They are also seven kings. Five have fallen, one is, and another has not yet come; but when he does come, he must remain for only a little while.
11 Ẹranko tí ó sì ti wà, tí kò sì ṣí, òun náà sì ni ẹ̀kẹjọ, ó sì ti inú àwọn méje náà wá, ó sì lọ sí ìparun.
The beast that was and is not, is an eighth king. Yet he is one of the seven and is on his way to destruction.
12 “Ìwo mẹ́wàá tí ìwọ sì rí ni ọba mẹ́wàá ni wọn, tí wọn kò ì ti gba ìjọba; ṣùgbọ́n wọn gba àṣẹ bí ọba pẹ̀lú ẹranko náà fún wákàtí kan.
The ten horns that yoʋ saw are ten kings who have not yet received a kingdom, but they will receive authority as kings for one hour with the beast.
13 Àwọn wọ̀nyí ní inú kan, wọ́n yóò sì fi agbára àti ọlá wọn fún ẹranko náà.
These kings have one mind and will give their power and authority to the beast.
14 Àwọn wọ̀nyí ni yóò si máa bá Ọ̀dọ́-Àgùntàn jagun, Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà yóò sì ṣẹ́gun wọn: nítorí òun ni Olúwa àwọn Olúwa, àti ọba àwọn ọba: àwọn tí ó sì wà pẹ̀lú rẹ̀, tí a pè, tí a yàn, tí wọ́n sì jẹ́ olóòtítọ́ yóò sì ṣẹ́gun pẹ̀lú.”
They will make war with the Lamb, but the Lamb will conquer them because he is the Lord of lords and King of kings, and those with him are called, chosen, and faithful.”
15 Ó sì wí fún mi pé, “Àwọn omi tí ìwọ ti rí ni, níbi tí àgbèrè náà jókòó, àwọn ènìyàn àti ẹ̀yà àti orílẹ̀ àti onírúurú èdè ni wọ́n.
Then the angel said to me, “The waters yoʋ saw, where the prostitute sits, are peoples, multitudes, nations, and tongues.
16 Àti ìwo mẹ́wàá tí ìwọ rí, àti ẹranko náà, àwọn wọ̀nyí ni yóò kórìíra àgbèrè náà, wọn ó sì sọ ọ́ di ahoro àti ẹni ìhòhò, wọn ó sì jẹ ẹran-ara rẹ̀, wọn ó sì fi iná sun ún pátápátá.
The beast and the ten horns yoʋ saw will hate the prostitute. They will make her desolate and naked; they will eat her flesh and burn her with fire.
17 Nítorí Ọlọ́run ti fi sínú ọkàn wọn láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ, láti ní inú kan, àti láti fi ìjọba wọn fún ẹranko náà, títí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yóò fi ṣẹ.
For God has put it into their hearts to carry out his purpose by being of one mind and handing their kingdom over to the beast until the words of God are fulfilled.
18 Obìnrin tí ìwọ rí ní ìlú ńlá ni, tí ń jẹ ọba lórí àwọn ọba ilẹ̀ ayé.”
As for the woman yoʋ saw, she is the great city that has dominion over the kings of the earth.”

< Revelation 17 >