< Revelation 15 >
1 Mo sì rí àmì mìíràn ní ọ̀run tí ó tóbi tí ó sì ya ni lẹ́nu, àwọn angẹli méje tí ó ni àwọn ìyọnu méje ìkẹyìn, nítorí nínú wọn ni ìbínú Ọlọ́run dé òpin.
Ještě jiné mocné a podivuhodné úkazy jsem uviděl na nebi. Přede mnou se rozprostíralo křišťálově průzračné jezero, jiskřící jako oheň. U něho se shromáždili všichni ti, kdo zůstali věrni Bohu a zvítězili nad ďábelskou šelmou, neuctívali její sochu a nedali se označit jejím číslem.
2 Mo sì rí bí ẹni pé, Òkun dígí tí o dàpọ̀ pẹ̀lú iná: àwọn tí ó sì dúró lórí Òkun dígí yìí jẹ́ àwọn ti wọ́n ṣẹ́gun ẹranko náà, àti àwòrán rẹ̀, àti àmì rẹ̀ àti nọ́mbà orúkọ rẹ̀, wọn ní ohun èlò orin Ọlọ́run.
3 Wọ́n sì ń kọ orin ti Mose, ìránṣẹ́ Ọlọ́run, àti orin ti Ọ̀dọ́-Àgùntàn, wí pé: “Títóbi àti ìyanu ni àwọn iṣẹ́ rẹ, Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè; òdodo àti òtítọ́ ni ọ̀nà rẹ̀, ìwọ ọba àwọn orílẹ̀-èdè.
Nyní dostali od Boha harfy, aby hráli a zpívali píseň vysvoboditele Božího lidu a píseň Spasitele světa Ježíše: „Velké a podivuhodné jsou tvé činy, Pane Bože všemohoucí. Tvoje cesty jsou spravedlivé a přímé, Králi všech národů.
4 Ta ni kì yóò bẹ̀rù, Olúwa, tí kì yóò sì fi ògo fún orúkọ rẹ̀? Nítorí ìwọ nìkan ṣoṣo ni mímọ́. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ni yóò sì wá, ti yóò sì foríbalẹ̀ níwájú rẹ, nítorí a ti fi ìdájọ́ rẹ hàn.”
Kdo by se tě, Pane, nebál a kdo by neuctíval tvoje jméno? Vždyť ty jediný jsi Svatý. Všechny národy přijdu a skloní se před tebou, všichni poznají, že tvoje soudy jsou spravedlivé.“
5 Lẹ́yìn náà mo sì wo, sì kíyèsi i, a ṣí tẹmpili àgọ́ ẹ̀rí ní ọ̀run sílẹ̀;
Potom jsem viděl: Otevřela se svatyně nebeského chrámu
6 àwọn angẹli méje náà sì ti inú tẹmpili jáde wá, wọ́n ni ìyọnu méje náà, a wọ̀ wọ́n ní aṣọ ọ̀gbọ̀ funfun ti ń dán, a sì fi àmùrè wúrà dìwọ́n ni oókan àyà.
a vyšlo z ní sedm andělů – vykonavatelů sedmi posledních pohrom, kterými se dovrší spravedlivý Boží hněv. Ti andělé měli zářivě čistá kněžská roucha a byli přepásáni zlatými šerpami.
7 Àti ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà fi ìgò wúrà méje fún àwọn angẹli méje náà, tí ó kún fún ìbínú Ọlọ́run, ẹni tí ń bẹ láààyè láé àti láéláé. (aiōn )
Jedna ze čtyř bytostí od Božího trůnu jim předala sedm zlatých číší naplněných hněvem od Boha, živého od věků na věky. (aiōn )
8 Tẹmpili náà sì kún fún èéfín láti inú ògo Ọlọ́run àti agbára rẹ̀ wá; ẹnikẹ́ni kò sì lè wọ inú tẹmpili náà lọ títí a fi mú ìyọnu méjèèje àwọn angẹli méje náà ṣẹ.