< Revelation 14 >
1 Mo sì wo, si kíyèsi i, Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà dúró lórí òkè Sioni, àti pẹ̀lú rẹ̀ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì ènìyàn; wọ́n ní orúkọ rẹ̀, àti orúkọ baba rẹ̀ tí a kọ sí iwájú orí wọn.
І я глянув, — і ось Агнець стоїть на Сіонській горі, а з Ним сто сорок чотири тисячі, що мають Ім'я́ Його й Ім'я́ Отця Його, написане на своїх чо́лах.
2 Mo sì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run wá, bí ariwo omi púpọ̀, àti bí sísán àrá ńlá, mo sì gbọ́ àwọn aludùùrù tí wọn ń lu dùùrù.
І почув я голос із неба, немов шум великої води, і немов гук міцно́го грому. І почув я голос гуслярі́в, що грали на гу́слах своїх,
3 Wọ́n sì ń kọ bí ẹni pé orin tuntun níwájú ìtẹ́ náà, àti níwájú àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin n nì àti àwọn àgbà náà, kò sì ṣí ẹni tí o lè kọ orin náà, bí kò ṣe àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì ènìyàn, tí a tí rà padà láti inú ayé wá.
і співали, як пісню нову́ перед престолом і перед чотирьома́ тваринами й ста́рцями. І ніхто не міг навчитися пісні, окрім цих ста сорока чотирьох тисяч, ви́куплених від землі.
4 Àwọn wọ̀nyí ni a kò fi obìnrin sọ di èérí, nítorí tí wọ́n jẹ́ wúńdíá. Àwọn wọ̀nyí ni o ń tọ Ọ̀dọ́-àgùntàn náà lẹ́yìn níbikíbi tí o bá ń lọ. Àwọn wọ̀nyí ni a rà padà láti inú àwọn ènìyàn wá, wọ́n jẹ́ àkọ́so fún Ọlọ́run àti fún Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà.
Це ті, хто не оскверни́вся з жінками, бо чисті вони. Вони йдуть за Агнцем, куди Він іде. Вони ви́куплені від людей, пе́рвістки Богові й Агнцеві,
5 A kò sì rí èké lẹ́nu wọn, wọn jẹ́ aláìlábùkù.
не знайшлося бо пі́дступу в їхніх уста́х, бо вони непорочні!
6 Mo sì rí angẹli mìíràn ń fò ní àárín méjì ọ̀run, pẹ̀lú ìyìnrere àìnípẹ̀kun láti wàásù fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé, àti fún gbogbo orílẹ̀, àti ẹ̀yà, àti èdè, àti ènìyàn. (aiōnios )
І побачив я іншого ангола, що летів серед неба, і мав благовісти́ти вічну Єва́нгелію ме́шканцям землі, і кожному людові, і племені, і язи́ку, і наро́дові. (aiōnios )
7 Ó ń wí ni ohùn rara pé, “Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ògo fún un, nítorí tí wákàtí ìdájọ́ rẹ̀ dé: ẹ sì foríbalẹ̀ fún ẹni tí o dá ọ̀run, àti ayé, àti Òkun, àti àwọn orísun omi!”
І він говорив гучним голосом: „Побійтеся Бога та славу віддайте Йому, бо настала година суду Його, і вклоніться Тому, Хто створи́в небо, і землю, і море, і водні джере́ла!“
8 Angẹli mìíràn sì tẹ̀lé e, ó ń wí pé, “o ṣubú, Babeli ńlá ṣubú, èyí ti o tí ń mú gbogbo orílẹ̀-èdè mu nínú ọtí wáìnì àìmọ́ àgbèrè rẹ̀!”
А інший, другий ангол леті́в слідо́м і казав: „Упав, упав Вавило́н, місто великий, бо лютим вином розпусти своєї він напоїв усі наро́ди!“
9 Angẹli mìíràn, ẹ̀kẹta, sì tẹ̀lé wọn, ó ń wí ni ohùn rara pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá ń foríbalẹ̀ fún ẹranko náà àti àwòrán rẹ̀, tí ó sì gba àmì sí iwájú orí rẹ̀ tàbí sí ọwọ́ rẹ̀.
А інший, третій а́нгол летів услід за ним, гучним голосом кажучи: „Коли хто вклоняється звіри́ні та о́бразу її, і приймає знаме́но на чолі́ своїм чи на руці своїй,
10 Òun pẹ̀lú yóò mú nínú ọtí wáìnì ìbínú Ọlọ́run, tí a dà ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ sínú ago ìrunú rẹ̀; a ó sì fi iná sulfuru dá a lóró níwájú àwọn angẹli mímọ́, àti níwájú Ọ̀dọ́-àgùntàn.
то той питиме з вина Божого гніву, вина незмішаного в чаші гніву Його, і буде му́чений в огні й сірці перед ангола́ми святими та перед А́гнцем.
11 Èéfín ìdálóró wọn ń lọ sókè títí láéláé wọn kò sì ní ìsinmi ni ọ̀sán àti ní òru, àwọn tí ń foríbalẹ̀ fún ẹranko náà àti fún àwòrán rẹ̀, àti ẹnikẹ́ni tí o ba sì gba àmì orúkọ rẹ̀.” (aiōn )
А дим їхніх мук підійматиметься вічні віки́. І не мають споко́ю день і ніч усі ті, хто вклоняється звіри́ні та о́бразу її, і приймає знаме́но йме́ння його“. (aiōn )
12 Níhìn-ín ni sùúrù àwọn ènìyàn mímọ́ gbé wà: àwọn tí ń pa òfin Ọlọ́run àti ìgbàgbọ́ Jesu mọ́.
Тут терпеливість святих, що доде́ржують заповіді Божі та Ісусову віру!
13 Mo sì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run wá ń wí fún mi pé, “Kọ̀wé rẹ̀, Alábùkún fún ni àwọn òkú tí o kú nínú Olúwa láti ìhín lọ.” Alábùkún ni wọ́n nítòótọ́, bẹ́ẹ̀ ni, Ẹ̀mí wí, “Nítorí tí wọn yóò sinmi kúrò nínú làálàá wọn, nítorí iṣẹ́ wọn ń tọ̀ wọn lẹ́yìn.”
І почув я голос із неба, що до мене казав: „Напиши: Блаженні ті мертві, хто з цього ча́су вмирає в Господі! Так, каже Дух, — вони від праць своїх заспоко́яться, бо їхні діла йдуть за ними слідо́м“.
14 Mo sì wo, sì kíyèsi i, ìkùùkuu àwọsánmọ̀ funfun kan, àti lórí ìkùùkuu àwọsánmọ̀ náà ẹnìkan jókòó tí o dàbí “ọmọ ènìyàn,” tí òun ti adé wúrà ní orí rẹ̀, àti dòjé mímú ni ọwọ́ rẹ̀.
І я глянув, — і ото біла хмара, а на хмарі сидить подібний до Лю́дського Сина. Він мав на Своїй голові золотого вінця́, а в руці Його гострий серп.
15 Angẹli mìíràn sì tí inú tẹmpili jáde wa tí ń ké lóhùn rara sí ẹni tí ó jókòó lórí ìkùùkuu àwọsánmọ̀ náà pé, “Tẹ dòjé rẹ bọ̀ ọ́, kí ó sì máa kórè; nítorí àkókò àti kórè dé, nítorí ìkórè ayé ti gbó tán.”
І інший ангол вийшов із храму, і гучним голосом кликнув до Того, Хто на хмарі сидів: „Пошли серпа свого й жни, бо настала година пожати, дозріло бо жни́во землі!“
16 Ẹni tí ó jókòó lórí ìkùùkuu àwọsánmọ̀ náà sì tẹ dòjé rẹ̀ bọ orí ilẹ̀ ayé; a sì ṣe ìkórè ilẹ̀ ayé.
I Той, Хто на хмарі сидів, скинув додолу серпа свого, — і земля була вижата.
17 Angẹli mìíràn sì tí inú tẹmpili tí ń bẹ ni ọ̀run jáde wá, òun pẹ̀lú sì ní dòjé mímú, kan.
І інший Ангол вийшов із храму, що на небі, — і він мав гострого серпа.
18 Angẹli mìíràn sì tí ibi pẹpẹ jáde wá, tí ó ní agbára lórí iná; ó sì ké ni ohùn rara sí ẹni tí o ni dòjé mímú náà, wí pé, “Tẹ dòjé rẹ mímú bọ̀ ọ́, ki ó sì rẹ́ àwọn ìdì àjàrà ayé, nítorí àwọn èso rẹ̀ tí pọ́n.”
І інший ангол, що мав вла́ду над огнем, вийшов від же́ртівника. І він гучним голосом кли́кнув до того, що мав гострого серпа, говорячи: „Пошли свого гострого серпа, і позбирай гро́на зе́мної виноградини, бо гро́на її вже доспіли“.
19 Angẹli náà sì tẹ dòjé rẹ̀ bọ ilẹ̀ ayé, ó sì gé àjàrà ilẹ̀ ayé, ó sì kó o lọ sínú ìfúntí, ìfúntí ńlá ìbínú Ọlọ́run.
І ангол кинув додо́лу серпа свого, і зібрав виноград на землі, і вкинув в велике чави́ло Божого гніву.
20 A sì tẹ ìfúntí náà lẹ́yìn òde ìlú náà, ẹ̀jẹ̀ sì ti inú ìfúntí náà jáde, ó sì ga sókè dé okùn ìjánu ẹṣin, èyí tí ìnàsílẹ̀ rẹ to ẹ̀gbẹjọ̀ ibùsọ̀.
І пото́вчене було чави́ло за містом, і потекла кров із чави́ла аж до кі́нських вузде́чок, на тисячу шістсот стадій.