< Revelation 10 >

1 Mó sì rí angẹli mìíràn alágbára ò ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, a fi àwọsánmọ̀ wọ̀ ọ́ ni aṣọ; òṣùmàrè sì ń bẹ ní orí rẹ̀, ojú rẹ̀ sì dàbí oòrùn, àti ẹsẹ̀ rẹ̀ bí ọ̀wọ́n iná.
And I saw another strong messenger coming down out of Heaven, clothed with a cloud, and a rainbow on the head, and his face as the sun, and his feet as pillars of fire,
2 Ó sì ní ìwé kékeré kan tí a ṣí ní ọwọ́ rẹ̀; ó sì fi ẹsẹ̀ rẹ̀ ọ̀tún lé Òkun, àti ẹsẹ̀ rẹ̀ òsì lé ilẹ̀.
and he had in his hand a little scroll opened, and he placed his right foot on the sea, and the left on the land,
3 Ó sì ké lóhùn rara, bí ìgbà tí kìnnìún bá bú ramúramù. Nígbà tí ó sì ké, àwọn àrá méje náà fọhùn.
and he cried with a great voice, as a lion roars, and when he cried, the seven thunders spoke out their voices;
4 Nígbà tí àwọn àrá méje fọhùn, mo múra àti kọ̀wé, mo sì gbọ́ ohùn láti ọ̀run wá ń wí fún pé, “Fi èdìdì di ohun tí àwọn àrá méje náà sọ, má sì ṣe kọ wọ́n sílẹ̀.”
and when the seven thunders spoke their voices, I was about to write, and I heard a voice out of Heaven saying to me, “Seal the things that the seven thunders spoke,” and, “You may not write these things.”
5 Angẹli náà tí mo rí tí ó dúró lórí Òkun àti lórí ilẹ̀, sì gbé ọwọ́ rẹ̀ sí òkè ọ̀run.
And the messenger whom I saw standing on the sea, and on the land, lifted up his hand to the sky,
6 Ó sì fi ẹni tí ń bẹ láààyè láé àti láé búra, ẹni tí o dá ọ̀run, àti ohun tí ń bẹ nínú rẹ̀, ayé ohun tí ń bẹ nínú rẹ̀ pé, “Kí yóò si ìjáfara mọ́. (aiōn g165)
and swore by Him who lives through the ages of the ages, who created the sky and the things in it, and the land and the things in it, and the sea and the things in it—that time will not be yet, (aiōn g165)
7 Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ ohùn angẹli keje, nígbà tí yóò ba fún ìpè, nígbà náà ni ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí o tí sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn wòlíì ni a ó mú ṣẹ.”
but in the days of the voice of the seventh messenger, when he may be about to sound the trumpet, and the secret of God may be accomplished, as He declared to His own servants, to the prophets.
8 Ohùn náà tí mo gbọ́ láti ọ̀run tún ń ba mi sọ̀rọ̀, ó sì wí pé, “Lọ, gba ìwé tí o ṣí lọ́wọ́ angẹli tí o dúró lórí Òkun àti lórí ilẹ̀.”
And the voice that I heard out of Heaven is again speaking with me, and saying, “Go, take the little scroll that is open in the hand of the messenger who has been standing on the sea, and on the land”:
9 Mo sì tọ angẹli náà lọ, mo sì wí fún pé, “Fún mi ní ìwé kékeré náà.” Ó sì wí fún mi pé, “Gbà kí o sì jẹ ẹ́ tan: yóò dàbí oyin.”
and I went away to the messenger, saying to him, “Give me the little scroll”; and he says to me, “Take, and eat it up, and it will make your belly bitter, but in your mouth it will be sweet as honey.”
10 Mo sì gba ìwé kékeré náà ni ọwọ́ angẹli náà mo sì jẹ ẹ́ tan; ó sì dùn lẹ́nu mi bí oyin; bí mo sì tí jẹ ẹ́ tan, inú mi korò.
And I took the little scroll out of the hand of the messenger, and ate it up, and it was in my mouth sweet as honey, and when I ate it my belly was made bitter;
11 A sì wí fún mi pé, “Ìwọ ó sì tún sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àti orílẹ̀ àti èdè, àti àwọn ọba.”
and he says to me, “You must again prophesy about many peoples, and nations, and tongues, and kings.”

< Revelation 10 >