< Psalms 99 >
1 Olúwa jẹ ọba; jẹ́ kí ayé kí ó wárìrì Ó jókòó lórí ìtẹ́ kérúbù jẹ́ kí ayé kí ó wárìrì.
耶和華作王;萬民當戰抖! 他坐在二基路伯上,地當動搖。
2 Olúwa tóbi ní Sioni; Ó sì ga jù gbogbo orílẹ̀-èdè lọ.
耶和華在錫安為大; 他超乎萬民之上。
3 Kí wọ́n sì yin orúkọ rẹ̀ tí ó tóbi tí ó ni ẹ̀rù, Mímọ́ ni Òun.
他們當稱讚他大而可畏的名; 他本為聖!
4 Ọba náà ní agbára, ó sì fẹ́ òdodo, ìwọ fi ìdí àìṣègbè múlẹ̀; ìwọ ṣe ohun tí ó tọ́ àti ohun tí ó yẹ nínú Jakọbu.
王有能力,喜愛公平,堅立公正, 在雅各中施行公平和公義。
5 Gbígbéga ni Olúwa Ọlọ́run wa ẹ foríbalẹ̀ níbi ẹsẹ̀ rẹ̀; ó jẹ́ mímọ́.
你們當尊崇耶和華-我們的上帝, 在他腳凳前下拜。 他本為聖!
6 Mose àti Aaroni wà nínú àwọn àlùfáà rẹ̀ Samuẹli wà nínú àwọn tí ó ń ké pe orúkọ rẹ̀ wọ́n ké pe Olúwa, ó sì dá wọn lóhùn.
在他的祭司中有摩西和亞倫; 在求告他名的人中有撒母耳。 他們求告耶和華,他就應允他們。
7 Ó sọ̀rọ̀ sí wọn nínú ọ̀wọ́n àwọsánmọ̀, wọ́n pa ẹ̀rí rẹ̀ mọ́ àti ìlànà tí ó fún wọn.
他在雲柱中對他們說話; 他們遵守他的法度和他所賜給他們的律例。
8 Olúwa Ọlọ́run wa, ó dá wọn lóhùn; ó jẹ́ Ọlọ́run tí ó ń dáríjì àwọn ọmọ Israẹli ìwọ tí ó ń fi ìyà àìṣedéédéé wọn jẹ wọ́n.
耶和華-我們的上帝啊,你應允他們; 你是赦免他們的上帝, 卻按他們所行的報應他們。
9 Gbígbéga ni Olúwa Ọlọ́run wa kí a sìn ín ní òkè mímọ́ rẹ̀ nítorí Olúwa Ọlọ́run wa jẹ́ mímọ́.
你們要尊崇耶和華-我們的上帝, 在他的聖山下拜, 因為耶和華-我們的上帝本為聖!