< Psalms 98 >

1 Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa, nítorí tí ó ṣe ohun ìyanu; ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti apá mímọ́ rẹ̀ o ṣe iṣẹ́ ìgbàlà fún un
A psalm. Oh, sing to Yahweh a new song, for he has done marvelous things; his right hand and his holy arm have given him victory.
2 Olúwa ti sọ ìgbàlà rẹ̀ di mí mọ̀ o fi òdodo rẹ̀ han àwọn orílẹ̀-èdè.
Yahweh has made known his salvation; he has openly showed his justice to all the nations.
3 Ó rántí ìfẹ́ rẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ fún àwọn ará ilé Israẹli; gbogbo òpin ayé ni ó ti rí iṣẹ́ ìgbàlà Ọlọ́run wa.
He calls to mind his covenant loyalty and faithfulness for the house of Israel; all the ends of the earth will see the victory of our God.
4 Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Olúwa, gbogbo ayé, ẹ bú sáyọ̀, ẹ kọrin ìyìn,
Shout for joy to Yahweh, all the earth; burst into song, sing for joy, and sing praises.
5 ẹ fi dùùrù kọrin sí Olúwa, pẹ̀lú dùùrù àti ìró ohùn orin mímọ́,
Sing praises to Yahweh with the harp, with the harp and melodious song.
6 pẹ̀lú ìpè àti fèrè ẹ hó fún ayọ̀ níwájú Olúwa ọba.
With trumpets and the sound of the horn, make a joyful noise before the King, Yahweh.
7 Jẹ́ kí òkun kí ó hó pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀, Gbogbo ayé àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.
Let the sea shout and everything in it, the world and those who live in it!
8 Ẹ jẹ́ kí odo kí ó ṣápẹ́, ẹ jẹ́ kí òkè kí ó kọrin pẹ̀lú ayọ̀;
Let the rivers clap their hands, and let the mountains shout for joy.
9 ẹ jẹ́ kí wọn kọrin níwájú Olúwa, nítorí tí yóò wá ṣèdájọ́ ayé bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè nínú òdodo àti àwọn ènìyàn ní àìṣègbè pẹ̀lú.
Yahweh is coming to judge the earth; he will judge the world with righteousness and the nations with fairness.

< Psalms 98 >