< Psalms 97 >
1 Olúwa jẹ ọba, jẹ́ kí ayé kí ó yọ̀ jẹ́ kí inú ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù kí ó dùn.
Yahweh reigns; let the earth rejoice; let the many coastlands be glad.
2 Ojú ọ̀run àti òkùnkùn yíká òdodo àti ìdájọ́ ni ó ṣe ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìtẹ́ rẹ̀.
Clouds and darkness surround him. Righteousness and justice are the foundation of his throne.
3 Iná ń jó níwájú rẹ̀. Ó sì ń jó àwọn ọ̀tá rẹ̀ yíkákiri.
Fire goes before him and consumes his adversaries on every side.
4 Ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tàn ó sì kárí ayé ayé rí i ó sì wárìrì.
His lightning lights up the world; the earth sees and trembles.
5 Òkè gíga yọ́ gẹ́gẹ́ bí ìda níwájú Olúwa, níwájú Olúwa gbogbo ayé.
The mountains melt like wax before Yahweh, the Lord of the whole earth.
6 Àwọn ọ̀run ròyìn òdodo rẹ̀, gbogbo ènìyàn sì rí ògo rẹ̀.
The skies declare his justice, and all the nations see his glory.
7 Gbogbo àwọn tí ń sin ère fínfín ni ojú yóò tì, àwọn tí ń fi ère gbéraga, ẹ máa sìn ín, gbogbo ẹ̀yin ọlọ́run!
All those who worship carved figures will be shamed, those who boast in worthless idols— bow down to him, all you gods!
8 Sioni gbọ́, inú rẹ̀ sì dùn inú àwọn ilé Juda sì dùn, nítorí ìdájọ́ rẹ, Olúwa.
Zion heard and was glad, and the towns of Judah rejoiced because of your righteous decrees, Yahweh.
9 Nítorí pé ìwọ, Olúwa, ni ó ga ju gbogbo ayé lọ ìwọ ni ó ga ju gbogbo òrìṣà lọ.
For you, Yahweh, are most high above all the earth. You are exalted far above all gods.
10 Jẹ kí gbogbo àwọn tí ó fẹ́ Olúwa, kórìíra ibi, ó pa ọkàn àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ mọ́ ó gbà wọ́n ní ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú.
You who love Yahweh, hate evil! He protects the lives of his saints, and he takes them out of the hand of the wicked.
11 Ìmọ́lẹ̀ tàn sórí àwọn olódodo àti ayọ̀ nínú àlàyé ọkàn.
Light is sown for the righteous and gladness for those with honest hearts.
12 Ẹ yọ̀ nínú Olúwa, ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ olódodo, kí ẹ sì yin orúkọ rẹ̀ mímọ́.
Be glad in Yahweh, you righteous; and give thanks when you remember his holiness.