< Psalms 95 >

1 Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a kọ orin ayọ̀ sí Olúwa, ẹ jẹ́ kí a kígbe sókè sí àpáta ìgbàlà wa.
לכו נרננה ליהוה נריעה לצור ישענו׃
2 Ẹ jẹ́ kí a wá sí iwájú rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́ kí a sì pòkìkí rẹ̀ pẹ̀lú ohun èlò orin àti ìyìn.
נקדמה פניו בתודה בזמרות נריע לו׃
3 Nítorí Olúwa Ọlọ́run títóbi ni, ọba tí ó tóbi ju gbogbo òrìṣà lọ.
כי אל גדול יהוה ומלך גדול על כל אלהים׃
4 Ní ọwọ́ rẹ̀ ni ọ̀gbun ilẹ̀ wà, ṣóńṣó orí òkè tirẹ̀ ní ṣe.
אשר בידו מחקרי ארץ ותועפות הרים לו׃
5 Tirẹ̀ ni Òkun, nítorí òun ni ó dá a àti ọwọ́ rẹ̀ ni ó fi dá ìyàngbẹ ilẹ̀.
אשר לו הים והוא עשהו ויבשת ידיו יצרו׃
6 Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a foríbalẹ̀ kí a sìn ín, ẹ jẹ́ kí a kúnlẹ̀ níwájú Olúwa ẹni tí ó dá wa,
באו נשתחוה ונכרעה נברכה לפני יהוה עשנו׃
7 nítorí òun ni Ọlọ́run wa, àwa sì ni ènìyàn pápá rẹ̀, àti ọ̀wọ́ ẹran ni abẹ́ ìpamọ́ rẹ̀. Lónìí tí ìwọ bá gbọ́ ohùn rẹ̀,
כי הוא אלהינו ואנחנו עם מרעיתו וצאן ידו היום אם בקלו תשמעו׃
8 “Ẹ má ṣe sé ọkàn yín le gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ṣe ní Meriba, àti bí ẹ ti ṣe ní ọjọ́ náà ní Massa ní aginjù,
אל תקשו לבבכם כמריבה כיום מסה במדבר׃
9 nígbà tí àwọn baba yín dán mi wò tí wọn wádìí mi, tí wọn sì rí iṣẹ́ mi.
אשר נסוני אבותיכם בחנוני גם ראו פעלי׃
10 Fún ogójì ọdún ni èmi fi bínú sí ìran náà; mo wí pé, ‘Wọ́n jẹ́ ènìyàn tí ọkàn wọn ṣáko lọ wọn kò sì mọ ọ̀nà mi.’
ארבעים שנה אקוט בדור ואמר עם תעי לבב הם והם לא ידעו דרכי׃
11 Nítorí náà ni mo kéde ìbúra nínú ìbínú mi, ‘Wọn kì yóò wọ ibi ìsinmi mi.’”
אשר נשבעתי באפי אם יבאון אל מנוחתי׃

< Psalms 95 >