< Psalms 94 >

1 Olúwa Ọlọ́run ẹni tí ń gbẹ̀san, Ọlọ́run ẹni tí ń gbẹ̀san.
אל נקמות יהוה אל נקמות הופיע׃
2 Gbé ara rẹ sókè, ìwọ onídàájọ́ ayé; san ẹ̀san fún agbéraga ohun tí ó yẹ wọ́n.
הנשא שפט הארץ השב גמול על גאים׃
3 Báwo ní yóò ti pẹ́ tó, Olúwa tí àwọn ẹni búburú yóò kọ orin ayọ̀?
עד מתי רשעים יהוה עד מתי רשעים יעלזו׃
4 Wọ́n ń sọ̀rọ̀ ìgbéraga jáde; gbogbo àwọn olùṣe búburú kún fún ìṣògo.
יביעו ידברו עתק יתאמרו כל פעלי און׃
5 Wọ́n fọ́ àwọn ènìyàn rẹ túútúú, Olúwa: wọ́n pọ́n ilẹ̀ ìní rẹ̀ lójú.
עמך יהוה ידכאו ונחלתך יענו׃
6 Wọ́n pa àwọn opó àti àlejò, wọ́n sì pa àwọn ọmọ aláìní baba.
אלמנה וגר יהרגו ויתומים ירצחו׃
7 Wọ́n sọ pé, “Olúwa kò rí i; Ọlọ́run Jakọbu kò sì kíyèsi i.”
ויאמרו לא יראה יה ולא יבין אלהי יעקב׃
8 Kíyèsi i, ẹ̀yin aláìlóye nínú àwọn ènìyàn; ẹ̀yin aṣiwèrè, nígbà wo ni ẹ̀yin yóò lóye?
בינו בערים בעם וכסילים מתי תשכילו׃
9 Ẹni tí ó gbin etí, ó lè ṣe aláìgbọ́ bí? Ẹni tí ó dá ojú? Ó ha lè ṣe aláìríran bí?
הנטע אזן הלא ישמע אם יצר עין הלא יביט׃
10 Ẹni tí ń bá orílẹ̀-èdè wí, ṣé kò lè tọ́ ni ṣọ́nà bí? Ẹni tí ń kọ́ ènìyàn ha lè ṣàìní ìmọ̀ bí?
היסר גוים הלא יוכיח המלמד אדם דעת׃
11 Olúwa mọ èrò inú ènìyàn; ó mọ̀ pé asán ni wọ́n.
יהוה ידע מחשבות אדם כי המה הבל׃
12 Ìbùkún ni fún ènìyàn náà tí ìwọ bá wí, Olúwa, ẹni tí ìwọ kọ́ nínú òfin rẹ,
אשרי הגבר אשר תיסרנו יה ומתורתך תלמדנו׃
13 Ìwọ gbà á kúrò nínú ọjọ́ ibi, títí a ó fi wa ihò sílẹ̀ fún ẹni búburú.
להשקיט לו מימי רע עד יכרה לרשע שחת׃
14 Nítorí Olúwa kò ní kọ àwọn ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀, Òun kò sì ní kọ ilẹ̀ ìní rẹ̀ sílẹ̀.
כי לא יטש יהוה עמו ונחלתו לא יעזב׃
15 Ìdájọ́ yóò padà sí òdodo, àti gbogbo àwọn ọlọ́kàn dídúró ṣinṣin yóò tẹ̀lé e lẹ́yìn.
כי עד צדק ישוב משפט ואחריו כל ישרי לב׃
16 Ta ni yóò dìde fún mi sí àwọn olùṣe búburú? Tàbí ta ni yóò dìde sí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ fún mi?
מי יקום לי עם מרעים מי יתיצב לי עם פעלי און׃
17 Bí kò ṣe pé Olúwa fún mi ní ìrànlọ́wọ́, èmi fẹ́rẹ̀ máa gbé ní ilẹ̀ tí ó dákẹ́.
לולי יהוה עזרתה לי כמעט שכנה דומה נפשי׃
18 Nígbà tí mo sọ pé, “Ẹsẹ̀ mi ń yọ̀”, Olúwa, ìfẹ́ rẹ̀ ni ó tì mí lẹ́yìn.
אם אמרתי מטה רגלי חסדך יהוה יסעדני׃
19 Nígbà tí àníyàn ńlá wà nínú mi, ìtùnú rẹ̀ mú ayọ̀ sí ọkàn mi.
ברב שרעפי בקרבי תנחומיך ישעשעו נפשי׃
20 Ìjọba ìbàjẹ́ ha lè kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú rẹ ẹni tí ń fi òfin dì mọ́ ìwà ìkà?
היחברך כסא הוות יצר עמל עלי חק׃
21 Wọ́n kó ara wọn jọ sí olódodo wọ́n sì ń dá àwọn aláìṣẹ̀ lẹ́bi sí ikú.
יגודו על נפש צדיק ודם נקי ירשיעו׃
22 Ṣùgbọ́n, Olúwa ti di odi alágbára mi, àti Ọlọ́run mi ni àpáta nínú ẹni tí mo ti ń gba ààbò.
ויהי יהוה לי למשגב ואלהי לצור מחסי׃
23 Òun yóò san ẹ̀san ibi wọn fún wọn yóò sì pa wọ́n run nítorí búburú wọn Olúwa Ọlọ́run wa yóò pa wọ́n run.
וישב עליהם את אונם וברעתם יצמיתם יצמיתם יהוה אלהינו׃

< Psalms 94 >