< Psalms 90 >

1 Àdúrà Mose ènìyàn Ọlọ́run. Olúwa, ìwọ ti jẹ́ ibùgbé wa ní gbogbo ìran dé ìran.
תפלה למשה איש-האלהים אדני--מעון אתה היית לנו בדר ודר
2 Kí a tó bí àwọn òkè ńlá àti kí ìwọ tó dá ilẹ̀ àti ayé, láti ayérayé dé ayérayé ìwọ ni Ọlọ́run.
בטרם הרים ילדו-- ותחולל ארץ ותבל ומעולם עד-עולם אתה אל
3 Ìwọ yí ènìyàn padà sí erùpẹ̀, wí pé, “Padà sí erùpẹ̀, ìwọ ọmọ ènìyàn.”
תשב אנוש עד-דכא ותאמר שובו בני-אדם
4 Nítorí pé ìgbà tí ẹgbẹ̀rún ọdún bá kọjá lójú rẹ, bí àná ni ó rí, bí ìgbà ìṣọ́ kan lóru.
כי אלף שנים בעיניך-- כיום אתמול כי יעבר ואשמורה בלילה
5 Ìwọ gbá ènìyàn dànù nínú oorun ikú; wọ́n dàbí koríko tuntun ní òwúrọ̀.
זרמתם שנה יהיו בבקר כחציר יחלף
6 Lóòtítọ́, ní òwúrọ̀, ó yọ tuntun ní àṣálẹ́ ni yóò gbẹ, tí yóò sì rẹ̀ dànù.
בבקר יציץ וחלף לערב ימולל ויבש
7 A pa wá run nípa ìbínú rẹ nípa ìbínú rẹ ara kò rọ̀ wá.
כי-כלינו באפך ובחמתך נבהלנו
8 Ìwọ ti gbé ẹ̀ṣẹ̀ wa ka iwájú rẹ, àti ohun ìkọ̀kọ̀ wa nínú ìmọ́lẹ̀ iwájú rẹ.
שת (שתה) עונתינו לנגדך עלמנו למאור פניך
9 Gbogbo ọjọ́ wa ń kọjá lọ lábẹ́ ìbínú rẹ; àwa ń lo ọjọ́ wa lọ bí àlá tí à ń rọ́.
כי כל-ימינו פנו בעברתך כלינו שנינו כמו-הגה
10 Àádọ́rin ọdún ni iye ọjọ́ ọdún wá, bi ó sì ṣe pé nípa agbára tí wọn bá tó ọgọ́rin ọdún, agbára nínú làálàá pẹ̀lú ìbànújẹ́ ni, nítorí pé a kò ní pẹ́ gé e kúrò, àwa a sì fò lọ.
ימי-שנותינו בהם שבעים שנה ואם בגבורת שמונים שנה-- ורהבם עמל ואון כי-גז חיש ונעפה
11 Ta ni ó mọ agbára ìbínú rẹ? Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rù rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ìbínú rẹ.
מי-יודע עז אפך וכיראתך עברתך
12 Kọ́ wa bí a ti ń kaye ọjọ́ wa dáradára, kí àwa ba à lè fi ọkàn wa sípa ọgbọ́n.
למנות ימינו כן הודע ונבא לבב חכמה
13 Yípadà, Olúwa! Yóò ti pẹ́ tó? Ṣàánú fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ.
שובה יהוה עד-מתי והנחם על-עבדיך
14 Tẹ́ wa lọ́rùn ní òwúrọ̀ nínú ìṣeun ìfẹ́ rẹ, kí àwa kí ó lè kọrin fún ayọ̀ kí inú wa sì dùn ní gbogbo ọjọ́.
שבענו בבקר חסדך ונרננה ונשמחה בכל-ימינו
15 Mú inú wa dùn bí ọjọ́ tí ìwọ ti pọ́n wa lójú, fún ọjọ́ púpọ̀ tí àwa ti rí wàhálà.
שמחנו כימות עניתנו שנות ראינו רעה
16 Jẹ́ kí a fi iṣẹ́ rẹ̀ han àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, ògo rẹ̀ sí àwọn ọmọ wọn.
יראה אל-עבדיך פעלך והדרך על-בניהם
17 Jẹ́ kí ẹwà Olúwa Ọlọ́run wa wà lára wa; fi ìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀ lára wa, bẹ́ẹ̀ ni, kí ó sì fi ìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀.
ויהי נעם אדני אלהינו-- עלינו ומעשה ידינו כוננה עלינו ומעשה ידינו כוננהו

< Psalms 90 >