< Psalms 9 >

1 Fún adarí orin. Ní ti ohun orin. “Ní ti ikú ọmọ.” Saamu ti Dafidi. Èmi ó yìn ọ́, Olúwa, pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi; èmi ó sọ ti ìyanu rẹ gbogbo.
εἰς τὸ τέλος ὑπὲρ τῶν κρυφίων τοῦ υἱοῦ ψαλμὸς τῷ Δαυιδ ἐξομολογήσομαί σοι κύριε ἐν ὅλῃ καρδίᾳ μου διηγήσομαι πάντα τὰ θαυμάσιά σου
2 Inú mi yóò dùn, èmi yóò sì yọ̀ nínú rẹ; èmi ó kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ, Ìwọ Ọ̀gá-Ògo jùlọ.
εὐφρανθήσομαι καὶ ἀγαλλιάσομαι ἐν σοί ψαλῶ τῷ ὀνόματί σου ὕψιστε
3 Àwọn ọ̀tá mi pẹ̀yìndà; wọ́n kọsẹ̀ wọn sì ṣègbé níwájú rẹ.
ἐν τῷ ἀποστραφῆναι τὸν ἐχθρόν μου εἰς τὰ ὀπίσω ἀσθενήσουσιν καὶ ἀπολοῦνται ἀπὸ προσώπου σου
4 Nítorí ìwọ ti di òtítọ́ àti ọ̀ràn mi mú; ìwọ ti jókòó lórí ìtẹ́ rẹ, láti ṣe ìdájọ́ òdodo.
ὅτι ἐποίησας τὴν κρίσιν μου καὶ τὴν δίκην μου ἐκάθισας ἐπὶ θρόνου ὁ κρίνων δικαιοσύνην
5 Ìwọ ti bá orílẹ̀-èdè wí, Ìwọ sì ti pa ẹni búburú run; Ìwọ ti yọ orúkọ wọn kúrò láé àti láéláé.
ἐπετίμησας ἔθνεσιν καὶ ἀπώλετο ὁ ἀσεβής τὸ ὄνομα αὐτῶν ἐξήλειψας εἰς τὸν αἰῶνα καὶ εἰς τὸν αἰῶνα τοῦ αἰῶνος
6 Ìparun àìlópin ti borí àwọn ọ̀tá, ìwọ ti fa àwọn ìlú wọn tu; àní ìrántí wọn sì ti ṣègbé.
τοῦ ἐχθροῦ ἐξέλιπον αἱ ῥομφαῖαι εἰς τέλος καὶ πόλεις καθεῖλες ἀπώλετο τὸ μνημόσυνον αὐτῶν μετ’ ἤχους
7 Olúwa jẹ ọba títí láé; ó ti gbé ìtẹ́ rẹ̀ kalẹ̀ fún ìdájọ́.
καὶ ὁ κύριος εἰς τὸν αἰῶνα μένει ἡτοίμασεν ἐν κρίσει τὸν θρόνον αὐτοῦ
8 Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ ayé ní òdodo; yóò ṣe àkóso ènìyàn pẹ̀lú òdodo.
καὶ αὐτὸς κρινεῖ τὴν οἰκουμένην ἐν δικαιοσύνῃ κρινεῖ λαοὺς ἐν εὐθύτητι
9 Olúwa ni ààbò fún àwọn tí a ni lára, ibi ìsádi ní àkókò ìpọ́njú.
καὶ ἐγένετο κύριος καταφυγὴ τῷ πένητι βοηθὸς ἐν εὐκαιρίαις ἐν θλίψει
10 Àwọn tí ó mọ orúkọ rẹ yóò gbẹ́kẹ̀lé ọ, nítorí, Olúwa, kò kọ àwọn tó ń wá a sílẹ̀.
καὶ ἐλπισάτωσαν ἐπὶ σὲ οἱ γινώσκοντες τὸ ὄνομά σου ὅτι οὐκ ἐγκατέλιπες τοὺς ἐκζητοῦντάς σε κύριε
11 Kọ orin ìyìn sí Olúwa, tí o ń jẹ ọba ní Sioni; kéde láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ohun tí ó ṣe.
ψάλατε τῷ κυρίῳ τῷ κατοικοῦντι ἐν Σιων ἀναγγείλατε ἐν τοῖς ἔθνεσιν τὰ ἐπιτηδεύματα αὐτοῦ
12 Nítorí ẹni tí ó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ rántí; òun kò kọ ẹkún àwọn tí a pọ́n lójú.
ὅτι ἐκζητῶν τὰ αἵματα αὐτῶν ἐμνήσθη οὐκ ἐπελάθετο τῆς κραυγῆς τῶν πενήτων
13 Olúwa, wo bí àwọn ọ̀tá ṣe ń ṣe inúnibíni sí mi! Ṣàánú, kí o sì gbé mí sókè kúrò ní ẹnu-ọ̀nà ikú,
ἐλέησόν με κύριε ἰδὲ τὴν ταπείνωσίν μου ἐκ τῶν ἐχθρῶν μου ὁ ὑψῶν με ἐκ τῶν πυλῶν τοῦ θανάτου
14 kí èmi kí ó lè sọ ti ìyìn rẹ ni ẹnu-ọ̀nà àwọn ọmọbìnrin Sioni àti láti máa yọ̀ nínú ìgbàlà rẹ.
ὅπως ἂν ἐξαγγείλω πάσας τὰς αἰνέσεις σου ἐν ταῖς πύλαις τῆς θυγατρὸς Σιων ἀγαλλιάσομαι ἐπὶ τῷ σωτηρίῳ σου
15 Àwọn orílẹ̀-èdè ti jì sí kòtò tí wọn ti gbẹ́; ẹsẹ̀ wọn ni àwọ̀n tí wọ́n dẹ sílẹ̀ kọ́.
ἐνεπάγησαν ἔθνη ἐν διαφθορᾷ ᾗ ἐποίησαν ἐν παγίδι ταύτῃ ᾗ ἔκρυψαν συνελήμφθη ὁ ποὺς αὐτῶν
16 A mọ Olúwa nípa òdodo rẹ̀; àwọn ènìyàn búburú ni a dẹ́kun mú nípa iṣẹ́ ọwọ́ wọn.
γινώσκεται κύριος κρίματα ποιῶν ἐν τοῖς ἔργοις τῶν χειρῶν αὐτοῦ συνελήμφθη ὁ ἁμαρτωλός ᾠδὴ διαψάλματος
17 Àwọn ènìyàn búburú ni a ó dà sí isà òkú, àti gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó gbàgbé Ọlọ́run. (Sheol h7585)
ἀποστραφήτωσαν οἱ ἁμαρτωλοὶ εἰς τὸν ᾅδην πάντα τὰ ἔθνη τὰ ἐπιλανθανόμενα τοῦ θεοῦ (Sheol h7585)
18 Ṣùgbọ́n àwọn aláìní ni a kò ní gbàgbé láéláé, ìrètí àwọn ti ó tálákà ni a kì yóò gbàgbé láéláé.
ὅτι οὐκ εἰς τέλος ἐπιλησθήσεται ὁ πτωχός ἡ ὑπομονὴ τῶν πενήτων οὐκ ἀπολεῖται εἰς τὸν αἰῶνα
19 Dìde, Olúwa, má ṣe jẹ́ kí ènìyàn borí; jẹ́ kí a ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè ni iwájú rẹ.
ἀνάστηθι κύριε μὴ κραταιούσθω ἄνθρωπος κριθήτωσαν ἔθνη ἐνώπιόν σου
20 Lù wọ́n pẹ̀lú ìpayà, Olúwa; jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè mọ̀ pé ènìyàn lásán ni wọ́n. (Sela)
κατάστησον κύριε νομοθέτην ἐπ’ αὐτούς γνώτωσαν ἔθνη ὅτι ἄνθρωποί εἰσιν διάψαλμα

< Psalms 9 >