< Psalms 89 >

1 Maskili ti Etani ará Esra. Èmi kọrin títóbi ìfẹ́ Olúwa títí láé; pẹ̀lú ẹnu mi ní èmi yóò jẹ́ kí a mọ òtítọ́ rẹ láti ìran dé ìran.
[A contemplation by Ethan, the Ezrahite.] I will sing of the loving kindness of the LORD forever. With my mouth I will make known your faithfulness to all generations.
2 Èmi ó wí pé, ìfẹ́ rẹ dúró títí láé, pé ìwọ gbe òtítọ́ rẹ kalẹ̀ ní ọ̀run fúnra rẹ̀.
I indeed declare, "Love stands firm forever. You established the heavens. Your faithfulness is in them."
3 Ìwọ wí pé, “Èmi ti dá májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn àyànfẹ́ mi mo ti búra fún Dafidi ìránṣẹ́ mi.
"I have made a covenant with my chosen one, I have sworn to David, my servant,
4 ‘Èmi ó fi ìdí irú-ọmọ rẹ múlẹ̀ títí láé èmí ó sì máa gbe ìtẹ́ rẹ ró láti ìran dé ìran.’”
'I will establish your offspring forever, and build up your throne for all generations.'" (Selah)
5 Àwọn ọ̀run yóò máa yin iṣẹ́ ìyanu rẹ, Olúwa, òtítọ́ rẹ ni ìpéjọpọ̀ àwọn ẹni mímọ́.
The heavens will praise your wonders, LORD; your faithfulness also in the assembly of the holy ones.
6 Ta ni ó wà ní ọ̀run tí a lè fiwé Olúwa? Ta ni nínú àwọn ọmọ alágbára ti a lè fiwé Olúwa?
For who in the skies can be compared to the LORD? Who among the sons of God is like the LORD,
7 Nínú àjọ ìgbìmọ̀ ẹni mímọ́, wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run gidigidi; ó sì ní ìbùyìn fún ju gbogbo àwọn tí ó yí i ká.
a very awesome God in the council of the holy ones, to be feared above all those who are around him?
8 Olúwa Ọlọ́run alágbára, ta ló dàbí rẹ ìwọ jẹ́ alágbára, Olúwa, òtítọ́ rẹ sì yí ọ ká.
LORD, God of hosts, who is a mighty one like you, LORD? Your faithfulness is around you.
9 Ìwọ ń darí ríru omi Òkun; nígbà tí ó ru àwọn omi sókè, ìwọ mú wọn parọ́rọ́.
You rule the pride of the sea. When its waves rise up, you calm them.
10 Ìwọ ni ó ti ya Rahabu pẹ́rẹpẹ̀rẹ bí ẹni tí a pa; ìwọ ti fi apá ọwọ́ agbára rẹ tú àwọn ọ̀tá rẹ ká.
You have broken Rahab in pieces, like one of the slain. You have scattered your enemies with your mighty arm.
11 Tìrẹ ní àwọn ọ̀run, ayé pẹ̀lú jẹ́ tìrẹ: ayé àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀: ìwọ ti gbé wọn kalẹ̀.
The heavens are yours. The earth also is yours; the world and its fullness. You have founded them.
12 Gúúsù àti àríwá ìwọ ni ó dá wọn; Tabori àti Hermoni ń fi ayọ̀ yin orúkọ rẹ.
The north and the south, you have created them. Tabor and Hermon rejoice in your name.
13 Ìwọ ní apá agbára; agbára ní ọwọ́ rẹ, gíga ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.
You have a mighty arm. Your hand is strong, and your right hand is exalted.
14 Òdodo àti òtítọ́ ni ìpìlẹ̀ ìtẹ́ rẹ: ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ àti òtítọ́ ń lọ síwájú rẹ.
Righteousness and justice are the foundation of your throne. Loving kindness and truth go before your face.
15 Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn tí wọn mọ ohùn ayọ̀ nì, Olúwa wọ́n ó máa rìn ní ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ.
Blessed are the people who know the joyful shout. They walk in the light of your presence, LORD.
16 Wọn ń ṣògo nínú orúkọ rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́, wọn ń yin òdodo rẹ.
In your name they rejoice all day. In your righteousness, they are exalted.
17 Nítorí ìwọ ni ògo agbára wọn; nípa ojúrere ni ìwo wá ń ṣògo.
For you are the glory of their strength. In your favor, our horn will be exalted.
18 Nítorí ti Olúwa ni asà wa, ọba wa sì ni Ẹni Mímọ́ Israẹli.
For our shield belongs to the LORD; our king to the Holy One of Israel.
19 Nígbà náà ni ìwọ sọ̀rọ̀ nínú ìran, sí àwọn olóòtítọ́ rẹ, wí pé, “Èmi ti gbé adé kalẹ̀ sórí ẹni tí ó lágbára, èmi ti gbé ẹni tí a yàn láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn ga.
Then you spoke in a vision to your faithful ones, and said, "I have bestowed strength on the warrior. I have exalted a young man from the people.
20 Èmi ti rí Dafidi ìránṣẹ́ mi; pẹ̀lú òróró mímọ́ mi ni mo fi yàn án.
I have found David, my servant. I have anointed him with my holy oil,
21 Ìgbà gbogbo ni ọwọ́ mi yóò máa wà pẹ̀lú rẹ̀ apá mí yóò sì fi agbára fún un.
with whom my hand shall be established. My arm will also strengthen him.
22 Àwọn ọ̀tá kì yóò borí rẹ̀, àwọn ènìyàn búburú kì yóò rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀.
No enemy will tax him. No wicked man will oppress him.
23 Èmi yóò run àwọn ọ̀tá rẹ níwájú rẹ èmi yóò lu àwọn tí ó kórìíra rẹ bolẹ̀.
I will beat down his adversaries before him, and strike those who hate him.
24 Òtítọ́ mi àti ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ yóò wà pẹ̀lú rẹ àti ní orúkọ mi ni a ó gbé ìwo rẹ ga.
But my faithfulness and my loving kindness will be with him. In my name, his horn will be exalted.
25 Èmi ó gbé ọwọ́ rẹ lórí òkun, àti ọwọ́ ọ̀tún rẹ lórí àwọn odo ńlá.
I will set his hand also on the sea, and his right hand on the rivers.
26 Òun yóò kígbe sí mi pé, ‘Ìwọ ni baba mi, Ọlọ́run mi, àti àpáta ìgbàlà mi!’
He will call to me, 'You are my Father, my God, and the rock of my salvation.'
27 Èmi yóò ṣe é ni àkọ́bí mi, ẹni gíga ju àwọn ọba ayé.
I will also appoint him my firstborn, the highest of the kings of the earth.
28 Títí láé ni èmi yóò pa ìfẹ́ dídúró ṣinṣin mọ́ fún un, àti májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ̀ yóò dúró gbọingbọin.
I will keep my loving kindness for him forevermore. My covenant will stand firm with him.
29 Èmi ó fi ìdí irú-ọmọ rẹ̀ múlẹ̀ títí láé, àti ìtẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀run ti wà láé.
And I will establish his descendants forever, and his throne as the days of heaven.
30 “Bí àwọn ọmọ rẹ̀ bá kọ òfin mi sílẹ̀ tí wọn kò sì rìn gẹ́gẹ́ bí ìlànà mi.
If his children forsake my Law, and do not walk in my ordinances;
31 Tí wọn bá ba ìlànà mi jẹ́ tí wọn kò sì pa àṣẹ mi mọ́,
if they break my statutes, and do not keep my commandments;
32 nígbà náà ni èmi ó fì ọ̀gọ̀ bẹ ìrékọjá wọn wò; àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn pẹ̀lú pàṣán;
then I will punish their sin with the rod, and their iniquity with stripes.
33 ṣùgbọ́n èmi kò ní mú ìfẹ́ mi tí ó dúró ṣinṣin kúrò lọ́dọ̀ rẹ, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò jẹ́ kí òtítọ́ mi kí ó yẹ̀.
But I will not completely take my loving kindness from him, nor allow my faithfulness to fail.
34 Èmi kì yóò sẹ́ májẹ̀mú mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò yí ọ̀rọ̀ tí ó ti ẹnu mi jáde padà.
I will not break my covenant, nor alter what my lips have uttered.
35 Lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo ni èmi ti fi ìwà mímọ́ mi búra; èmi kì yóò purọ́ fún Dafidi.
Once have I sworn by my holiness, I will not lie to David.
36 Irú-ọmọ rẹ yóò dúró títí láé, àti ìtẹ́ rẹ̀ yóò dúró bí oòrùn níwájú mi.
His descendants will endure forever, his throne like the sun before me.
37 A ó fi múlẹ̀ títí láé bí òṣùpá, àti bi ẹlẹ́rìí òtítọ́ ni ọ̀run.” (Sela)
It will be established forever like the moon, the faithful witness in the sky." (Selah)
38 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ìwọ ti ṣá tì, ìwọ sì kórìíra; ìwọ kún fún ìrunú sí ẹni àmì òróró rẹ.
But you have rejected and spurned. You have been angry with your anointed.
39 Ìwọ ti sọ májẹ̀mú ìránṣẹ́ rẹ di òfo; ìwọ tàbùkù adé rẹ nínú eruku.
You have renounced the covenant of your servant. You have defiled his crown in the dust.
40 Ìwọ ti wó gbogbo àwọn odi rẹ̀ ìwọ sọ ibi gíga rẹ̀ di ahoro.
You have broken down all his hedges. You have brought his strongholds to ruin.
41 Àwọn tí ń kọjá lọ fi ṣe ìjẹ; ó ti di ẹ̀gàn àwọn olùbágbé rẹ̀.
All who pass by the way rob him. He has become an object of ridicule to his neighbors.
42 Ìwọ ti gbé ọwọ́ ọ̀tún ọ̀tá rẹ̀ sókè; ìwọ mú gbogbo ọ̀tá rẹ̀ yọ̀.
You have exalted the right hand of his adversaries. You have made all of his enemies rejoice.
43 Pẹ̀lú, ìwọ ti yí ojú idà rẹ̀ padà, ìwọ kò sì dúró tì í nínú ogun.
Yes, you turn back the edge of his sword, and haven't supported him in battle.
44 Ìwọ ti mú ògo rẹ̀ kùnà, ìwọ si wó ìtẹ́ rẹ̀ palẹ̀ sílẹ̀ẹ́lẹ̀.
You have ended his splendor, and thrown his throne down to the ground.
45 Ìwọ ti gé ọjọ́ èwe rẹ̀ kúrú; ìwọ sì fi ìtìjú bò ó.
You have shortened the days of his youth. You have covered him with shame. (Selah)
46 Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa? Tí ìwọ ó ha fi ara rẹ pamọ́ títí láé? Yóò ti pẹ́ to tí ìbínú rẹ yóò máa jó bí iná?
How long, LORD? Will you hide yourself forever? Will your wrath burn like fire?
47 Rántí bí ọjọ́ mi ti kúrú tó nítorí asán ha ni ìwọ fi ṣẹ̀dá àwọn ènìyàn!
Remember how short my time is. Have you created the descendants of Adam for no reason?
48 Ta ni yóò wà láààyè tí kò ní rí ikú rẹ̀? Ta ló lè sá kúrò nínú agbára isà òkú? (Sheol h7585)
What man is he who shall live and not see death, who shall deliver his soul from the power of Sheol? (Selah) (Sheol h7585)
49 Olúwa, níbo ni ìṣeun ìfẹ́ rẹ àtijọ́ wà, tí ìwọ ti fi òtítọ́ rẹ búra fún Dafidi?
LORD, where are your former loving kindnesses, which you swore to David in your faithfulness?
50 Rántí, Olúwa, bí a ti ń gan àwọn ìránṣẹ́ rẹ; bí èmi ti gbà ní àyà mi láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn,
Remember, LORD, the ridicule of all the many peoples against your servants I have borne in my heart,
51 ẹ̀gàn tí àwọn ọ̀tá rẹ gàn, Olúwa, tí wọn gan ipasẹ̀ ẹni àmì òróró rẹ.
how your enemies have ridiculed, LORD, how they have ridiculed the footsteps of your anointed one.
52 Olùbùkún ní Olúwa títí láé.
Blessed be the LORD forevermore. Amen, and Amen.

< Psalms 89 >