< Psalms 88 >
1 Orin. Saamu ti àwọn ọmọ Kora. Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti mahalati leannoti. Maskili ti Hemani ará Esra. Olúwa, Ọlọ́run tí ó gbà mí là, ní ọ̀sán àti ní òru, mo kígbe sókè sí Ọ.
A song of a Psalm for the sons of Core for the end, upon Maeleth for responsive [strains], of instruction for Aeman the Israelite. O Lord God of my salvation, I have cried by day and in the night before thee.
2 Jẹ́ kí àdúrà mi kí ó wá sí iwájú rẹ; dẹ etí rẹ sí igbe mi.
Let my prayer come in before thee; incline thine ear to my supplication, O Lord.
3 Nítorí ọkàn mi kún fún ìpọ́njú ọkàn mi sì súnmọ́ isà òkú. (Sheol )
For my soul is filled with troubles, and my life has drawn nigh to Hades. (Sheol )
4 A kà mí mọ́ àwọn tí wọ́n lọ sí ọ̀gbun ilẹ̀ èmi dàbí ọkùnrin tí kò ni agbára.
I have been reckoned with them that go down to the pit; I became as a man without help;
5 A yà mí sọ́tọ̀ pẹ̀lú àwọn òkú bí ẹni tí a pa tí ó dùbúlẹ̀ ní ipò ikú, ẹni tí ìwọ kò rántí mọ́, ẹni tí a gé kúrò lára àwọn tí ìwọ ń tọ́jú.
free among the dead, as the slain ones cast out, who sleep in the tomb; whom thou rememberest no more; and they are rejected from thy hand.
6 Ìwọ tí ó fi mí sí kòtò jíjìn, ní ibi ọ̀gbun tó ṣókùnkùn.
They laid me in the lowest pit, in dark [places], and in the shadow of death.
7 Ìbínú rẹ ṣubú lé mi gidigidi; ìwọ ti fi àwọn ìjì rẹ borí mi.
Thy wrath has pressed heavily upon me, and thou hast brought upon me all thy billows. (Pause)
8 Ìwọ tí gba ọ̀rẹ́ mi tí ó súnmọ́ mi kúrò lọ́wọ́ mi ìwọ sì sọ mi di ìríra sí wọn. A há mi mọ́, èmi kò sì le è jáde;
Thou hast removed my acquaintance far from me; they have made me an abomination to themselves; I have been delivered up, and have not gone forth.
9 ojú mi káàánú nítorí ìpọ́njú. Mo kígbe pè ọ́, Olúwa, ní gbogbo ọjọ́; mo na ọwọ́ mi jáde sí ọ.
Mine eyes are dimmed from poverty; but I cried to thee, O Lord, all the day; I spread forth my hands to thee.
10 Ìwọ ó fi iṣẹ́ ìyanu rẹ hàn fún òkú bi? Àwọn òkú yóò ha dìde láti yìn ọ́ bí?
Wilt thou work wonders for the dead? or shall physicians raise [them] up, that they shall praise thee?
11 A ó ha fi ìṣeun ìfẹ́ rẹ hàn ní ibojì bí, tàbí òtítọ́ rẹ ní ipò ìparun?
Shall any one declare thy mercy in the tomb? and thy truth in destruction?
12 A ha lè mọ iṣẹ́ ìyanu rẹ ní òkùnkùn bí àti òdodo rẹ ní ilẹ̀ ìgbàgbé?
Shall thy wonders be known in darkness? and thy righteousness in a forgotten land?
13 Ṣùgbọ́n mo kígbe sí ọ fún ìrànlọ́wọ́, Olúwa; ní òwúrọ̀ ni àdúrà mí wá sọ́dọ̀ rẹ.
But I cried to thee, O Lord; and in the morning shall my prayer prevent thee.
14 Olúwa, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí tí ìwọ fi ojú rẹ pamọ́ fún mi?
Wherefore, O Lord, dost thou reject my prayer, [and] turn thy face away from me?
15 Láti ìgbà èwe mi, ìṣẹ́ ń ṣẹ́ mi, èmi múra àti kú; nígbà tí ẹ̀rù rẹ bá ń bà mí, èmi di gbére-gbère.
I am poor and in troubles from my youth; and having been exalted, I was brought low and into despair.
16 Ìbínú rẹ ti kọjá lára mi; ìbẹ̀rù rẹ ti gé mi kúrò.
Thy wrath has passed over me; and thy terrors have greatly disquieted me.
17 Ní gbogbo ọjọ́ ni wọn yí mi ká bí ìkún omi; wọ́n mù mí pátápátá.
They compassed me like water; all the day they beset me together.
18 Ìwọ ti mú ọ̀rẹ́ àti olùfẹ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi; òkùnkùn sì jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ mi.
Thou hast put far from me [every] friend, and mine acquaintances because of [my] wretchedness.