< Psalms 87 >

1 Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu. Orin. Ó ti fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ sórí òkè mímọ́;
Of the sons of Korah. A Psalm. A Song. This house is resting on the holy mountain.
2 Olúwa fẹ́ràn ẹnu-ọ̀nà Sioni ju gbogbo ibùgbé Jakọbu lọ.
The Lord has more love for the doors of Zion than for all the tents of Jacob.
3 Ohun ológo ni a sọ nípa rẹ̀, ìlú Ọlọ́run,
Noble things are said of you, O town of God. (Selah)
4 “Èmi ó dárúkọ Rahabu àti Babeli láàrín àwọn tí ó jẹ́wọ́ mi: Filistia pẹ̀lú, àti Tire, pẹ̀lú Kuṣi, yóò sọ pé, ‘Èyí ni a bí ní Sioni.’”
Rahab and Babylon will be named among those who have knowledge of me; see, Philistia and Tyre, with Ethiopia; this man had his birth there.
5 Nítòótọ́, ti Sioni ni a ó sọ, “Eléyìí àti eléyìí ni a bí nínú rẹ̀, àti Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo ni yóò fìdí rẹ̀ múlẹ̀.”
And of Zion it will be said, This or that man had his birth there; and the Most High will make her strong.
6 Olúwa yóò kọ nínú àkọsílẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀: “Eléyìí ni a bí ní Sioni.”
The Lord will keep in mind, when he is writing the records of the people, that this man had his birth there. (Selah)
7 Àti àwọn olórin àti àwọn tí ń lu ohun èlò orin yóò wí pé, “Gbogbo orísun mi ń bẹ nínú rẹ.”
The players on instruments will be there, and the dancers will say, All my springs are in you.

< Psalms 87 >