< Psalms 86 >
1 Àdúrà ti Dafidi. Gbọ́, Olúwa, kí o sì dá mi lóhùn, nítorí mo jẹ́ tálákà àti aláìní.
A prayer of David. Incline your ear, Lord, and answer me, for I am afflicted and needy.
2 Dáàbò bò ayé mi, nítorí a ti yà mí sọ́tọ̀ fún ọ: ìwọ ni Ọlọ́run mi, gbà ìránṣẹ́ rẹ là tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ.
Guard me, for I am loyal: save your servant, who trusts in you.
3 Ṣàánú fún mi, Olúwa, nítorí èmi ń pè ọ́ ní gbogbo ọjọ́.
Lord, be gracious to me, for you are my God; I cry to you all the day.
4 Mú ayọ̀ wà fún ìránṣẹ́ rẹ, nítorí ìwọ, Olúwa, ni mo gbé ọkàn mí sókè sí.
Gladden the heart of your servant; for to you, Lord, I set my hope.
5 Ìwọ ń dáríjì, ìwọ sì dára, Olúwa, ìwọ sì ṣàánú fún gbogbo àwọn tí ń ké pè ọ́.
For you, Lord, are good and forgiving, rich in love towards all who call on you.
6 Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa; tẹ́tí sí ẹkún mi fún àánú.
Listen, O Lord, to my prayer; attend to my plea for mercy.
7 Ní ọjọ́ ìpọ́njú mi èmi yóò pè ọ́, nítorí ìwọ yóò dá mi lóhùn.
In the day of my trouble I call on you, with assurance that you will answer me.
8 Nínú àwọn òrìṣà kò sí ẹni tí ó dàbí i rẹ, Olúwa: kò sí àwọn iṣẹ́ tí a lè fiwé tìrẹ.
None of the gods is like you, Lord, nor are any works like yours.
9 Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ dá yóò wá láti wá jọ́sìn níwájú rẹ, Olúwa; wọn ó mú ògo wà fún orúkọ rẹ̀.
All the nations you have made will come and bow down before you, giving glory, O Lord, to your name.
10 Nítorí pé ìwọ tóbi, ìwọ sì ń ṣe ohun ìyanu; ìwọ nìkan ni Ọlọ́run.
For great are you, and a doer of wonders; you alone are God.
11 Kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, Olúwa, èmi ó sì máa rìn nínú òtítọ́ rẹ; fún mi ní ọkàn tí kì í yapa, kí èmi kí ó ba lè bẹ̀rù orúkọ rẹ.
Teach me, O Lord, your way, that I may walk in your truth: so my heart shall rejoice in your name.
12 Èmi ó yìn ọ́, Olúwa Ọlọ́run mi, pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi; èmi ó fògo fún orúkọ rẹ títí láé.
I will give you thanks, O Lord, with all my heart, my God, I will honor your name forever.
13 Nítorí títóbi ni ìfẹ́ rẹ si mi; ìwọ ti gbà mí kúrò nínú ọ̀gbun isà òkú. (Sheol )
For great is your love towards me, from the depths of Sheol you have saved me. (Sheol )
14 Àwọn onígbèéraga ń dojúkọ mí, Ọlọ́run; àti ìjọ àwọn alágbára ń wá ọkàn mi kiri, wọn kò sì fi ọ́ pè.
Haughty men have risen up against me, O God, a band of the violent seeking my life, who think nothing of you.
15 Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, jẹ́ aláàánú àti Ọlọ́run olójúrere, Ó lọ́ra láti bínú, Ó sì pọ̀ ní ìfẹ́ àti òtítọ́.
But you are a God of pity and grace, patient and rich in kindness and faithfulness; turn to me with your grace, O Lord.
16 Yípadà sí mi kí o sì ṣàánú fún mi; fún àwọn ènìyàn rẹ ní agbára kí o sì gba ọ̀dọ́mọkùnrin ìránṣẹ́bìnrin rẹ là.
Grant your strength to your servant, and save the child of your handmaid.
17 Fi àmì hàn mí fún rere, kí àwọn tí ó kórìíra mi lè ri, kí ojú lè tì wọ́n, nítorí ìwọ Olúwa ni ó ti tù mí nínú.
Show me a sign of your favor, which those who hate me may see with confusion, since you, Lord, are my helper and comforter.