< Psalms 85 >

1 Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu. Ìwọ fi ojúrere hàn fún ilé rẹ, Olúwa; ìwọ mú ohun ìní Jakọbu bọ̀ sí ipò.
For the choirmaster. A Psalm of the sons of Korah. You showed favor to Your land, O LORD; You restored Jacob from captivity.
2 Ìwọ dárí àìṣedéédéé àwọn ènìyàn rẹ jì ìwọ sì bó ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀. (Sela)
You forgave the iniquity of Your people; You covered all their sin.
3 Ìwọ fi àwọn ìbínú rẹ sápá kan ìwọ sì yípadà kúrò nínú ìbínú gbígbóná rẹ.
You withheld all Your fury; You turned from Your burning anger.
4 Yí wa padà, Ọlọ́run ìgbàlà wa, kí o sì yí ìbínú rẹ̀ padà kúrò lọ́dọ̀ wa.
Restore us, O God of our salvation, and put away Your displeasure toward us.
5 Ìwọ yóò ha máa bínú sí wa títí láé? Ìwọ yóò ha mú ìbínú rẹ pẹ́ yí gbogbo ìran ká?
Will You be angry with us forever? Will You draw out Your anger to all generations?
6 Ìwọ kì yóò ha sọ wá jí padà mọ́, pé kí àwọn ènìyàn rẹ lè yọ nínú rẹ?
Will You not revive us again, that Your people may rejoice in You?
7 Fi ìfẹ́ rẹ tí kò le è kùnà hàn wá, Olúwa, kí o sì fún wa ní ìgbàlà rẹ.
Show us Your loving devotion, O LORD, and grant us Your salvation.
8 Èmi ó gbọ́ ohun tí Olúwa Ọlọ́run yóò wí; ó ṣèlérí àlàáfíà fún àwọn ènìyàn rẹ̀, àní ẹni mímọ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí wọn padà sí àìmoye.
I will listen to what God the LORD will say; for He will surely speak peace to His people and His saints; He will not let them return to folly.
9 Nítòótọ́ ìgbàlà rẹ̀ súnmọ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, pé kí ògo rẹ̀ kí ó lè gbé ní ilẹ̀ wa.
Surely His salvation is near to those who fear Him, that His glory may dwell in our land.
10 Ìfẹ́ àti òtítọ́ parapọ̀; òdodo àti àlàáfíà fẹnu ko ara wọn.
Loving devotion and faithfulness have joined together; righteousness and peace have kissed.
11 Òtítọ́ ń sun jáde láti ilẹ̀ wá òdodo sì bojú wolẹ̀ láti ọ̀run.
Faithfulness sprouts from the earth, and righteousness looks down from heaven.
12 Olúwa yóò fi ohun dídára fún ni nítòótọ́, ilẹ̀ wa yóò sì mú ìkórè rẹ̀ jáde.
The LORD will indeed provide what is good, and our land will yield its increase.
13 Òdodo síwájú rẹ lọ o sì pèsè ọ̀nà fún ìgbésẹ̀ rẹ̀.
Righteousness will go before Him to prepare the way for His steps.

< Psalms 85 >