< Psalms 81 >
1 Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti gittiti. Ti Asafu. Kọrin sókè sí Ọlọ́run agbára wa ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọ́run Jakọbu!
For the leader. On the gittith. Of Asaph. Sing aloud to God our strength, shout for joy to the God of Jacob.
2 Ẹ mú orin mímọ́, kí ẹ sì mú ìlù wá, tẹ dùùrù dídùn pẹ̀lú ohun èlò orin mímọ́.
Raise a song, sound the timbrel, sweet lyre and harp.
3 Ẹ fún ìpè ní oṣù tuntun àní nígbà tí a yàn; ní ọjọ́ àjọ wa tí ó ní ìrònú.
On the new moon blow the horn, at the full moon, the day of our festival.
4 Èyí ni àṣẹ fún Israẹli, àti òfin Ọlọ́run Jakọbu.
For this is a statute for Israel, a ruling of the God of Jacob,
5 Ó fi múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà fún Josẹfu nígbà tí ó la ilẹ̀ Ejibiti já. Níbi tí a ti gbọ́ èdè tí kò yé wa.
a witness he set up in Joseph, when he marched against Egypt’s land, where he heard an unknown voice say:
6 Ó wí pé, “Mo gbé àjàgà kúrò ní èjìká yín, a tú ọwọ́ wọn sílẹ̀ kúrò nínú apẹ̀rẹ̀.
‘I removed from your shoulder the burden, and freed your hands from the basket.
7 Nínú ìnilára ni ẹ pè mo sì gbà yín là, mo dá a yín lóhùn nínú ìkọ̀kọ̀ àrá, mo dán an yín wò ní odò Meriba. (Sela)
At your call of distress I delivered you, from the thundercloud I answered you. At Meribah’s waters I tested you. (Selah)
8 “Gbọ́, ẹ̀yin ènìyàn mi, èmi ó sì kìlọ̀ fún un yín, bí ìwọ bá fetí sí mi, ìwọ Israẹli.
‘Listen, my people, to my warning, O Israel, if you would but listen!
9 Ẹ̀yin kì yóò ní Ọlọ́run ilẹ̀ mìíràn láàrín yín; ẹ̀yin kì yóò foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run àjèjì.
There must not be a strange god among you, you must bow to no foreign god.
10 Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ, ẹni tí ó mú un yín jáde láti Ejibiti. Ẹ la ẹnu yín gbòòrò, èmi yóò sì kún un.
I am the Lord your God who brought you up out of Egypt. Open your mouth, that I fill it.
11 “Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi kì yóò gbọ́ tèmi; Israẹli kò ní tẹríba fún mi.
‘But my people did not listen to my voice, Israel would have none of me.
12 Nítorí náà ni mo ṣe fi wọ́n fún ọkàn líle wọn láti máa rìn ní ọ̀nà ẹ̀tàn wọn.
So to their own hard hearts I left them, to follow their own devices.
13 “Bí àwọn ènìyàn mi yóò bá gbọ́ tèmi bí Israẹli yóò bá tẹ̀lé ọ̀nà mi,
O that my people would listen, that Israel would walk in my ways.
14 ní kánkán ni èmi yóò ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn kí n sì yí ọwọ́ mi padà sí ọ̀tá wọn!
Soon would I humble their enemies, and turn my hand on their foes.
15 Àwọn tí ó kórìíra Olúwa yóò tẹríba níwájú rẹ̀. Ìjìyà wọn yóò sì pẹ́ títí láé.
Those who hate the Lord would cringe before him in everlasting terror.
16 Ṣùgbọ́n a ó fi ọkà tí ó dára bọ́ ọ yín èmi ó tẹ́ ẹ yín lọ́rùn pẹ̀lú oyin inú àpáta.”
But you would I feed with the richest wheat, and with honey from the rock to your heart’s desire.’