< Psalms 80 >
1 Fún adarí orin. Tí ohùn “Lílì Ti Májẹ̀mú.” Ti Safu. Saamu. Gbọ́ tiwa, ìwọ olùṣọ́-àgùntàn Israẹli; ìwọ tí ó darí Josẹfu bí ọ̀wọ́ ẹran. Ìwọ tí o jókòó lórí ìtẹ́ láàrín Kérúbù, tàn jáde
For the leader. On shoshannim, eduth. Of Asaph, a psalm. Listen, Shepherd of Israel, who leads Joseph like a flock of sheep; from your throne on the cherubs shine forth
2 níwájú Efraimu, Benjamini àti Manase. Ru agbára rẹ̀ sókè; wá fún ìgbàlà wa.
before Ephraim, Manasseh, and Benjamin. Stir up your mighty power, come to our help.
3 Mú wa padà bọ̀ sípò, ìwọ Ọlọ́run; jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí wa, kí a bá à lè gbà wá là.
God, restore us: show us the light of your face, so we may be saved.
4 Olúwa Ọlọ́run alágbára, ìbínú rẹ̀ yóò ti pẹ́ tó sí àdúrà àwọn ènìyàn rẹ?
O Lord of hosts, how long is your anger to smoke, despite the prayer of your people?
5 Ìwọ ti fi oúnjẹ bọ́ wọn ìwọ ti mú wọn wa ẹkún mu ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.
You have fed them with bread of tears, you have made them drink tears by the measure.
6 Ìwọ sọ wá di ẹlẹ́yà fún àwọn aládùúgbò wa, àwọn ọ̀tá wa sì ń yọ̀ wá.
The scorn of our neighbours you make us, the laughing-stock of our foes.
7 Tún wa yípadà, ìwọ, Ọlọ́run alágbára; jẹ́ kí ojú rẹ tàn sí wa, kí a ba à lè gbà wá là.
God of hosts, restore us: show us the light of your face, so we may be saved.
8 Ìwọ mú àjàrà jáde láti Ejibiti; ìwọ lé àwọn kèfèrí jáde, o sì gbìn ín.
A vine out of Egypt you brought; you did drive out the nations, and plant her;
9 Ìwọ ṣí ààyè sílẹ̀ fún un, ìwọ sì mu ta gbòǹgbò jinlẹ̀ ó sì kún ilẹ̀ náà.
in the ground you did clear she struck root, and she filled all the land.
10 A bò àwọn òkè mọ́lẹ̀ òkè pẹ̀lú òjìji rẹ̀, ẹ̀ka rẹ̀ dàbí kedari Ọlọ́run.
The shade of her covered the mountains, her branches the cedars of God.
11 O yọ ẹ̀ka rẹ̀ sínú Òkun, ọwọ́ rẹ̀ sí odò ńlá nì.
She sent forth her shoots to the sea, and her branches as far as the River.
12 Èéṣe tí ìwọ fi wó odi rẹ̀ tí àwọn ènìyàn tí ó ń kọjá fi ń ṣa èso rẹ̀?
Why have you torn down her fences, and left her to be plucked at by all who pass by,
13 Ìmàdò láti inú igbó ń bá a jẹ́ àti ẹranko igbó ń jẹ ẹ́ run.
to be gnawed by the boar from the forest, and devoured by the beasts of the field?
14 Yípadà sí wa, àwa ń bẹ̀ ọ́, Ọlọ́run alágbára! Bojú wolẹ̀ láti ọ̀run kí o sì wò ó! Kí o sì bẹ àjàrà yìí wò,
O God of hosts, return: look down from heaven and see and visit this vine, and restore her
15 gbòǹgbò èyí tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ti gbìn, àti ẹ̀ka tí ìwọ ti mú lágbára fún ara rẹ.
the vine which your right hand has planted.
16 A gé àjàrà rẹ lulẹ̀, a ti fi iná sun ún; ní ìfibú, àwọn ènìyàn rẹ̀ ń ṣègbé.
She is burned with fire and cut down before your stern face they are perishing.
17 Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó wà lára ọkùnrin tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ, ọmọ ènìyàn tí ìwọ tí gbé kalẹ̀ fún ara rẹ.
Support the one you have chosen, the one you have raised for yourself;
18 Nígbà náà àwa kí yóò yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ; mú wa yè, àwa o sì máa pe orúkọ rẹ.
then from you we will never draw back. Preserve us, and we will call on your name.
19 Tún wa yípadà, Olúwa Ọlọ́run alágbára; kí ojú rẹ̀ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí wa, kí á ba à lè gbà wá là.
Lord, God of hosts, restore us: Show us the light of your face, so we may be saved.