< Psalms 8 >

1 Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti gittiti. Saamu ti Dafidi. Olúwa, Olúwa wa, orúkọ rẹ̀ ti ní ìyìn tó ní gbogbo ayé! Ìwọ ti gbé ògo rẹ ga ju àwọn ọ̀run lọ.
For the leader: A psalm of David, to be accompanied by a stringed instrument. Lord our God! How glorious in all the earth is your name! Your praise reaches as high as the heavens,
2 Láti ẹnu ọmọ ọwọ́ àti ọmọ ọmú ni o ti yan ìyìn nítorí àwọn ọ̀tá rẹ, láti pa àwọn ọ̀tá àti àwọn olùgbẹ̀san lẹ́nu mọ́.
from the mouths of children and infants. You have built a fortress against your enemies, to silence the foe and the rebel.
3 Nígbà tí mo ro ọ̀run rẹ, iṣẹ́ ìka rẹ, òṣùpá àti ìràwọ̀, tí ìwọ tí gbé kalẹ̀,
When I look at your heavens, the work of your fingers, the moon and the stars, which you have set there,
4 kí ni ènìyàn tí ìwọ ń rò nípa rẹ̀, àní ọmọ ènìyàn tí ìwọ ń ṣe ìtọ́jú rẹ̀?
what are mortals, that you think of them, humans, that you visit them?
5 Ìwọ ṣe é ní onírẹ̀lẹ̀ díẹ̀ ju Ọlọ́run lọ, ìwọ sì dé e ní adé ògo àti ọlá.
Yet you made them little less than divine, crowned them with glory and majesty,
6 Ìwọ mú un jẹ ọba lórí gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ; ìwọ sì fi ohun gbogbo sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀:
made them lord of the works of your hands, put all things under their feet –
7 àwọn agbo àgùntàn àti àwọn màlúù, àti ẹranko igbó,
sheep and oxen, all of them; and the wild beasts also:
8 ẹyẹ ojú ọrun, àti ẹja inú Òkun, àti ohun tí ń wẹ nínú ipa Òkun.
birds of the air, and fish of the sea, and all that crosses the paths of the ocean.
9 Olúwa, Olúwa wa, orúkọ rẹ ti ní ìyìn tó ní gbogbo ayé!
Lord our God! How glorious in all the earth is your name!

< Psalms 8 >