< Psalms 79 >

1 Saamu ti Asafu. Ọlọ́run, àwọn orílẹ̀-èdè ti wá ilẹ̀ ìní rẹ; wọ́n ti ba tẹmpili mímọ́ rẹ jẹ́, wọn di Jerusalẹmu kù sí òkìtì àlàpà.
A Psalm of Asaph. The nations, O God, have invaded Your inheritance; they have defiled Your holy temple and reduced Jerusalem to rubble.
2 Wọn ti fi ara òkú àwọn ìránṣẹ́ rẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ní oúnjẹ, ẹran-ara àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ fún ẹranko ilẹ̀.
They have given the corpses of Your servants as food to the birds of the air, the flesh of Your saints to the beasts of the earth.
3 Wọ́n tu ẹ̀jẹ̀ jáde gẹ́gẹ́ bí omi yí Jerusalẹmu ká, kò sì ṣí àwọn tí yóò sìn wọ́n.
They have poured out their blood like water all around Jerusalem, and there is no one to bury the dead.
4 Àwa di ohun ẹ̀gàn sí àwọn tí ó yí wa ká, àbùkù àti ìfiṣe ẹlẹ́yà sí àwọn tí ó yí wa ká.
We have become a reproach to our neighbors, a scorn and derision to those around us.
5 Nígbà wo, Olúwa? Ní ìwọ ó máa bínú títí láé? Yóò ti pẹ́ tó ti owú rẹ yóò ha jò bí iná?
How long, O LORD? Will You be angry forever? Will Your jealousy burn like fire?
6 Tú ìbínú rẹ jáde sí orílẹ̀-èdè tí kò ní ìmọ̀ rẹ, lórí àwọn ìjọba tí kò pe orúkọ rẹ;
Pour out Your wrath on the nations that do not acknowledge You, on the kingdoms that refuse to call on Your name,
7 nítorí wọ́n ti run Jakọbu wọ́n sì sọ ibùgbé rẹ di ahoro.
for they have devoured Jacob and devastated his homeland.
8 Má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wa sí wa lọ́rùn jẹ́ kí àánú rẹ wá kánkán láti bá wa, nítorí tí a rẹ̀ wá sílẹ̀ gidigidi.
Do not hold past sins against us; let Your compassion come quickly, for we are brought low.
9 Ràn wá lọ́wọ́, Ọlọ́run Olùgbàlà wa, fún ògo orúkọ rẹ; gbà wá kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì nítorí orúkọ rẹ.
Help us, O God of our salvation, for the glory of Your name; deliver us and atone for our sins, for the sake of Your name.
10 Àwọn orílẹ̀-èdè yóò máa wí pé, “Níbo ni Ọlọ́run wọn wà?” Ní ojú wa, kí a mọ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè kí ó sì gbẹ̀san àwọn ẹ̀jẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ tí a tú jáde.
Why should the nations ask, “Where is their God?” Before our eyes, make known among the nations Your vengeance for the bloodshed of Your servants.
11 Jẹ́ kí ìmí ẹ̀dùn oǹdè náà wá síwájú rẹ, gẹ́gẹ́ bí títóbi agbára rẹ ìwọ ṣe ìtọ́jú àwọn ti a dá lẹ́bi ikú.
May the groans of the captives reach You; by the strength of Your arm preserve those condemned to death.
12 San án padà sí àyà àwọn aládùúgbò wa nígbà méje nípa ẹ̀gàn tí wọn ti gàn ọ́ Olúwa.
Pay back into the laps of our neighbors sevenfold the reproach they hurled at You, O Lord.
13 Nígbà náà àwa ènìyàn rẹ, àti àgùntàn pápá rẹ, yóò fi ọpẹ́ fún ọ títí láé; láti ìran dé ìran ni àwa ó fi ìyìn rẹ hàn.
Then we Your people, the sheep of Your pasture, will thank You forever; from generation to generation we will declare Your praise.

< Psalms 79 >