< Psalms 78 >
1 Maskili ti Asafu. Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ gbọ́ ẹ̀kọ́ mi; tẹ́tí rẹ sí ọ̀rọ̀ ẹnu mi.
intellectus Asaph adtendite populus meus legem meam inclinate aurem vestram in verba oris mei
2 Èmi ó la ẹnu mi ní òwe, èmi o sọ ohun ìkọ̀kọ̀, ohun ti ọjọ́ pípẹ́;
aperiam in parabola os meum eloquar propositiones ab initio
3 ohun tí a ti gbọ́ tí a sì ti mọ̀, ohun tí àwọn baba wa ti sọ fún wa.
quanta audivimus et cognovimus ea et patres nostri narraverunt nobis
4 Àwa kì yóò pa wọ́n mọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ, ní fífi ìyìn Olúwa, àti ipa rẹ̀ àti iṣẹ́ ìyanu tó ti ṣe hàn fún ìran tí ń bọ̀.
non sunt occultata a filiis eorum in generationem alteram narrantes laudes Domini et virtutes eius et mirabilia eius quae fecit
5 Ó gbé ẹ̀rí kalẹ̀ ní Jakọbu o sì fìdí àṣẹ múlẹ̀ ní Israẹli, èyí tí ó pàṣẹ fún àwọn baba ńlá wa láti kọ́ àwọn ọmọ wọn,
et suscitavit testimonium in Iacob et legem posuit in Israhel quanta mandavit patribus nostris nota facere ea filiis suis
6 nítorí náà, àwọn ìran tí ń bọ̀ yóò mọ̀ wọ́n bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ tí a kò tí ì bí tí yóò dìde tí wọn yóò sọ fún àwọn ọmọ wọn.
ut cognoscat generatio altera filii qui nascentur et exsurgent et narrabunt filiis suis
7 Nígbà náà ni wọ́n ò fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sínú Ọlọ́run wọn kò sì ní gbàgbé iṣẹ́ Ọlọ́run ṣùgbọ́n wọn ó pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.
ut ponant in Deo spem suam et non obliviscantur opera Dei et mandata eius exquirant
8 Kí wọn kí ó má ṣe dàbí àwọn baba ńlá wọn, ìran alágídí àti ọlọ́tẹ̀, ìran tí ọkàn wọn kò ṣọ òtítọ́ si olóore, àti ẹ̀mí ẹni tí kò bá Ọlọ́run dúró ṣinṣin.
ne fiant sicut patres eorum generatio prava et exasperans generatio quae non direxit cor suum et non est creditus cum Deo spiritus eius
9 Àwọn ọkùnrin Efraimu, tí ó há mọ́ ọ tí wọ́n mú ọrun, wọ́n yípadà ní ọjọ́ ogun
filii Effrem intendentes et mittentes arcus conversi sunt in die belli
10 Wọn kò pa májẹ̀mú Ọlọ́run mọ́ wọn sì kọ̀ láti máa gbé nínú òfin rẹ̀.
non custodierunt testamentum Dei et in lege eius noluerunt ambulare
11 Wọ́n gbàgbé ohun tí ó ti ṣe, àwọn ìyanu tí ó ti fihàn wọ́n.
et obliti sunt benefactorum eius et mirabilium eius quae ostendit eis
12 Ó ṣe ìyanu níwájú àwọn baba wọn ní ilẹ̀ Ejibiti, ní agbègbè Ṣoani.
coram patribus eorum quae fecit mirabilia in terra Aegypti in campo Taneos
13 Ó pín òkun ní yà, ó sì mú wọn kọjá Ó mù kí omi náà dúró bi odi gíga.
interrupit mare et perduxit eos statuit aquas quasi utrem
14 Ní ọ̀sán, ó fi ìkùùkuu àwọsánmọ̀ ṣe amọ̀nà wọn àti ní gbogbo òru pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ iná.
et deduxit eos in nube diei et tota nocte in inluminatione ignis
15 Ó sán àpáta ní aginjù ó sì fún wọn ní omi mímu lọ́pọ̀lọ́pọ̀ bí ẹni pé láti inú ibú wá.
interrupit petram in heremo et adaquavit eos velut in abysso multa
16 Ó mú ìṣàn omi jáde láti inú àpáta omi ṣíṣàn sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí odò.
et eduxit aquam de petra et deduxit tamquam flumina aquas
17 Wọ́n sì tún tẹ̀síwájú láti dẹ́ṣẹ̀ sí i ní ìṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá-ògo ní aginjù.
et adposuerunt adhuc peccare ei in ira excitaverunt Excelsum in inaquoso
18 Wọ́n mọ̀ ọ́n mọ̀ dán Ọlọ́run wò nípa bíbéèrè fún oúnjẹ tí wọn bẹ̀bẹ̀ fún.
et temptaverunt Deum in cordibus suis ut peterent escas animabus suis
19 Wọ́n sọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run, wí pé “Ọlọ́run ha lè tẹ́ tábìlì ní aginjù?
et male locuti sunt de Deo dixerunt numquid poterit Deus parare mensam in deserto
20 Nígbà tí ó lu àpáta, omi tú jáde, odò sì sàn lọ́pọ̀lọ́pọ̀ ṣùgbọ́n òun ha lè fún wa lóúnjẹ ó ha le pèsè ẹran fún àwọn ènìyàn rẹ̀?”
quoniam percussit petram et fluxerunt aquae et torrentes inundaverunt numquid et panem potest dare aut parare mensam populo suo
21 Nígbà tí Olúwa gbọ́ wọn, ó bínú gidigidi; iná rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ sí Jakọbu, ìbínú rẹ̀ sì rú sí Israẹli,
ideo audivit Dominus et distulit et ignis accensus est in Iacob et ira ascendit in Israhel
22 nítorí wọn kò gba Ọlọ́run gbọ́, wọn kò sì gbẹ́kẹ̀lé ìgbàlà rẹ̀.
quia non crediderunt in Deo nec speraverunt in salutare eius
23 Síbẹ̀ ó pàṣẹ fún ìràwọ̀ ojú ọ̀run, ó sì ṣí ìlẹ̀kùn ọ̀run sílẹ̀;
et mandavit nubibus desuper et ianuas caeli aperuit
24 Ó rọ manna fún àwọn ènìyàn láti jẹ, ó fún wọn ní ọkà láti ọ̀run.
et pluit illis manna ad manducandum et panem caeli dedit eis
25 Àwọn ènìyàn jẹ oúnjẹ àwọn angẹli; Ó fún wọn ní oúnjẹ ní àjẹyó,
panem angelorum manducavit homo cibaria misit eis in abundantiam
26 Ó mú afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn láti ọ̀run wá ó mú afẹ́fẹ́ gúúsù wá nípa agbára rẹ̀.
transtulit austrum de caelo et induxit in virtute sua africum
27 Ó rọ òjò ẹran sílẹ̀ sórí wọn bí erùpẹ̀ ilẹ̀, àti ẹyẹ abìyẹ́ gẹ́gẹ́ bí iyanrìn etí òkun
et pluit super eos sicut pulverem carnes et sicut harenam maris volatilia pinnata
28 Ó jẹ́ kí wọn jáde ní ibùdó wọn, yíká àgọ́ wọn.
et ceciderunt in medio castrorum eorum circa tabernacula eorum
29 Wọ́n jẹ, wọ́n sì yó jọjọ nítorí ó ti fún wọn ní ohun tí wọn fìtara bẹ̀bẹ̀ fún.
et manducaverunt et saturati sunt nimis et desiderium eorum adtulit eis
30 Ṣùgbọ́n wọn kò kúrò nínú oúnjẹ tí wọn fìtara bẹ̀bẹ̀ fún, nígbà tí oúnjẹ wọn sì wà ní ẹnu wọn,
non sunt fraudati a desiderio suo adhuc escae eorum erant in ore ipsorum
31 ìbínú Ọlọ́run dìde sí wọn ó pa àwọn tí ó jùlọ nínú wọn, ó sì lu àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Israẹli bolẹ̀.
et ira Dei ascendit in eos et occidit pingues eorum et electos Israhel inpedivit
32 Nínú gbogbo ìwọ̀nyí, wọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ síwájú; nínú gbogbo iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, wọ́n kò gbàgbọ́.
in omnibus his peccaverunt adhuc et non crediderunt mirabilibus eius
33 O fi òpin sí ayé wọn nínú asán àti ọdún wọn nínú ìpayà.
et defecerunt in vanitate dies eorum et anni eorum cum festinatione
34 Nígbàkígbà tí Ọlọ́run bá pa wọ́n, wọn yóò wá a kiri; wọn yóò fi ìtara yípadà sí i.
cum occideret eos quaerebant eum et revertebantur et diluculo veniebant ad Deum
35 Wọ́n rántí pé Ọlọ́run ní àpáta wọn; wí pé Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo jùlọ ni olùràpadà àpáta wọn.
et rememorati sunt quia Deus adiutor est eorum et Deus excelsus redemptor eorum est
36 Ṣùgbọ́n nígbà náà ni wọ́n yóò pọ́n ọn pẹ̀lú ẹnu wọ́n wọ́n fi ahọ́n wọ́n purọ́ fún un;
et dilexerunt eum in ore suo et lingua sua mentiti sunt ei
37 ọkàn wọn kò sòtítọ́ sí i, wọn kò jẹ́ olódodo sí májẹ̀mú rẹ̀.
cor autem ipsorum non erat rectum cum eo nec fideles habiti sunt in testamento eius
38 Síbẹ̀ ó ṣàánú; ó dárí àìṣedéédéé wọn jì òun kò sì pa wọ́n run nígbà púpọ̀ ló ń yí ìbínú rẹ̀ padà kò sì ru ìbínú rẹ̀ sókè
ipse autem est misericors et propitius fiet peccatis eorum et non perdet eos et abundabit ut avertat iram suam et non accendet omnem iram suam
39 Ó rántí pé ẹlẹ́ran ara ni wọ́n, afẹ́fẹ́ tó ń kọjá tí kò lè padà.
et recordatus est quia caro sunt spiritus vadens et non rediens
40 Nígbà gbogbo ní wọn ń ṣọ̀tẹ̀ sí i ní aginjù wọn mú un bínú nínú ilẹ̀ tí ó di ahoro!
quotiens exacerbaverunt eum in deserto in ira concitaverunt eum in inaquoso
41 Síwájú àti síwájú wọ́n dán Ọlọ́run wò; wọ́n mú ẹni mímọ́ Israẹli bínú.
et conversi sunt et temptaverunt Deum et Sanctum Israhel exacerbaverunt
42 Wọ́n kò rántí agbára rẹ̀: ní ọjọ́ tí ó rà wọ́n padà lọ́wọ́ àwọn aninilára,
non sunt recordati manus eius die qua redemit eos de manu tribulantis
43 ní ọjọ́ tí ó fi iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ hàn ní Ejibiti, àti iṣẹ́ àmì rẹ̀ ni ẹkùn Ṣoani
sicut posuit in Aegypto signa sua et prodigia sua in campo Taneos
44 Ó sọ omi wọn di ẹ̀jẹ̀; wọn kò lè mu láti odò wọn.
et convertit in sanguine flumina eorum et imbres eorum ne biberent
45 Ó rán ọ̀wọ́ eṣinṣin láti pa wọ́n run, àti ọ̀pọ̀lọ́ tí ó bá wọn jẹun.
misit in eos cynomiam et comedit eos et ranam et disperdit eos
46 Ó fi ọkà wọn fún láńtata, àwọn ìre oko wọn fún eṣú.
et dedit erugini fructus eorum et labores eorum lucustae
47 Ó fi yìnyín ba àjàrà wọn jẹ́ ó bá èso sikamore wọn jẹ́.
et occidit in grandine vineam eorum et moros eorum in pruina
48 Ó fi ohun ọ̀sìn wọn fún yìnyín, agbo ẹran wọn fún mọ̀nàmọ́ná.
et tradidit grandini iumenta eorum et possessionem eorum igni
49 Ó mú kíkorò ìbínú rẹ̀ wá sí wọn lára, ìrunú àti ìkáàánú, àti ìpọ́njú, nípa rírán angẹli apanirun sí wọn.
misit in eos iram indignationis suae indignationem et iram et tribulationem inmissionem per angelos malos
50 Ó pèsè ipa fún ìbínú rẹ̀, òun kò gbà wọ́n lọ́wọ́ ikú, ṣùgbọ́n ó fi ẹ̀mí wọ́n fún àjàkálẹ̀-ààrùn.
viam fecit semitae irae suae non pepercit a morte animarum eorum et iumenta eorum in morte conclusit
51 Ó kọlu àwọn àkọ́bí ọmọ ọkùnrin Ejibiti, olórí agbára wọn nínú àgọ́ Hamu.
et percussit omne primitivum in terra Aegypti primitias laborum eorum in tabernaculis Cham
52 Ṣùgbọ́n ó mú àwọn ènìyàn rẹ̀ jáde bí ọ̀wọ́ ẹran; ó ṣọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí àgùntàn nínú aginjù.
et abstulit sicut oves populum suum et perduxit eos tamquam gregem in deserto
53 Ó dáàbò bò wọ́n dáradára, nítorí náà ni ẹ̀rù kò ṣe bà wọ́n ṣùgbọ́n òkun padé mọ́ àwọn ọ̀tá wọn.
et deduxit eos in spe et non timuerunt et inimicos eorum operuit mare
54 Bákan náà ni ó mú wọn wá sí etí ilẹ̀ mímọ́ rẹ̀ òkè tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ti gbà
et induxit eos in montem sanctificationis suae montem quem adquisivit dextera eius et eiecit a facie eorum gentes et sorte divisit eis terram in funiculo distributionis
55 Ó lé kèfèrí jáde níwájú wọn ó sì fi títa okùn pín ilẹ̀ náà fún wọn gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní; ó mú àwọn ẹ̀yà Israẹli jókòó ní ilẹ̀ wọn.
et habitare fecit in tabernaculis eorum tribus Israhel
56 Ṣùgbọ́n wọn dán Ọlọ́run wò wọn sì ṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá-ògo; wọn kò pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.
et temptaverunt et exacerbaverunt Deum excelsum et testimonia eius non custodierunt
57 Ṣùgbọ́n wọ́n yípadà, wọn jẹ́ aláìṣòdodo gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn wọ́n sì pẹ̀yìndà sí apákan bí ọrun ẹ̀tàn.
et averterunt se et non servaverunt pactum quemadmodum patres eorum conversi sunt in arcum pravum
58 Wọ́n bí i nínú pẹ̀lú ibi gíga wọn; wọn rú owú rẹ̀ sókè nípa òrìṣà wọn.
et in ira concitaverunt eum in collibus suis et in sculptilibus suis ad aemulationem eum provocaverunt
59 Nígbà tí Ọlọ́run gbọ́ wọn, inú bí i gidigidi; ó kọ Israẹli pátápátá.
audivit Deus et sprevit et ad nihilum redegit valde Israhel
60 Ó kọ àgọ́ Ṣilo sílẹ̀, àgọ́ tí ó ti gbé kalẹ̀ láàrín àwọn ènìyàn.
et reppulit tabernaculum Selo tabernaculum suum ubi habitavit in hominibus
61 Ó rán àpótí ẹ̀rí, agbára rẹ̀ lọ sí ìgbèkùn, dídán ògo rẹ̀ lọ sí ọwọ́ àwọn ọ̀tá.
et tradidit in captivitatem virtutem eorum et pulchritudinem eorum in manus inimici
62 Ó fi àwọn ènìyàn rẹ̀ lé idà lọ́wọ́, ó sì bínú sí àwọn ohun ìní rẹ̀.
et conclusit in gladio populum suum et hereditatem suam sprevit
63 Iná run àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọn, àwọn ọmọbìnrin wọn kò sì ní orin ìgbéyàwó:
iuvenes eorum comedit ignis et virgines eorum non sunt lamentatae
64 àfi àlùfáà wọn fún idà, àwọn opó wọn kò sì le è sọkún.
sacerdotes eorum in gladio ceciderunt et viduae eorum non plorabuntur
65 Olúwa sì jí gẹ́gẹ́ bí ẹni ojú oorun, gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin ti i jí kúrò nínú ìraníyè ọtí.
et excitatus est tamquam dormiens Dominus tamquam potens crapulatus a vino
66 Ó kọlu àwọn ọ̀tá rẹ̀ padà; ó fi wọn sínú ìtìjú ayérayé.
et percussit inimicos suos in posteriora obprobrium sempiternum dedit illis
67 Nígbà náà ni ó kọ́ àgọ́ Josẹfu, kò sì yan ẹ̀yà Efraimu,
et reppulit tabernaculum Ioseph et tribum Effrem non elegit
68 ṣùgbọ́n ó yan ẹ̀yà Juda, òkè Sioni, èyí tí ó fẹ́ràn.
et elegit tribum Iuda montem Sion quem dilexit
69 Ó kọ́ ibi mímọ́ rẹ̀, ibi gíga, gẹ́gẹ́ bí ayé tí ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ títí láé.
et aedificavit sicut unicornium sanctificium suum in terra quam fundavit in saecula
70 Ó yan Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀ ó mú láti inú àwọn agbo ẹran;
et elegit David servum suum et sustulit eum de gregibus ovium de post fetantes accepit eum
71 Ó mú un jáde nínú ìtọ́jú àgùntàn láti jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn àwọn ènìyàn rẹ̀ Jakọbu àti Israẹli ogún un rẹ̀.
pascere Iacob servum suum et Israhel hereditatem suam
72 Dafidi sì ṣọ́ wọn pẹ̀lú òtítọ́ inú ọkàn; pẹ̀lú ọwọ́ òye ni ó fi darí wọn.
et pavit eos in innocentia cordis sui et in intellectibus manuum suarum deduxit eos