< Psalms 76 >
1 Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Saamu ti Asafu. Orin. Ní Juda ni a mọ Ọlọ́run; orúkọ rẹ̀ sì lágbára ní Israẹli
阿撒夫的詩歌。交與樂官,樂用絃樂。 天主在猶大地顯示了自己,在以色列廣揚了自己的名。
2 Àgọ́ rẹ̀ wà ní Salẹmu, ibùgbé rẹ̀ ni Sioni.
他在撒冷支搭了自己的帳幕,他在熙雍建豎了自己的住處。
3 Níbẹ̀ ni ó ṣẹ́ ọfà, asà àti àwọn idà, ohun ìjà ogun. (Sela)
在那裏他打斷了弓上的火箭,他也打斷了槍柄、盾牌與刀劍。
4 Ìwọ ni ògo àti ọlá, ju òkè ńlá ìkógun wọ̀nyí lọ.
大能者,您大發光明,是來自遠古的山陵。
5 A kó àwọn alágídí ọkàn ní ìkógun wọ́n sun oorun ìgbẹ̀yìn wọn; kò sí ọ̀kan nínú àwọn akọni tó lè gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè.
膽大的人,全被剝奪,一睡不醒,那勇敢的將領,手臂麻木失靈。
6 Ní ìfibú rẹ, Ọlọ́run Jakọbu, àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ogun sì dùbúlẹ̀ síbẹ̀.
雅各伯的天主,因您的恐嚇,戰車戰馬都驚得麻木僵直。
7 Ìwọ nìkan ni ó yẹ kí a bẹ̀rù. Ta ló lé dúró níwájú rẹ, nígbà tí ìwọ bá ń bínú?
您尊嚴可畏;您盛怒時,何人能在您面前站立?
8 Ìwọ ń ṣe ìdájọ́ láti ọ̀run, ilé ayé bẹ̀rù, ó sì dúró jẹ́ẹ́,
您由天上宣佈判案,大地戰慄默默無言。
9 nígbà tí, ìwọ Ọlọ́run, bá dìde láti ṣe ìdájọ́, láti gba àwọn ẹni ìnilára ilẹ̀ náà. (Sela)
因為天主起來施行審判,是要救世上的一切貧賤。
10 Lóòótọ́, ìbínú rẹ sí àwọn ènìyàn ń mú ìyìn wá fún ọ, ẹni tí ó yọ nínú ìbínú rẹ ní a dá nígbà tí ìwọ bá fi ìbínú ìyókù di ara rẹ ni àmùrè.
人 的狂怒成全您的光榮,幸免憤怒的人,向您祝頌。
11 Jẹ́ ẹ̀jẹ́ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ kí o sì mú un ṣẹ; kí gbogbo àwọn tí ó yí i ká mú ẹ̀bùn wá fún ẹni tí ó tọ́ láti bẹ̀rù.
您們許願要向上主您們的天主還願;他四周的人都要向可敬者供奉祭獻。
12 Ó ké ẹ̀mí àwọn aládé kúrò; àwọn ọba ayé sì ń bẹ̀rù rẹ̀.
他抑壓首領們的氣燄,他使地上的眾王抖顫。