< Psalms 74 >

1 Maskili ti Asafu. Ọlọ́run, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ wá sílẹ̀ títí láé? Èéṣe tí ìbínú rẹ̀ fi dìde sí àwọn àgùntàn pápá rẹ?
משכיל לאסף למה אלהים זנחת לנצח יעשן אפך בצאן מרעיתך׃
2 Rántí àwọn ènìyàn tí ìwọ ti rà nígbà àtijọ́, ẹ̀yà ilẹ̀ ìní rẹ, tí ìwọ ti rà padà. Òkè Sioni, níbi tí ìwọ ń gbé.
זכר עדתך קנית קדם גאלת שבט נחלתך הר ציון זה שכנת בו׃
3 Yí ẹsẹ̀ rẹ padà sí ìparun ayérayé wọn, gbogbo ìparun yìí tí ọ̀tá ti mú wá sí ibi mímọ́.
הרימה פעמיך למשאות נצח כל הרע אויב בקדש׃
4 Àwọn ọ̀tá rẹ ń bú ramúramù láàrín ènìyàn rẹ, wọ́n ń gbé àsíá wọn sókè fún àmì.
שאגו צרריך בקרב מועדך שמו אותתם אתות׃
5 Wọ́n ń rí bí ọkùnrin tí ó gbé àáké rẹ̀ sókè láti gé igi igbó dídí.
יודע כמביא למעלה בסבך עץ קרדמות׃
6 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, iṣẹ́ ọnà fínfín, ni wọ́n fi àáké wó lulẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀kan náà.
ועת פתוחיה יחד בכשיל וכילפת יהלמון׃
7 Wọ́n sun ibi mímọ́ rẹ lulẹ̀ wọ́n ba ibùgbé orúkọ rẹ jẹ́.
שלחו באש מקדשך לארץ חללו משכן שמך׃
8 Wọ́n wí ní ọkàn wọn. “Àwa ó run wọ́n pátápátá!” Wọ́n sun gbogbo ibi ìjọ́sìn Ọlọ́run ní ilẹ̀ náà.
אמרו בלבם נינם יחד שרפו כל מועדי אל בארץ׃
9 A kò fún wa ní àmì iṣẹ́ ìyanu kankan; kò sí wòlíì kankan ẹnìkankan wa kò mọ ìgbà tí eléyìí yóò dà.
אותתינו לא ראינו אין עוד נביא ולא אתנו ידע עד מה׃
10 Àwọn ọ̀tá yóò ti kùn sí ọ pẹ́ tó, Ọlọ́run? Àwọn ọ̀tá yóò ha ba orúkọ rẹ jẹ́ títí láé?
עד מתי אלהים יחרף צר ינאץ אויב שמך לנצח׃
11 Èéṣe tí ìwọ fi dá ọwọ́ rẹ dúró, ọwọ́ ọ̀tún rẹ? Mú un kúrò nínú ìṣẹ́po aṣọ rẹ kí o sì run wọ́n!
למה תשיב ידך וימינך מקרב חוקך כלה׃
12 Ṣùgbọ́n ìwọ Ọlọ́run ni ọba mi láti ìgbà pípẹ́; Ó mú ìgbàlà wá sórí ilẹ̀ ayé.
ואלהים מלכי מקדם פעל ישועות בקרב הארץ׃
13 Ìwọ ni ó la òkun sílẹ̀ nípa agbára rẹ; ìwọ fọ́ orí ẹ̀mí búburú nínú omi.
אתה פוררת בעזך ים שברת ראשי תנינים על המים׃
14 Ìwọ fọ́ orí Lefitani túútúú, o sì fi ṣe oúnjẹ fun àwọn ẹ̀dá tí ń gbé inú ijù tìrẹ ni ọ̀sán, tìrẹ sì ni alẹ́ pẹ̀lú; ìwọ fi ìdí oòrùn àti òṣùpá lélẹ̀.
אתה רצצת ראשי לויתן תתננו מאכל לעם לציים׃
15 Ìwọ ya orísun omi àti ìṣàn omi; Ìwọ mú kí odò tó ń sàn gbẹ.
אתה בקעת מעין ונחל אתה הובשת נהרות איתן׃
16 Tìrẹ ni ọ̀sán, tìrẹ ni òru pẹ̀lú; ìwọ yà oòrùn àti òṣùpá.
לך יום אף לך לילה אתה הכינות מאור ושמש׃
17 Ìwọ pààlà etí ayé; Ìwọ dá ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti ìgbà òtútù.
אתה הצבת כל גבולות ארץ קיץ וחרף אתה יצרתם׃
18 Rántí bí àwọn ọ̀tá ń kẹ́gàn rẹ, Olúwa bí àwọn aṣiwèrè ènìyàn ti ń ba orúkọ rẹ jẹ́.
זכר זאת אויב חרף יהוה ועם נבל נאצו שמך׃
19 Má ṣe fi ẹ̀mí àdàbà rẹ fún ẹranko igbó búburú; má ṣe gbàgbé ẹ̀mí àwọn ènìyàn rẹ tí a ń pọ́n lójú títí láé.
אל תתן לחית נפש תורך חית ענייך אל תשכח לנצח׃
20 Bojú wo májẹ̀mú rẹ, nítorí ibi òkùnkùn ayé kún fún ibùgbé ìkà.
הבט לברית כי מלאו מחשכי ארץ נאות חמס׃
21 Má ṣe jẹ́ kí àwọn aninilára padà sẹ́yìn nínú ìtìjú jẹ́ kí àwọn aláìní àti tálákà yin orúkọ rẹ.
אל ישב דך נכלם עני ואביון יהללו שמך׃
22 Dìde, Ọlọ́run, gba ẹjọ́ ara rẹ rò; rántí bí àwọn aṣiwèrè ti ń kẹ́gàn rẹ ní gbogbo ọjọ́.
קומה אלהים ריבה ריבך זכר חרפתך מני נבל כל היום׃
23 Má ṣe gbàgbé ohùn àwọn ọ̀tá rẹ, bíbú àwọn ọ̀tá rẹ, tí ó ń pọ̀ sí i nígbà gbogbo.
אל תשכח קול צרריך שאון קמיך עלה תמיד׃

< Psalms 74 >