< Psalms 72 >
1 Ti Solomoni. Fi ìdájọ́ fún àwọn ọba, Ọlọ́run, ọmọ-aládé ni ìwọ fi òdodo rẹ fún.
BY SOLOMON. O God, give Your judgments to the king, And Your righteousness to the king’s Son.
2 Yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú òdodo, yóò sì máa fi ẹ̀tọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn tálákà rẹ̀.
He judges Your people with righteousness, And Your poor with judgment.
3 Àwọn òkè ńlá yóò máa mú àlàáfíà fún àwọn ènìyàn àti òkè kéékèèké nípa òdodo.
The mountains bear peace to the people, And the heights by righteousness.
4 Yóò dáàbò bo àwọn tí a pọ́n lójú láàrín àwọn ènìyàn yóò gba àwọn ọmọ aláìní; yóò sì fa àwọn aninilára ya.
He judges the poor of the people, Gives deliverance to the sons of the needy, And bruises the oppressor.
5 Àwọn òtòṣì àti aláìní yóò máa fi ọ̀wọ̀ ńlá fún ọ nígbà gbogbo, níwọ̀n ìgbà tí oòrùn àti òṣùpá bá ń ràn, yóò ti pẹ́ tó, láti ìrandíran.
They fear You with the sun, and before the moon, Generation—generations.
6 Yóò dàbí òjò tí ó ń rọ̀ sórí pápá ìrẹ́mọ́lẹ̀, bí ọwọ́ òjò tó ń rin ilẹ̀.
He comes down as rain on mown grass, As showers—sprinkling the earth.
7 Àwọn olódodo yóò gbilẹ̀ ni ọjọ́ rẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà yóò sì wà; títí tí òṣùpá kò fi ní sí mọ́.
The righteous flourish in His days, And abundance of peace until the moon is not.
8 Yóò máa jẹ ọba láti òkun dé òkun àti láti odò Eufurate títí dé òpin ayé.
And He rules from sea to sea, And from the river to the ends of the earth.
9 Àwọn tí ó wà ní aginjù yóò tẹríba fún un àwọn ọ̀tá rẹ̀ yóò máa lá erùpẹ̀ ilẹ̀.
Desert-dwellers bow before Him, And His enemies lick the dust.
10 Àwọn ọba Tarṣiṣi àti ti erékùṣù wọn yóò mú ọrẹ wá fún un; àwọn ọba Ṣeba àti Seba wọn ó mú ẹ̀bùn wá fún un.
Kings of Tarshish and of the islands send back a present. Kings of Sheba and Seba bring a reward near.
11 Gbogbo ọba yóò tẹríba fún un àti gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sìn ín.
And all kings bow themselves to Him, All nations serve Him,
12 Nítorí yóò gba àwọn aláìní nígbà tí ó bá ń ké, tálákà àti ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́.
For He delivers the needy who cries, And the poor when he has no helper,
13 Yóò káàánú àwọn aláìlera àti aláìní yóò pa aláìní mọ́ kúrò nínú ikú.
He has pity on the poor and needy, And He saves the souls of the needy,
14 Yóò ra ọkàn wọn padà lọ́wọ́ ẹ̀tàn àti ipá nítorí ẹ̀jẹ̀ wọn ṣọ̀wọ́n níwájú rẹ̀.
He redeems their soul from fraud and from violence, And their blood is precious in His eyes.
15 Yóò sì pẹ́ ní ayé! A ó sì fún un ní wúrà Ṣeba. Àwọn ènìyàn yóò sì máa gbàdúrà fún un nígbà gbogbo kí a sì bùkún fún un lójoojúmọ́.
And He lives, and the gold of Sheba [is] given to Him, And prayer is continually made for Him, All day He is continually blessed.
16 Kí ìkúnwọ́ ọkà wà lórí ilẹ̀; ní orí òkè ni kí ó máa dàgbà kí èso rẹ̀ kí o gbilẹ̀ bí ti Lebanoni yóò máa gbá yìn bí i koríko ilẹ̀.
There is a handful of grain in the earth, On the top of mountains, Its fruit shakes like Lebanon, And they flourish out of the city as the herb of the earth.
17 Kí orúkọ rẹ̀ kí ó wà títí láé; orúkọ rẹ̀ yóò máa gbilẹ̀ níwọ̀n bí oòrùn yóò ti pẹ́ tó. Wọn ó sì máa bùkún fún ara wọn nípasẹ̀ rẹ. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ní yóò máa pè mí ní alábùkún fún.
His Name is for all time, Before the sun is His Name continued, And they bless themselves in Him, All nations pronounce Him blessed.
18 Olùbùkún ni Olúwa Ọlọ́run, Ọlọ́run Israẹli, ẹnìkan ṣoṣo tí ó ń ṣe ohun ìyanu.
Blessed is YHWH God, God of Israel, He alone is doing wonders,
19 Olùbùkún ni orúkọ rẹ̀ tí ó lógo títí láé; kí gbogbo ayé kún fún ògo rẹ̀.
And blessed [is] the Name of His glory for all time, And the whole earth is filled [with] His glory. Amen and amen!
20 Èyí ni ìparí àdúrà Dafidi ọmọ Jese.
The prayers of David son of Jesse have been ended.