< Psalms 71 >

1 Nínú rẹ, Olúwa, ni mo ní ààbò; má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí.
In you, O Lord, I take refuge, let me never be put to shame.
2 Gbà mí kí o sì tú mi sílẹ̀ nínú òdodo rẹ; dẹ etí rẹ sí mi, kí o sì gbà mí.
In your faithfulness save me and rescue me, bend your ear to me and save me.
3 Jẹ́ àpáta ààbò mi, níbi tí èmi lè máa lọ, pa àṣẹ láti gbà mí, nítorí ìwọ ni àpáta àti odi agbára mi.
Be to me a rock of defence, a fortified house, to save me; for my rock and my fortress are you.
4 Gbà mí, Ọlọ́run mi, lọ́wọ́ àwọn olùṣe búburú, ní ọwọ́ aláìṣòdodo àti ìkà ọkùnrin.
Save me, my God, from the hand of the wicked, from the grasp of the unjust and cruel.
5 Nítorí ìwọ jẹ́ ìrètí mi, Olúwa Olódùmarè, ìwọ ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi láti ìgbà èwe.
For you, Lord, are my hope, in whom from my youth I have trusted.
6 Mo gbẹ́kẹ̀lé ọ láti ìgbà ìbí mi; Ìwọ mú mi jáde láti inú ìyá mi wá èmi ó máa yìn ọ́ títí láé.
On you have I leaned from my birth; from my mother’s womb it was you who did draw me. In you is my hope evermore.
7 Mo di àmì fún ọ̀pọ̀ ènìyàn, ṣùgbọ́n ìwọ ni ààbò mi tí ó lágbára.
I have been as a wonder to many, for you are my refuge and strength.
8 Ìyìn rẹ̀ kún ẹnu mi, ó ń sọ ti ọlá rẹ ní ọjọ́ gbogbo.
All the day long my mouth is filled with your praise and your glory.
9 Má ṣe ta mí nù ní ọjọ́ ogbó mi, má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀ nígbà tí kò sí okun mọ́.
Cast me not off in the time of old age; when my strength is spent, forsake me not.
10 Nítorí àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀-òdì sí mi, àwọn tí wọn dúró láti pa mí gbìmọ̀ pọ̀.
For my foes whisper against me, they who watch me take counsel together;
11 Wọ́n wí pé, “Ọlọ́run ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀; lépa rẹ̀ kí ẹ sì mu, nítorí kò sí ẹni tí yóò gbà á.”
“God has left him,” they say: “pursue and seize him, for he is helpless.”
12 Má ṣe jìnnà sí mi, Ọlọ́run; wa kánkán, Ọlọ́run mi, láti ràn mí lọ́wọ́.
O God, be not far from me, haste, O my God, to my help.
13 Jẹ́ kí wọn kí ó dààmú, kí a sì run àwọn tí ń ṣe ọ̀tá ọkàn mi kí a sì fi ẹ̀gàn àti àbùkù bo àwọn tí ń wá ìpalára mi.
Put my foes to shame and dishonor, with insult and shame be they covered.
14 Ṣùgbọ́n ní tèmi, ìgbà gbogbo ní ìrètí mi; èmi ó yìn ọ́ síwájú àti síwájú sí i.
But I will never stop hoping, and more and yet more will I praise you.
15 Ẹnu mi yóò sọ nípa ti òdodo rẹ, ti ìgbàlà rẹ, ni gbogbo ọjọ́, lóòtítọ́, èmi kò mọ iye rẹ̀.
All the day long shall my mouth tell your faithfulness and your salvation, though I know not how they may be counted.
16 Èmi ó wá láti wá kéde agbára, Olúwa Olódùmarè; èmi ó kéde òdodo rẹ̀ nìkan.
I will tell of the might of the Lord, and your faithfulness praise, you alone.
17 Láti ìgbà èwe, Ọlọ́run ni ìwọ ti kọ́ mi títí di òní ni mo ń sọ ti iṣẹ́ ìyanu rẹ.
You have taught me, O God, from my youth, and till now have I told of your wonders.
18 Pẹ̀lúpẹ̀lú, nígbà tí èmi di arúgbó tán tí mo sì hewú, má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀, Ọlọ́run mi, títí èmi ó fi ipá rẹ han ìran tí ń bọ̀, àti agbára rẹ fún gbogbo àwọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn.
Even in old age and grey hair, O God, do not forsake me. Still would I tell of your might unto all generations to come.
19 Ọlọ́run, òdodo rẹ dé ọ̀run, ìwọ tí o ti ṣe ohun ńlá. Ta ni ó dàbí rẹ, Ọlọ́run?
Your power and your justice, O God, extend as far as the heavens: for great are the things you have done. Who is like you, O God?
20 Pẹ̀lúpẹ̀lú ìwọ ti mú mi rí ìdààmú, tí ó pọ̀ tí ó sì korò, ìwọ yóò tún sọ ayé mi jí ìwọ yóò sì tún mú mi sọ sókè láti ọ̀gbun ilẹ̀ wá. Ìwọ yóò sọ ọlá mi di púpọ̀.
You have caused us to see troubles many, but you will revive us again. From the depths of the earth you will bring me up again.
21 Ìwọ yóò fi kún ọwọ́ mi ìwọ yóò tù mí nínú ní ha gbogbo.
You will multiply my greatness, and comfort me again.
22 Èmi yóò fi dùùrù mi yìn fún òtítọ́ rẹ, Ọlọ́run mi; èmi ó kọrin ìyìn sí ọ pẹ̀lú dùùrù ìwọ ẹni mímọ́ Israẹli.
So with harp I will praise you, and your faithfulness, O my God; and make music to you on the lyre, O you Holy One of Israel.
23 Ètè mi yóò kígbe fún ìyìn nígbà tí mo bá kọrin ìyìn sí ọ: èmi, ẹni tí o rà padà.
My lips shall ring out their joy, my mouth shall sing praises to you; all of me, which you have redeemed.
24 Ahọ́n mi yóò sọ ti òdodo rẹ ní gbogbo ọjọ́, fún àwọn tí ó fẹ́ pa mí lára, a sì dójúti àwọn tí ń wá ìdààmú mi.
Yes, all the day long shall my tongue utter your righteousness; for ashamed and confounded are they who were seeking my hurt.

< Psalms 71 >