< Psalms 70 >

1 Fún adarí orin. Ti Dafidi. Ẹ̀bẹ̀. Yára, Ọlọ́run, láti gbà mí là, Olúwa, wá kánkán láti ràn mí lọ́wọ́.
למנצח לדוד להזכיר אלהים להצילני יהוה לעזרתי חושה
2 Kí àwọn tí ń wá ọkàn mi kí a dójútì wọ́n, kí wọn sì dààmú; kí àwọn tó ń wá ìparun mi yí ẹ̀yìn padà nínú ìtìjú.
יבשו ויחפרו מבקשי נפשי יסגו אחור ויכלמו חפצי רעתי
3 Kí a pa wọ́n ní ẹ̀yìn dà fún èrè ìtìjú àwọn tí ń wí pé, “Háà! Háà!”
ישובו על-עקב בשתם-- האמרים האח האח
4 Ṣùgbọ́n kí àwọn tí ó ń wá ọ ó máa yọ̀ kí inú wọn kí ó sì máa dùn nípa rẹ, kí àwọn tí ó ń fẹ́ ìgbàlà rẹ máa wí pé, “Jẹ́ kí a gbé Ọlọ́run ga!”
ישישו וישמחו בך-- כל-מבקשיך ויאמרו תמיד יגדל אלהים-- אהבי ישועתך
5 Ṣùgbọ́n mo jẹ́ òtòṣì àti aláìní; wa kánkán sí ọ̀dọ̀ mi, Ọlọ́run. Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àti olùdáǹdè mi; Olúwa, má ṣe dúró pẹ́.
ואני עני ואביון-- אלהים חושה-לי עזרי ומפלטי אתה יהוה אל-תאחר

< Psalms 70 >