< Psalms 7 >

1 Ṣiggaioni ti Dafidi, èyí tí ó kọ sí Olúwa nípa Kuṣi, ará Benjamini. Olúwa Ọlọ́run mi, ààbò mi wà nínú rẹ; gba mí là kí o sì tú mi sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tó ń lé mi,
שגיון לדוד אשר שר ליהוה על דברי כוש בן ימיני יהוה אלהי בך חסיתי הושיעני מכל רדפי והצילני׃
2 kí wọn ó má ba à fa ọkàn mi ya gẹ́gẹ́ bí kìnnìún, wọ́n á ya á pẹ́rẹpẹ̀rẹ láìsí ẹni tí yóò gbà mí.
פן יטרף כאריה נפשי פרק ואין מציל׃
3 Olúwa Ọlọ́run mi, tí èmi bá ṣe èyí tí ẹ̀bi sì wà ní ọwọ́ mi.
יהוה אלהי אם עשיתי זאת אם יש עול בכפי׃
4 bí èmi bá ṣe ibi sí ẹni tí ń wá àlàáfíà pẹ̀lú mi, tí mo ja ọ̀tá mi lólè láìnídìí,
אם גמלתי שולמי רע ואחלצה צוררי ריקם׃
5 nígbà náà, jẹ́ kí ọ̀tá mi lé mi kí wọn sì mú mi; jẹ́ kí òun kí ó tẹ ọkàn mi mọ́lẹ̀ kí wọn sì mú mi sùn nínú eruku. (Sela)
ירדף אויב נפשי וישג וירמס לארץ חיי וכבודי לעפר ישכן סלה׃
6 Dìde, Olúwa, nínú ìbínú rẹ; dìde lòdì sí ìrunú àwọn ọ̀tá mi. Jí, Ọlọ́run mi; kéde òdodo.
קומה יהוה באפך הנשא בעברות צוררי ועורה אלי משפט צוית׃
7 Kí ìpéjọ àwọn ènìyàn yíká. Jọba lórí wọn láti òkè wá.
ועדת לאמים תסובבך ועליה למרום שובה׃
8 Jẹ́ kí Olúwa ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn. Ṣe ìdájọ́ mi, Olúwa, gẹ́gẹ́ bí òdodo mi, gẹ́gẹ́ bí ìwà òtítọ́, ẹni gíga jùlọ.
יהוה ידין עמים שפטני יהוה כצדקי וכתמי עלי׃
9 Ọlọ́run Olódodo, Ẹni tí ó ń wo inú àti ọkàn, tí ó ń mú òpin sí ìwà ipá ẹni búburú tí ó sì ń pa àwọn olódodo mọ́.
יגמר נא רע רשעים ותכונן צדיק ובחן לבות וכליות אלהים צדיק׃
10 Ààbò mi ń bẹ lọ́dọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí ń ṣe ìgbàlà òtítọ́ ní àyà.
מגני על אלהים מושיע ישרי לב׃
11 Ọlọ́run ni onídàájọ́ òtítọ́, Ọlọ́run tí ń sọ ìrunú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́.
אלהים שופט צדיק ואל זעם בכל יום׃
12 Bí kò bá yípadà, Òun yóò pọ́n idà rẹ̀ mú; ó ti fa ọrun rẹ̀ le ná, ó ti múra rẹ̀ sílẹ̀.
אם לא ישוב חרבו ילטוש קשתו דרך ויכוננה׃
13 Ó ti pèsè ohun ìjà ikú sílẹ̀; ó ti pèsè ọfà iná sílẹ̀.
ולו הכין כלי מות חציו לדלקים יפעל׃
14 Ẹni tí ó lóyún ohun búburú, tí ó sì lóyún wàhálà, ó bí èké jáde.
הנה יחבל און והרה עמל וילד שקר׃
15 Ẹni tí ó gbẹ́ ọ̀fìn, tí ó kó o jáde jì sí kòtò tí ó gbẹ́ sílẹ̀.
בור כרה ויחפרהו ויפל בשחת יפעל׃
16 Wàhálà tí ó fà padà sórí rẹ̀; ìwà ipá rẹ̀ padà sórí ara rẹ̀.
ישוב עמלו בראשו ועל קדקדו חמסו ירד׃
17 Èmi ó fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí òdodo rẹ̀, èmi ó kọrin ìyìn sí Olúwa Ọ̀gá-ògo jùlọ.
אודה יהוה כצדקו ואזמרה שם יהוה עליון׃

< Psalms 7 >