< Psalms 67 >
1 Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Saamu. Orin. Kí Ọlọ́run kí ó ṣàánú fún wa kí ó sì bùkún fún wa, kí ó sì jẹ́ kí ojú rẹ̀ tàn yí wa ká,
詩歌,交與樂官,和以絃樂。 願天主祝福我們;以祂的慈愛容光照耀我們!
2 kí ọ̀nà rẹ le di mí mọ̀ ní ayé, ìgbàlà rẹ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè.
使世人認識天主的道路,萬民得知祂的救援。
3 Kí àwọn ènìyàn kí ó yìn ọ́, Ọlọ́run; kí gbogbo ènìyàn kí ó yìn ọ́!
天主,願萬民都稱頌您,願列邦也都讚美您!
4 Kí orílẹ̀-èdè kí ó yọ̀, kí ó sì kọrin fún ayọ̀, nítorí ìwọ fi òdodo darí àwọn ènìyàn, ìwọ sì jẹ ọba àwọn orílẹ̀-èdè ní ayé.
您以正義統治世人,且在地上領導萬民,萬民都要踴躍歡欣。
5 Kí àwọn ènìyàn kí ó yìn ọ́, Ọlọ́run; kí gbogbo ènìyàn kí ó yìn ọ́. (Sela)
天主,願萬民都稱頌您,願列邦也都讚美您!
6 Nígbà náà ní ilẹ̀ yóò mú ìkórè rẹ̀ wá, Ọlọ́run, Ọlọ́run wa, yóò bùkún fún wa.
大地為我們生產百果與五穀;天主,我們的天主給我們賜福。
7 Ọlọ́run yóò bùkún fún wa, àti gbogbo òpin ilẹ̀ ayé yóò sì máa bẹ̀rù rẹ̀.
願天主給我們祝福,願萬民都敬愛天主!