< Psalms 66 >
1 Fún adarí orin. Orin. Saamu. Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọ́run, ẹ̀yin ilẹ̀ gbogbo!
For the leader. A song. A psalm. Shout to God, all the earth,
2 Ẹ kọrin ọlá orúkọ rẹ̀; ẹ kọrin ìyìnsí i.
sing praise to his glorious name, sing his glorious praise.
3 Ẹ wí fún Ọlọ́run pé, “Ìwọ ti ní ẹ̀rù tó nínú iṣẹ́ rẹ! Nípa ọ̀pọ̀ agbára rẹ ni àwọn ọ̀tá rẹ yóò fi sìn ọ́.
Say to God, ‘How dread are your works, so great is your might that your enemies cringe to you.
4 Gbogbo ayé ń wólẹ̀ fún ọ; wọn ń kọrin ìyìn sí ọ, wọ́n ń kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ.” (Sela)
All the earth does homage to you, singing praises to you, singing praise to your name.’ (Selah)
5 Ẹ wá wo ohun tí Ọlọ́run ṣe, iṣẹ́ rẹ̀ ti ní ẹ̀rù tó sí àwọn ọmọ ènìyàn!
Come and see what God has done, awe-inspiring is he in his works among people.
6 Ó yí òkun padà sí ilẹ̀ gbígbẹ, wọ́n fi ẹsẹ̀ rin inú omi kọjá, níbẹ̀ ni àwa yọ̀ nínú rẹ̀.
He turns the sea into dry land, and people cross the river on foot. Let us therefore rejoice in him,
7 Ó ń jẹ ọba títí láé nípa agbára rẹ̀, ojú rẹ̀ ń wo orílẹ̀-èdè kí àwọn ọlọ̀tẹ̀ má ṣe gbé ara wọn ga. (Sela)
the mighty Ruler eternal, whose eyes keep watch on the nations, that no rebel lift up his head. (Selah)
8 Ẹ yin Ọlọ́run wa, ẹ̀yin ènìyàn, jẹ́ kí a mú ni gbọ́ ohùn ìyìn rẹ̀;
O bless our God, you peoples; sound aloud his praise,
9 Ó ti dá ààbò bo ẹ̀mí wa, kò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ wa kí ó yẹ̀.
who keeps us in life, and keeps our feet from slipping.
10 Nítorí ìwọ, Ọlọ́run, dán wa wò; ìwọ dán wa bí a tí ń dán fàdákà wò.
For you, God, have tested us, have tried us, as silver is tried.
11 Ìwọ mú wa wá sínú ẹ̀wọ̀n o sì di ẹrù lé ẹ̀yìn wa.
You did bring us into prison, and put chains upon us,
12 Ìwọ mú àwọn ènìyàn gún wá ní orí àwa la iná àti omi kọjá ṣùgbọ́n ìwọ mú wa dé ibi ọ̀pọ̀.
you did let people ride over our head. We went through fire and through water, but you led us out to a spacious place.
13 Èmi ó wá sí tẹmpili rẹ pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun, kí n sì mú ẹ̀jẹ́ mi ṣẹ sí ọ,
I will enter your house with burnt-offerings, I will pay to you my vows,
14 ẹ̀jẹ́ tí ètè mi jẹ́, tí ẹnu mi sì sọ nígbà tí mo wà nínú ìṣòro.
which my open lips have uttered, arid my mouth has declared in my straits.
15 Èmi ó rú ẹbọ sísun ọlọ́ràá sí ọ, àti ẹbọ ọ̀rá àgbò; èmi ó rú akọ màlúù àti ewúrẹ́. (Sela)
I will offer you offerings of fatlings, with the odour of burning rams, I will sacrifice bullocks with goats. (Selah)
16 Ẹ wá gbọ́ gbogbo ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run; ẹ jẹ́ kí n sọ ohun tí ó ṣe fún mi.
Come and hear my story all who fear God – of what he has done for me.
17 Mo fi ẹnu mi kígbe sókè sí i, ìyìn rẹ̀ wà ní ẹnu mi.
For my mouth had no sooner invoked him than his praise was under my tongue.
18 Bí èmi bá gba ẹ̀ṣẹ̀ ní àyà mi, Olúwa kì yóò gbọ́ ohùn mi;
Had I cherished sin in my heart, the Lord would never have listened.
19 ṣùgbọ́n Ọlọ́run gbọ́ nítòótọ́ ó ti gbọ́ ohùn mi nínú àdúrà.
But assuredly God has listened, and attended to my loud prayer.
20 Ìyìn ni fún Ọlọ́run ẹni tí kò kọ àdúrà mi tàbí mú ìfẹ́ rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi!
Blessed be God, who turned not aside my prayer, nor withdrew his kindness from me.