< Psalms 65 >

1 Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi. Orin. Ìyìn ń dúró dè ọ́, Ọlọ́run, ní Sioni; sí ọ ni a ó mú ẹ̀jẹ́ wa ṣẹ.
למנצח מזמור לדוד שיר ב לך דמיה תהלה אלהים בציון ולך ישלם-נדר
2 Ìwọ tí ó ń gbọ́ àdúrà, gbogbo ènìyàn yóò sì wá sọ́dọ̀ rẹ.
שמע תפלה-- עדיך כל-בשר יבאו
3 Ọ̀ràn àìṣedéédéé borí mi bí ó ṣe ti ìrékọjá wa ni! Ìwọ ni yóò wẹ̀ wọ́n nù kúrò.
דברי עונת גברו מני פשעינו אתה תכפרם
4 Ìbùkún ni fún àwọn tí o yàn tí o mú wa láti máa gbé àgọ́ rẹ! A tẹ́ wá lọ́rùn pẹ̀lú ohun rere inú ilé rẹ, ti tẹmpili mímọ́ rẹ.
אשרי תבחר ותקרב-- ישכן חצריך נשבעה בטוב ביתך קדש היכלך
5 Ìwọ dá wa lóhùn pẹ̀lú ohun ìyanu ti òdodo, Ọlọ́run olùgbàlà wa, ẹni tí ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé gbogbo òpin ayé àti àwọn tí ó jìnnà nínú òkun,
נוראות בצדק תעננו-- אלהי ישענו מבטח כל-קצוי-ארץ וים רחקים
6 ìwọ tí ó dá òkè nípa agbára rẹ, tí odi ara rẹ ní àmùrè agbára,
מכין הרים בכחו נאזר בגבורה
7 ẹni tí ó mú rírú omi òkun dákẹ́, ríru ariwo omi wọn, àti ìdágìrì àwọn ènìyàn.
משביח שאון ימים--שאון גליהם והמון לאמים
8 Àwọn tí ó ń gbé òkèrè bẹ̀rù, nítorí àmì rẹ wọ̀n-ọn-nì; ìwọ mú ìjáde òwúrọ̀ àti ti àṣálẹ́ yọ̀, ìwọ pè fún orin ayọ̀.
וייראו ישבי קצות--מאותתיך מוצאי בקר וערב תרנין
9 Ìwọ bẹ ayé wò, o sì bomirin; ìwọ mú un ọ̀rọ̀ púpọ̀. Odò Ọlọ́run kún fún omi láti pèsè ọkà fún àwọn ènìyàn, nítorí ibẹ̀ ni ìwọ ti yàn án.
פקדת הארץ ותשקקה רבת תעשרנה-- פלג אלהים מלא מים תכין דגנם כי-כן תכינה
10 Ìwọ fi bomirin sí aporo rẹ̀ ìwọ tẹ́ ògúlùtu rẹ̀; ìwọ fi òjò mú ilẹ̀ rẹ̀ rọ̀, o sì bùkún ọ̀gbìn rẹ̀.
תלמיה רוה נחת גדודה ברביבים תמגגנה צמחה תברך
11 Ìwọ fi oore rẹ dé ọdún ní adé, ọ̀rá ń kán ní ipa ọ̀nà rẹ.
עטרת שנת טובתך ומעגליך ירעפון דשן
12 Pápá tútù ní aginjù ń kan àwọn òkè kéékèèké fi ayọ̀ di ara wọn ní àmùrè.
ירעפו נאות מדבר וגיל גבעות תחגרנה
13 Agbo ẹran ni a fi wọ pápá tútù náà ní aṣọ; àfonífojì ni a fi ọkà bò mọ́lẹ̀, wọ́n hó fún ayọ̀, wọ́n ń kọrin pẹ̀lú.
לבשו כרים הצאן-- ועמקים יעטפו-בר יתרועעו אף-ישירו

< Psalms 65 >