< Psalms 64 >
1 Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi. Gbóhùn mi, Ọlọ́run, bí mo ti ń sọ àròyé mi pa ọkàn mi mọ́ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀rù àwọn ọ̀tá.
To the chief music-maker. A Psalm. Of David. O God, let the voice of my grief come to your ear: keep my life from the fear of those who are against me.
2 Pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ àwọn ènìyàn búburú kúrò nínú ọ̀pọ̀ igbe lọ́wọ́ ìrúkèrúdò oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.
Keep me safe from the secret purpose of wrongdoers; from the band of the workers of evil;
3 Wọ́n pọ́n ahọ́n wọn bí idà, wọ́n sì fa ọrun wọn le láti tafà wọn, àní ọ̀rọ̀ kíkorò.
Who make their tongues sharp like a sword, and whose arrows are pointed, even bitter words;
4 Wọ́n tafà ní ìkọ̀kọ̀ sí àwọn aláìlẹ́ṣẹ̀: wọ́n tafà si lójijì, wọn kò sì bẹ̀rù.
So that in secret they may let loose their arrows at the upright, suddenly and unseen.
5 Wọ́n, gba ara wọn níyànjú nínú èrò búburú, wọ́n sọ̀rọ̀ lórí dídẹkùn sílẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀ wọ́n wí pé, “Ta ni yóò rí wa?”
They make themselves strong in an evil purpose; they make holes for secret nets; they say, Who will see it,
6 Wọ́n gbìmọ̀ àìṣòdodo, wọ́n wí pé, “A wa ti parí èrò tí a gbà tán!” Lóòótọ́ àyà àti ọkàn ènìyàn kún fún àrékérekè.
Or make discovery of our secret purpose? The design is framed with care; and the inner thought of a man, and his heart, is deep.
7 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò ta wọ́n ní ọfà; wọn ó sì gbọgbẹ́ lójijì.
But God sends out an arrow against them; suddenly they are wounded.
8 Ahọ́n wọn yóò sì dojú ìjà kọ wọ́n, yóò sì run wọ́n, gbogbo ẹni tí ó bá rí wọn yóò sì mi orí fún wọn.
The evil of their tongues is the cause of their fall; all those who see them are shaking their heads at them.
9 Gbogbo ènìyàn yóò máa bẹ̀rù wọn ó kéde iṣẹ́ Ọlọ́run wọn ó dúró lé ohun tí ó ṣe.
And in fear men make public the works of God; and giving thought to his acts they get wisdom.
10 Jẹ́ kí olódodo kí ó yọ̀ nínú Olúwa yóò sì rí ààbò nínú rẹ̀. Gbogbo ẹni ìdúró ṣinṣin ní ọkàn yóò máa yìn ín.
The upright will be glad in the Lord and have hope in him; and all the lovers of righteousness will give him glory.